Está en la página 1de 71

14.O. APOLA IRẸTẸ.

14.1. IRẸTẸ-AGBE (IRẸTẸ-OGBE, AATẸ-GBE )

ẸSẸ KINNI.

Ire ilọsiwaju. (Bendicion de prosperidad)

Ifa lawọn ọrẹ-meji kan niyi, Ifa niwọn jọ ra fila kanna, Ifa njuwe wipe fila pupa ni. Ifa ni kiwọn mu fila yi
kiwọn fikun ẹbọ ru, kiwọn lee jọ sorire papọ, kọran wọn le gun, kọran wọn le ko. Ifa leleyii yoo jasiwaju bi
ọba, tiwọn yoo si dọja rere. Ifa ni kiwọn fi FILA PUPA KUN ẸBỌ RU nibẹ.
Toba sobinrin lo dafa yi, gele nifa ntọka si nibẹ, kiwọn o fi GELE PUPA YI RUBỌ nibẹ , kiwọn le debi tiwọn
nlọ, kiwọn lee moke nibẹ, kori rere wọn lee jade sita, kọba tiwọn yoo jẹ le niyi, kole lẹyẹ, kaiye le mọ wọn si
rere. Ifa ni fila lawọn ọrẹ mejeji yi ni papọ. To basi sobinrin ni, gele niwọon ni papọ. Ifa ni pupa ni fila tabi
gele yi, kiwọn wonu ile wọn nibẹ, wọn yoo ba nibẹ, kiwọn fi kun ẹbọ ru nibẹ, kọran awọn mejeji le dara
papọ. Ifa ni yoo yẹ wọn, wọn yoo nilaari, wọn yoo dẹni apesin, wọn yoo dọlọja rere. Tiwọn ba dale-isẹ silẹ,
ile-isẹ yi yoo fẹ, yoo gboro.
Ifa nikan ninu awọn ọrẹ mejeji yoo jọba, yoo si jọ yẹ wọn papọ. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que hay dos amigos, Ifa dice que tienen las mismas gorras juntos, Ifa esta senalando que son gorras
rojas. Ifa dice que deben PONER ESAS GORRAS en su scarificio, para que pueden conseguir bendiciones
juntos, para que las vidas les van bien a los dos juntos. Ifa dice que esta persona sera un lider como el Rey y
tendran buen mercado, que tendran buen negocio. Ifa dice que deben poner esas gorras en su sacrificio.
Si es una mujer que ha hecho esta consulta, Ifa esta senalando a panos de la cabeza, son panos rojos, Ifa dice
que deben PONER ESOS PANOS en su sacrificio, para que pueden llegar juntos a donde quieren/deben
llegar, para que pueden superar los obstaculos juntos, para que les abren sus caminos de bendiciones, para
que pueden ser Reyes y persona de negocios populares juntos, para que todos el mundo les conocen para
bien. Ifa dice que estos dos amigos tienen las mismas gorras juntos. Si es una mujer que ha hecho esta
consulta, Ifa dice que son panos de la cabeza que tienen juntos, deben mirar sus casas muy bien, Ifa dice
que debe poner estas gorras o panos de cabeza en su sacrificio, para que los asuntos de los dos salen bien.
Ifa dice que seran personas populares, prosperaran y seran personas que las gentes adoran. Si quieren
montar una empreza, esa empresa prosperara y se multiplicara. Ifa dice que uno de estos dos amigos sera
un Rey y los dos amigos seran populares juntos. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Atẹgbe nihin. (Ategbe aqui)


Atẹgbe lọhun. (Ategbe alla)
A difa fun Ooru ohun Aako. (Se adivino Ifa para Ooru y Aako)
Aako ndade. (Aako esta coronandose)
Ooru ndaja. (Ooru esta haciendo negocios/comercios)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)

Aako ati Ooru, ọrẹ lawọn mejeji. Niwọn balọ dafa wipe bawo niwaju awọn yoo seri. Ifa lọjọ iwaju wọn yoo
dara. Ifa lawọn mejeji ni fila kan, Ifa ni pupa ni fila naa. Wọn ni lotitọ ni. Ifa ni FILA PUPA YI NI KIWỌN
FI KUN ẸBỌ RU nibẹ, kire wọn tiwọn bani, lee ma dọjọ alẹ, wipe aiye koni sẹwọn lori nibẹ.
Ifa nikan ninu wọn yoo dọba alade lọjọ iwaju, ti yoo dade. Ikan ninu wọn yoo dọlọja gboro, tọja rẹ yoo si
kun, tọja re yoo pọ ninu awọn mejeji. Ifa ni yoo wa jọ yẹwọn pọ. Ọlọja ta nwi ni wipe keniyan dale-isẹ silẹ,
tile-isẹ yi yoo gbooro, ti yoo tobi pupọ, teleyii yoo wa dọlọla ati ọlọrọ, pẹlu eyiti o dade naa, ni yoo bajọ yẹ
awọn mejeji papọ.
Niwọn ba rubọ, wọn se gbogbo ohun toyẹ kiwọn se. Wọn ko gbagbe Ifa. Wọn ko gbagbe babalawo to sefa
funwọn. Niwọn ba njo, wọn nyọ, wọn nyin awọn awo wọn, awọn awo wọn si nyin Ifa; Wọn ni, bẹẹ gẹgẹ
lawọn awo tawọn wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo tawọn sọ:

Ooru y Aako eran dos amigos, fueron a consultarse con Ifa para saber de sus futuros. Ifa dijo que tendran
buen futuro. Ifa dijo que los dos tienen gorras de color rojo juntos. Ooru y Aako dijieron que era la verdad.
Ifa dijo que DEBEN PONER LAS GORRAS en sus sacrificio, para que sus bendiciones les duran hasta sus
ultimos dias de vidas, Ifa dice que las gentes, brujos/as no conseguiran a matarles.
Ifa dice que uno de ellos sera el Rey con corona en el futuro. Ifa dice que el otro de ellos sera un comerciante
de negocios con mucho futuro por delante. Ifa dice que los dos amigos seran populares juntos, que tendran
dinero y las riquezas juntos.
Hicieron los sacrificios y todos los demas cosas que les mandaron a hacer. No olividaron de Ifa. No
olividaron de los babalawos que les adivinaron Ifa. Los dos amigos estaban felices, empezaron a bailar y
cantar; Que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Atẹgbe nihin. (Ategbe aqui)


Atẹgbe lọhun. (Ategbe alla)
A difa fun Ooru ohun Aako. (Se adivino Ifa para Ooru y Aako)
Aako ndade. (Aako esta coronandose)
Ooru ndaja. (Ooru esta haciendo negocios/comercios)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)
Ẹbọ niwọn ni wọn se. (Les dijieron que deben hacer el sacrificios)
Wọn si gbẹbọ nibẹ, wọn rubọ. (Lo hicieron)
Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)

O nse: ORIN (CANCION)

Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)
Aako ndade. (Aako esta coronandose)
Ooru ndaja. (Ooru esta haciendo negocios/comercios)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)
Aako ndade. (Aako esta coronandose)
Ooru ndaja. (Ooru esta haciendo negocios/comercios)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)
Aako ndade. (Aako esta coronandose)
Ooru ndaja. (Ooru esta haciendo negocios/comercios)
Ati dade ọba ko soro. (No sera dificil coronarse el Rey)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o setutu nibẹ. Ifa lọjọ iwaju wọn yoo dun yoo larinrin loju Irẹtẹ-Agbe. Ifa ni kiwọn fi
FILA PUPA KUN ẸBỌ RU nibẹ. Toba sobinrin lo dafa yi, gele nifa ntọka si nibẹ, kiwọn o fi GELE PUPA YI
RUBỌ nibẹ.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que el futuro de ellos seran dulces como
el miel en el signo de Irẹtẹ-Agbe. Ifa dice que deben PONER ESAS GORRAS en su scarificio. Si es una mujer
que ha hecho esta consulta, Ifa esta senalando a panos de la cabeza, son panos rojos, Ifa dice que deben
PONER ESOS PANOS en su sacrificio.

ẸSẸ KEJI.

Ayewo iku. (Investigar la muerte)


Tifa ba gbin, tifa kosọ nkan dada, wipe lori ohun teleyii dafa si ko dara. Ifa ni keleyii o rubọ dada nibẹ. Ifa
lọmọbinrin kan niyi, koma ba jẹpe lọsan kan, oru kan lọmọbinrin yi yoo file aiye sile, ti yoo ku. Ifa ni kiwọn
o rubọ nitori ọmọbinrin, kọmọbinrin yi ma baku.
Ifa lọmọbinrin yi ko jabiku, ko jemere ni. Ifa ni kwọn setutu nitori ọmọbinrin yi, koma ba jẹpe lọsan kan,
oru kan lọmọbinrin yi yoo file aiye sile, ti yoo ku. Emere ọmọ tiko ni dape, tiko ni duro dada, ti yoo ba
pogun ọdun, ti yoo siku.
Emere ọmọ miran wa, ti yoo duro dada, ti nkankan koni sọmọyi, tiwọn yoo wa dajọ igbeyawo rẹ, ti yoo si
wa ku. Ifa ni kiwọn setutu nitori ọmọbinrin yi. Ifa ni Ọlọrun koni jẹ kisẹlẹ buruku o sẹlẹ sonifa yi. Ifa ni ko
setutu nibẹe, koma ba jepe lọsan kan, oru kan lọmọbinrin yi yoo file aiye silẹ, tiwọn yoo muu lọ, ti yoo siku.
Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Si Ifa dice que no, si Ifa no habla bien sobre lo que esta persona ha consultado. Ifa dice que esta persona
debe hacer el sacrificio muy bien. Ifa dice que hay una mujer, para que esta mujer no déjà el mundo en un
dia y murir. Ifa dice que deben hacer el sacrificio para esta mujer para que ella no muere.
Ifa dice que esta mujer no parace a una persona que viene al mundo para no quedarse o un espiritu. Ifa dice
que deben hacer el sacrificio para esta mujer para que ella no muere. Un hijo-espiritu que no esta complete,
que no esta bien firme en el tierra, que viene al mundo para no quedarse, que no va a llegar los vente anos
antes de murirse.
Hay otro tipo de hijo-espiritu, que parece que esta bien firme en la tierra, pero el dia que senalan la fecha de
su boda, se mueren. Ifa dice que deben hacer el sacrificio para esta mujer, para que ella no muere. Ifa pide a
Olodumare para que algo malo no pasa a esta persona que ha hecho esta consulta. Ifa dice que deben hacer
el sacrificio para esta mujer, para que ella no déjà el mundo en un dia y murirse. Ifa lo dice asi con este
verso; QUE:

Egbo ewuro ko lomi. (Las raices de la hierba de ewuro no tiene agua/jugo)


Tọdan ni o gba kengbe. (La raiz del arbol de Ọdan no entra dentro de la jicara)
Ẹni toba rigbẹ-esusu, (El que ve el bosque de Esusu)
Koma gbagbe yun mọ. (Que no juega con la jicara)
Gbogbo igbo kii se lomi. (!Porque todos los bosque no pueden tener agua!)
A difa fun Eegbin. (Se adivino Ifa para el Eegbin “Antilope”)
Eyiti nsọmọ Ọlọrun-jojolo. (El que era el hijo del Dios que es un recien nacido)
Ero ti reegbin lọna oko. (Las gentes han vistos al Eegbin “Antilope” en el camino del
campo)
Ero to reegbin lọna odo. (Las gentes que han vistos al Eegbin “Antilope” en el camino
del rio)
Ẹ ma matọ. (Ustedes no cogen el rifle)
Ẹ ma mọfa. (Ustedes no cogen el arco)
Eegbin ile wọn lo jalọ. (Es el Eegbin “Antilope” de la casa de ellos que rompio la
cuerda y se escapo)
Ifa ma majẹ keegbin ile mi o jalọ. (Ifa no déjà que el Eegbin “Antilope” de me casa rompe la
cuerda y escaparse)
Ero opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹ ma majẹ keegbin ile mi o jalọ. (Ustedes no déjàn que el Eegbin “Antilope” de me casa
rompe la cuerda y escaparse)
ASẸ-IFÁ:- Ifa ni Ọlọrun koni jẹ keegbin inu ile eleyii o jalọ, kohun rere inu ile eleyii ma jalọ. Ifa lohun to
dara ninu ile eleyii, arẹwa obinrin, koni jalọ. Ifa ni Ọlọrun koni fiku paa meleyii lọwọ, ko TETE rubọ nibẹ,
kiku ma pọmọbinrin yi.

ASẸ-IFÁ:- Ifa pide a Olodumare para que el Eegbin “Antilope” de la casa de esta persona, no rompe la
cuerda y escaper, que no escapa las cosas buenas fde esta casa. Ifa dice que la cosa Buena de esta casa, una
mujer bella, no se va a escaper. Ifa dice que Olodumare no va a permitir que la muerte la lleva, que debe
hacer el sacrificio URGENTEMENTE, para que la muerte no mata a esta mujer bella/guapa.

14.2. AATẸ-YẸKU (IRẸTẸ ỌYẸKU)

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Investigar el vencimiento de los enimigos)

Ifa nsọ feleyi wipe ẹnikan ni nseke yi, ti nsewa ọdalẹ, iwa buruku, keniyan ma sabosi. Eniyan ti nparọ. Ifa
leleyii nsayọnusọ kakiri, ayọnusọ ọrọ tiko keleyii. Ifa ni Ọlọrun se tan ti yoo meleiyi, tasiri rẹ yoo tu wipe
onisọkusọ ni, wipe alabosi ni, wipe eleyii kii seniyan dada.
Ifa lẹni to nsọ nkan tiko ri yi, yoo ni wahala. Ifa ni Ọlorun se tan ti yoo meleyii, tasiri rẹ yoo tu larin gbogbo
aiye. Ifa ni gbogbo ẹniti nbati nsọsọkusọ yoo kan wahala loju Aatẹ-yẹku. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa
na sọ pe:

Ifa le esta diciendo a esta persona que hay una persona mentiendo, traicionando, comportarse mal, un
chismoso. Una persona mentiroso. Ifa dice que esa persona esta hablando por alli lo que no sabe y lo que no
tiene nada que ver con el. Ifa dice que Olodumare esta preparado para descubir a esa persona, el escreto de
esa persona se va a revelar que es una persona que habla sin sentidos, que es un chismoso y que no es una
buena persona.
Ifa dice que esa persona que esta hablando de lo que no sabe, ni ha visto y tendra problema. Ifa dice que
Olodumare esta preparado para descubirle y el secreto de esa persona se revelara delante todo el mundo. Ifa
dice que todas las personas que hablan lo que no saben, ni lo han vistos tendran problemas en el signo de
Aatẹ-yẹku. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:
Aatẹ yẹku. (Aatẹ yẹku)
O yiwọn biri. (Enseguida dio la vuelta a ellos)
Oloti-juhun, bayi lẹ ẹ seke. (Oloti-juhun asi sois mentirosos)
A dia fun Oosa-nla Osẹrẹmagbo. (Se adivina Ifa para Oosa-nla Osẹrẹmagbo)
Nijọ ti baba nlọ re fẹru eke jona. (El dia que el padre iba a quemar las petenencias del mentiroso)
Ẹbọ niwọn niki baba o se. (Dijieron al padre que debe hacer el sacrificio)
O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Oju talayọnusọ. (El chismoso se quedo en verguenza)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, Ifa loju yoo talafenusọ. Ifa lasiri eleyii yoo tu. Gbogbo ẹniti nsabosi, ti
nseke, Ifa yoo foju wọn delẹ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kawọn babalawo beleyi jewe Ifa. Ifa leleyii yoo sẹgun
awọn ọta rẹ nibẹ.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que el chismoso se quedara en
verguenza. Ifa dice que el escreto de esa persona se revelara. Ifa dice que todas las personas que hablan lo
que no saben, ni lo han vistos, tendran problemas. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y
acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa. Ifa dice que esta persona vencera a sus
enimigos.

ẸSẸ KEJI.

Ifa lobinrin kan niyi to ndọkọ yi, o nyan ale mọkọ rẹ lara. Ifa lobinrin yi yoo ni wahala, ti gbogbo eniyan yoo
simọ wipe obinrin yi nyan ale. Ifa nigbayi lobinrin yi yoo darukọ gbogbo awọn ale rẹ, gbogbo awọn tiwọn
nbobinrin yii sun, nigba toba ni wahala. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que hay una mujer que esta teniendo otro hombre fuera de su matrimonio. Ifa dice que esta mujer
tendra problema y todo el mundo se enteraran que esta mujer esta teniendo relaciones con otro hombre
fuera su matrimonio. Ifa dice que cuando esta mujer tenga problema, nombrara a todos los hombres que
estan teniendo relaciones sexuales con ella fuera de su matrimonio. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Aatẹ yẹku. (Aatẹ yẹku)


O yiwọn biri. (Enseguida dio la vuelta a ellos)
Igba-Esunsun ko tọkọ kan. (Dos cientos de Esunsun no son suficiente para llenar/montar
un vehiculo)
Ọba lo tori Esunsun jẹ (solamente el Rey es capaz de comer la cabeza de Esunsun)
A dia fun Jẹ-moti ran-ọ. (Se adivino Ifa para Jẹ-moti ran-ọ)
Eyiti nsayoo Onijẹhuntẹ. (Que era la esposa preferida de Onijẹhuntẹ)
Ewure ile o gbọdọ kan akọ. (La cabra de la casa no puede dar cabezazo al macho)
Agutan ile o gbọdọ kan Agbo. (La chiva de la casa no puede dar cabezazo al chivo)
Boko ba dun ẹ ladunju. (Si la piedra te duele mas de la cuenta)
Koma mase kami (No me nombra a me)

Wọn niki Jẹ-moti ran-ọ o rubọ, koma ba jẹpe nigbati wahala yoo bade sarin oun ale-rẹ, koma lee ma ka
gbogbo awọn ale-rẹ, wọn niki Jẹ-moti ran-ọ o rubọ nibẹ, koma ba di wahala o. Nitoripe tobinrin bati nka
gbogbo awọn ale-rẹ, yoo di wahala ni. Wọn yoo ma sọpe lagbaja ni ndoyawo lamọrin, lamọrin ni ndoyawo
lagbaja. Ni Jẹ-moti ran-ọ ba rubọ nibẹ.
Nigba tasiri tu, tara Jẹ-moti ran- ọ ko ya, ẹbọ timu Jẹ-moti ran-ọ, kole darukọ awọn ale-rẹ. Ifa ni keleyii o
rubọ nibẹ, keleyii ma lee kakọ nigbati wahala bade sii larin awọn tiwọn nba a sun. Tẹnikan badun koto
lagbo ile nisinsinyi, se niwọn yoo sin nigbẹrẹ rẹ, tiko ni le kakọ, obinrin yi koni sẹniti ndo o layelaye, isẹ tifa
nseni. Ifa ni tọran ba daru larin awọn tiwọn ndo eleyii, koma ba kakọ.

Dijieron a Jẹ-moti ran-ọ que debe hacer el sacrificio, para que ella no nombran a los hombres que estan
teniendo relaciones sexuales con ella fuera de su matrimonio. Dijieron que Jẹ-moti ran-ọ debe hacer el
sacrificio, para que no tenga problema. Porque se convertira en problema, cuando una mujer nombra a los
hombres que estan teniendo relaciones sexuales con ella fuera de su matrimonio. Las gentes diran que tal
persona esta teniendo relaciones sexuales con la mujer de fulano. Je-moti ran-ọ hizo el sacrificio.
Cuando descubrieron los sercretos de Je-moti ran-ọ. Je-moti ran-ọ estaba enferma. Su sacrificio se levanto y
se acepto, ella no podia nombrar a los hombres que estan teniendo relaciones sexuales con ella fuera de su
matrimonio. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que ella no nombra a los hombres que
estan teniendo relaciones sexuales con ella fuera de su matrimonio, cuando tenga problemas esos hombres.
Ahora mismo, si una mujer empieza a nombra a los hombres que estan teniendo relaciones sexuales con
ella fuera de su matrimonio, se hace inciciones a ella y no nombrara a los hombres que estan teniendo
relaciones sexuales con ella fuera de su matrimonio; es obra de Ifa. Ifa dice que cuando ella tenga problema
con los hombres que estan teniendo relaciones sexuales con ella fuera de su matrimonio, para que ella no
menciona los nombres de esos hombres.

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni tọran ba daru larin awọn tiwọn ndo eleyii, koma ba kakọ. Ifa
nkeleyi nilọ wipe ko sọrarẹ, koma sabosi, koma rojọ ẹlẹjọ, koma gbẹniyan lẹsẹ, kole ba debi to nlọ. Ifa
nkeleyii nilọ.
Toba jobinrin leleyii, Ifa ni ko sọrarẹ, koma yan ale mọkọ-rẹ lara, tobinrin ba yan ale mọkọ-rẹ lara, asiri rẹ
yoo tu, ti wahala yoo side. Ti wahala bade, obinrin yii koni mẹni to baa sun mọ, koni le darukọ wọn. Ifa ni
ko sọra dada loju Irẹtẹ Ọyẹku.

ASẸ-IFÁ:- Ifa le esta diciendo a esta persona que debe hacer el sacrificio. Ifa dice que cuando ella tenga
problema con los hombres que estan teniendo relaciones sexuales con ella fuera de su matrimonio, para que
ella no mencionan los nombres de esos hombres. Ifa esta insistiendo y llamando la atencion a esta persona
que no debe ser chismoso/sa, no debe hablar de los demas por alli, no debe hacer mal a los demas, para
que puede llegar a donde tiene que llegar. Ifa esta llamando la atencion a esta persona.
Si esta persona es una mujer, Ifa dice que ella debe tener cuidado, ella no debe tener relaciones sexuales con
otros hombres fuera de su matrimonio, porque sus secretos se descubriran si ella lo hace y tendra
problema. Cuando ella tenga problema, ella no recuerdara de los nombres de esos hombres que han tenidos
relaciones sexuales con ella. Ifa dice que ella debe tener cuidado en el signo de Irẹtẹ-Ọyẹku.

14.3. IRẸTẸ AWỌNYE (IRẸTẸ IWORI)

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo ogun. (Investigar la batalla)

Irẹtẹ-Iwori la npeni Irẹtẹ-Awọnye. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa logun nbọ niwaju eleyii, ko TETE rubọ silẹ
dogun yi, kole ba a sẹgun. Toba jẹlu lo dafa yi, kiwọn sọ fun ilu yi wipe ogun nbọ, ko TETE rubọ silẹ dogun
yi, kole ba a sẹgun nigba togun yi bade, ti wahala yi bade.
Ifa ni koni AGBO KAN lẹbọ nibẹ, koni ORUKỌ KAN lẹbọ nibẹ, koni ẸYIN ADIẸ MẸRINDINLOGUN lẹbọ
nibẹ, kogun ma baa wọnu ilu yi, tabi ninu ile yi.
Toba jẹnikan lo dafa yi, ko rubọ, ogun kan nbọ, ko rubọ, kogun yi ma baa muwọn loju Irẹtẹ Iwori. Ibi tifa wa
gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Irẹtẹ Iwori es lo que llamamos Irẹtẹ Awọnye. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que
viene batalla/guierra enfrente de esta persona. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio
URGENTEMENTE, antes de que llega la batalla/guierra, para que puede vencer. Si es una ciudad que ha
hecho esta consulta, Ifa dice que viene batalla enfrente de esta ciudad, deben hacer el sacrificio
URGENTEMENTE, antes de que llega la batalla, para que pueden vencer cuando llega la batalla, para que
pueden vencer cuando llega este problema.
Ifa dice que debe tener UN CHIVO en su sacrificio, debe tener UNA CABRA MACHO en su sacrificio, debe
tener UN GALLO en su sacrificio, debe tener DIECISIES HUEVOS DE GALLINA en su sacrificio, para que
la guierra/batalla no entra en esa ciudad/casa.
Si es una persona que ha hecho esta consulta, Ifa dice que debe hacer el sacrificio URGENTEMENTE porque
viene guierra/batalla enfrente de esta persona, para que esta guierra/batalla no captura a esta persona en el
signo de Irẹtẹ-Iwori. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:
Irẹtẹ Iwori awo aiye. (Irete-Iwori el awo del mundo)
Ogun maa baiye jẹ. (Que la guierra no destruye el mundo)
Ọtẹ sọbi-nu. (Las conspiraciones se hecha a peder de nacer)
Ogun maa baiye jẹ o. (Que la guirra no destruye el mundo)
Ọtẹ sọbi-nu. (Las conspiraciones se hecha a peder de nacer)
Ọtẹ ntọmọ eniyan mọlẹ. (Las conspiraciones esta pisando a las gentes del mundo al suelo)
A difa fun Ọlọfin. (Se adivino Ifa para Ọlofin)
Nijọ tiwọn ni ko rubọ nitori ogun. (El dia que le dijieron que haga el sacrificio por la guierra/batalla)
Kole baa sẹgun. (Para que puede vencer)
O kọ, ko rubo. (Se nego en hacer el sacrificio)
Esu aisẹbọ. (La tentacion de no hacer el sacrificio)
Ẹgba aiteru. (La paralisis de no apasiguar a Esu pronto)
Ohun lomu kogun koleỌlọfin. (Por eso la guierra/batalla capturo a la casa de Ọlofin)

Ọba ni n jẹ Ọlọfin, wọn niki Ọlọfin o rubọ, wipe ogun n bọ, ki o le baa sẹgun, ki gbogbo nkan maa baa daru
lakoko ti o wa lori oye yii o. Ki o ni AGBO KAN lẹbọ nibẹ, ki o ni ORUKO KAN lẹbọ nibẹ, ki o ni AKUKỌ
ADIẸ KAN lẹbọ nibẹ, ki o ni ẸYIN ADIẸ MẸRINDINLOGUN lẹbọ nibẹ. Ọlọfin kọ ko rubọ. O pe Awo leke. O
pe Esu lole. O wo ọrun yanyanyan bi ẹnipe ilẹ ko ni su mọ.
Nijọ kan, ni wahala dade, ere ni, awada ni, lo ba di ogun, niwọn ba n yinbọn si ara wọn. Bayi ni ilu yii se
parẹ titi doni. Bayi ni ogun se ko ilu Ọlọfin. Ifa niki eleyii o rubọ silẹ de ogun ti n bọ yi, tiko ba rubọ silẹ de
ogun yi, ilu yi yoo parẹ mọ eleyii lori ni. Nigba ti ogun yi ba pari tan, ti o wa gbera lọ silu kan, ko lee darapọ
mọ awọn ara ilu, ko si lee jọba le wọn lori, ọba meji ko le si ninu ilu kan. Ni o wa n kabamọ, ni o wa n sẹsẹ
ranti gbogbo ohun tawọn awo sọ. O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn Awo tawọn wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn Awo tawọn sọ:

Ọlọfin era Rey, le dijieron que debe hacer el sacrificio porque le viene guierra/batalla enfrente, para que
puede vencer, para que no capturan la ciudad durante su reino. Ifa dice que debe tener UN CHIVO en su
sacrificio, que debe tener UNA CABRA MACHO en su sacrificio, que debe tener UN GALLO en su sacrificio,
que debe tener DIECISIES HUEVOS DE GALLINA en su sacrificio. Ọlọfin nego en hacer el sacrificio. Ọlọfin
llamo a Awo mentiroso. Llamo a Esu ladron. Miro al cielo tan brillante como que no iba a hacer de noche.
Un dia, ocurrio problema en la ciudad, enseguida este problema se convertio en guierra, empezaron a
matarse entre ellos con rifles. Asi fue como esta ciudad desaparecio. Asi fue como la guierra capturo la
ciudad de Ọlọfin. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio ante mano para esta guierra que le viene
enfrente, si esta persona no hace el sacrificio ante mano para esta guierra que le viene enfrente, su
ciudad/casa se destruira en su presencia. Cuando termino la guirra, Ọlọfin se fue a otra ciudad, Ọlọfin no
puede mezclarse con las gentes de esa ciudad, tampoco puede ser el Rey sobre ellos, porque esa ciudad tiene
su rey y dos Reyes no pueden estar en una ciudad. Ọlọfin empezo a arepentirse que asi mismo lo han
adivinados y cantados sus Awos; QUE:

Irẹtẹ Iwori awo aiye. (Irete-Iwori el awo del mundo)


Ogun maa baiye jẹ. (Que la guierra no destruye el mundo)
Ọtẹ sọbi-nu. (Las conspiraciones se hecha a peder de nacer)
Ogun maa baiye jẹ o. (Que la guirra no destruye el mundo)
Ọtẹ sọbi-nu. (Las conspiraciones se hecha a peder de nacer)
Ọtẹ ntọmọ eniyan mọlẹ. (Las conspiraciones esta pisando a las gentes del mundo al suelo)
A difa fun Ọlọfin. (Se adivino Ifa para Ọlofin)
Nijọ tiwọn ni ko rubọ nitori ogun. (El dia que le dijieron que haga el sacrificio por la guierra/batalla)
Kole baa sẹgun. (Para que puede vencer)
O kọ, ko rubo. (Se nego en hacer el sacrificio)
Esu aisẹbọ. (La tentacion de no hacer el sacrificio)
Ẹgba aiteru. (La paralisis de no apasiguar a Esu pronto)
Ohun lomu kogun koleỌlọfin. (Por eso la guierra/batalla capturo a la casa de Ọlofin)

ASẸ-IFÁ:- Bogun se kole Ọlọfin niyi. Ifa ni keleyii TETE rubọ silẹ dogun ti nbọ niwaju rẹ yi, kole ba a sẹgun
nigba togun yi bade. Ifa ni koni AGBO KAN lẹbọ nibẹ, koni ORUKỌ KAN lẹbọ nibẹ, koni ẸYIN ADIẸ
MẸRINDINLOGUN lẹbọ nibẹ

ASẸ-IFÁ:- Asi fue como la guierra capturo la ciudad de Olokun. Ifa dice que esta persona debe hacer
URGENTEMENTE el sacrificio ante-mano para esta guierra que le viene enfrente, para que puede vencer
cuando llega esta batalla/guierra. Ifa dice que debe tener UN CHIVO en su sacrificio, que debe tener UNA
CABRA MACHO en su sacrificio, que debe tener UN GALLO en su sacrificio, que debe tener DIECISIES
HUEVOS DE GALLINA en su sacrificio.

ẸSẸ KEJI.

Ire gbogbo. (Todas las bendiciones)

Ifa ni keleyii lọ TẸFA nibẹ, kigbesi aiye-rẹ le baa rọrun. Kolọ TẸFA, kole baa rojutu gbogbo ohun to nsẹlẹ
nigbesi aiye eleyii. Teleyii ko balọ tẹfa, yoo kan ma se gbogbo nkan lasan ni, koni rojutu igbesi aiye rẹ. Eleyii
yoo sa ma rii wipe ẹnikan nkọle, ẹnikan nse nkan dada, eleyi koni rojutu igbesi aiye rẹ, gbogbo nkan ti daru
meleyii lọwọ.
Teleyii koba tẹfa, yoo kan ma wa nibẹ ni, yoo ma fọdun yan ọdun ni, wipe lọdun to nbọ, oun fẹ se nkankan,
wipe bawo lọdun yi se wa ribi tesin. Ifa ni keleyii lọ TẸFA o, to bafẹ rojutu igbesi aiye re. Teleyii bati tẹfa,
yoo rojutu igbesi aiye rẹ, oun na yoo wa dẹni iyi lawujọ, ti yoo ma pasẹ feniyan lawujọ, ti yoo dọlọla. Ibi tifa
wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe INICIARSE EN IFA para que puede vivir su vida pacificamente y con
tranquilidad. Que debe INICIARSE EN IFA para en contrar solucion a los problemas de su vida. Si esta
persona no se inicia en Ifa, estara haciendo todas las cosas sin frutos y no tendra solucion a los problemas
de su vida. Ifa dice que esta persona estara viendo que los demas personas que estan comprando casas,
edificando casas, haciendos cosas buenas y no tendra solucion a los problemas de su vida.
Si esta persona no inicia en Ifa, estara alli ano tras ano para nada. Ifa dice que esta persona debe
INICIARSE EN IFA, si quiere encontrar solucion a los problemas de su vida. Si esta persona se inicia en Ifa,
encontrara soluciones a los problemas de su vida, el tambien sera una persona impotante en la sociedad,
mandara a las gentes en la sociedad y sera una perona rica. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Jiji timo ji lakọkọ. (Nada mas que me levanto la primera vez)


Mo ngbọ tereku-tereku. (Estuve oiendo “tereku-tereku”)
Moni kinni ndun bayi. (!Pregunte por lo que estaba sonando asi!)
Wọn ni Irẹ ”Irẹtẹ” ni ntẹ Iwori nifa. (Dijieron que el grillo ”Irẹtẹ” estaba iniciando a
IWORI en Ifa)
Jiji timo ji lekeji. (Cuando me levanter por la segunda vez)
Mo ngbọ tereku-tereku. (Estuve oiendo “tereku-tereku”)
Moni kinni n dun bayi. (!Pregunte por lo que estaba sonando asi!)
Wọn ni Irẹ ”Irẹtẹ” ni n tẹ Iwori nifa. (Dijieron que el grillo ”Irẹtẹ” estaba iniciando a IWORI
en Ifa)
Moni Ifa ni alaba, alasẹ Orisa. (Dije que Ifa es el consejero y el que manda/ dar
bendiciones a los Orisas)
Asẹ naa niwọn fun Agbe, tofi ni dudu. (Ese mando/bendicion es lo que dieron al pajaro de
Agbe, por eso tiene el color negro)
Towa nyẹyin funfun. (Y esta dando huevos blancos)
Asẹ naa niwọn fun Aluko, tofi ni pupa. (Ese mando/bendicion es lo que dieron al pajaro de
Aluko, por eso tiene el color rojo)
Towa nyẹyin funfun. (Y esta dando huevos blancos)
A dia fun Ọrunmila Bara Agbọnmiregun. (Se adivino Ifa para Ọrunmila Bara Agbọnmiregun
Wọn niki baba o ru IGBA OLUYAYA, OBI ỌPỌLỌPỌ, pẹlu ẸGBAWA OWO lẹbọ. (Dijieron al padre que
debe hacer el sacrificio con CALABAZA DE OLUYAYA, MUCHAS COLAS con DOS MIL DE DINERO)
Baba gbọ riru, o ru. (El padre oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Ẹnu Ọrunmila ni Olodumare fasẹ si. (Olodumare dio el mando/bendicion a la boca de
Ọrunmila)
Ifa dalaba o, o dalasẹ. (Ifa se convertio en el consejero, se convertio en el
mando)

Nigba tiwọn ni k’Ọrunmila o rubọ, wipe t’Ọrunmila bati rubọ, wipe koni dero ẹyin o. Wọn ni k’Ọrunmila o
si TẸFA o. Ni Ọrunmila ba rubọ, loba se gbogbo nkan tiwọn ni kose. Ọrunmila ba TẸFA, bi Eledumare se
ko gbogbo asẹ f’Ọrunmila niyi, ti nsakoso gbogbo ile aiye. Ti Ọrunmila bani bayi ni, bẹẹ ni yoo ri. Ti
Ọrunmila bani bayi ni kẹ gbalọ, bẹẹ nani. BI Ọrunmila se dalaba lasẹ titi doni niyi. Ọrunmila ni Olodumare
ko gbogbo asẹ fun. Ni Ọrunmila ba jolori gbogbo awọn nkan t’Olodumare da sode isalaye.
Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kosi lọ TẸFA nibẹ. Ifa leleyii yoo jolori ile tabi olori ilu, gbogbo ohun teleyii
basọ niwọn yoo sima gba seleyii lẹnu. Ni Ọrunmila ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si
nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo tawọn wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo tawọn so:
Dijieron al Ọrunmila que debe hacer el sacrificio para no convertirse en el ultimo la cola entre las
gentes. Dijieron al Ọrunmila que debe INICIARSE EN IFA. Ọrunmila hizo el sacrificio y todos los
demas cosas que le mandaron a hacer. Ọrunmila se INICIO EN IFA, asi fue como Olodumare dio todo
el mando/bendicion a la boca de Ọrunmila, Ọrunmila empezo a mandar el mundo. Todos lo que dice
Ọrunmila se hace realidad. Asi fue como se convertio en el consejero, se convertio en el que manda sobre
todas las cosas en el mundo hasta la fecha de hoy. Olodumare entrego el mando al Ọrunmila. Ọrunmila se
convertio en el jefe sobre todas las cosas que Ọlodumare crio en el mundo.
Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe INICIARSE EN IFA. Ifa dice que esta persona sera el
jefe de una casa o ciudad y todos lo que dice esta persona sera aceptados por las gentes. Ọrunmila empezo a
alabar a sus awos y sus awos alabando a Ifa; Que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Jiji timo ji lakọkọ. (Nada mas que me levanto la primera vez)


Mo ngbọ tereku-tereku. (Estuve oiendo “tereku-tereku”)
Moni kinni ndun bayi. (!Pregunte por lo que estaba sonando asi!)
Wọn ni Irẹ ”Irẹtẹ” ni ntẹ Iwori nifa. (Dijieron que el grillo ”Irẹtẹ” estaba iniciando a
IWORI en Ifa)
Jiji timo ji lekeji. (Cuando me levanter por la segunda vez)
Mo ngbọ tereku-tereku. (Estuve oiendo “tereku-tereku”)
Moni kinni n dun bayi. (!Pregunte por lo que estaba sonando asi!)
Wọn ni Irẹ ”Irẹtẹ” ni n tẹ Iwori nifa. (Dijieron que el grillo ”Irẹtẹ” estaba iniciando a IWORI
en Ifa)
Moni Ifa ni alaba, alasẹ Orisa. (Dije que Ifa es el consejero y el que manda/ dar
bendiciones a los Orisas)
Asẹ naa niwọn fun Agbe, tofi ni dudu. (Ese mando/bendicion es lo que dieron al pajaro de
Agbe, por eso tiene el color negro)
Towa nyẹyin funfun. (Y esta dando huevos blancos)
Asẹ naa niwọn fun Aluko, tofi ni pupa. (Ese mando/bendicion es lo que dieron al pajaro de
Aluko, por eso tiene el color rojo)
Towa nyẹyin funfun. (Y esta dando huevos blancos)
A dia fun Ọrunmila Bara Agbọnmiregun. (Se adivino Ifa para Ọrunmila Bara Agbọnmiregun
Wọn niki baba o ru IGBA OLUYAYA, OBI ỌPỌLỌPỌ, pẹlu ẸGBAWA OWO lebo. (Dijieron al padre que
debe hacer el sacrificio con CALABAZA DE OLUYAYA, MUCHAS COLAS con DOS MIL DE DINERO)
Baba gbọ riru, o ru. (El padre oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Ẹnu Ọrunmila ni Olodumare fasẹ si. (Olodumare dio el mando/bendicion a la boca de
Ọrunmila)
Ifa dalaba o, o dalasẹ. (Ifa se convertio en el consejero, se convertio en el
mando)
Ko pẹ, ko jinna, (Pronto y no tan lejano)
Ifa wa ba ni ijẹbutu ire. (Ifa ven a encontranos en la celebracion de bendicion)
Ijẹbutu ire, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion se encuentra uno a los
pies del Rey de los Orisas)
ASẸ-IFÁ:- B’Ọrunmila se jolori gbogbo awọn t’Olodumare da sode isalaye niyi. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ,
kosi lọ TẸFA nibẹ, Ifa leleyii yoo jolori ile tabi olori ilu, gbogbo ohun teleyii basọ niwọn yoo si ma gba seleyii
lẹnu. Ifa ni keleyii o ni IGBA OLUYAYA, OBI ỌPỌLỌPỌ, pẹlu ẸGBAWA OWO lẹbọ.

ASẸ-IFÁ:- Asi fue como Ọrunmila se convertio en el consejero, se convertio en el que manda sobre todas
las cosas en el mundo hasta la fecha de hoy. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, que debe
INICIARSE EN IFA. Ifa dice que esta persona sera el jefe de una casa o ciudad y todos lo que dice esta
persona sera aceptados por las gentes. Ifa dice que esta persona debe tener CALABAZA DE OLUYAYA,
MUCHAS COLAS con DOS MIL DE DINERO en su sacrificio.

14.4. IRẸTẸ-DI (ODI)

ẸSẸ KINNI.

Ifa ni keleyii o rubọ larin ọmọ iya meji, koma ba jẹpe nigba toba dara fẹnikan, koni dara fẹni keji, kole ba
dara fun gbogbo wọn papọ.Boya baba wọn, o le jẹyawo meji loni, ẹnikan bọkunrin, ẹnikan bobinrin, kiwọn
o rubo, koma ba jẹ pọmọ ẹnikan yoo dara, ọmọ ẹni-keji koni dara, kiwọn o rubọ, kole dara fun gbogbo wọn
papọ. Ifa ni tiwọn bati rubọ nibẹ, tawọn babalawo bawọn jewe Ifa, Ifa ni ti gbogbo wọn ma dara. Ibi tifa wa
gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio entre dos hermanos de la misma madre, para que no sea el
caso que la vida le va ir bien para uno y mal para el otro, para que la vida les vayan bien a los dos juntos.
Tambien puede ser que el padre de esta persona tiene dos esposas, una esposa tiene hijo y la otra esposa
tiene hija, deben hacer el sacrificio, para que no sea el caso que la vida le va ir bien para el hijo de una
esposa y mal para mal para la hija de la otra esposa, para que la vida les vayan bien a los hijos de las dos
esposas juntos. Ifa dice que si hacen el sacrificio y se acercan a los babalawos para que les preparan las
hierbas de Ifa, Ifa dice que la vida ira bien a los dos hermanos juntos. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Tẹdi-tẹdi awo Ẹsin. (Tẹdi-tẹdi Awo del caballo)


Lo difa fun Ẹsin. (Adivino Ifa para el caballo)
A bu fun Ẹ-nla. (Tambien adivino Ifa para E-nla)
Eyiti nsọmọ iya-rẹ. (Que era su hermano de la misma madre)
Ẹbọ niwọn ni kiwọn o se. (Dijieron que deben hacer el sacrificio)
Kole ba dara funwọn papọ. (Para que la vida les vayan bien a los dos juntos)

Ẹsin ati Ẹ-nla, wọn ni kawọn mejeji o rubọ papọ, kolee ba jọ dara funwọn papọ. Ẹsin nikan lo rubọ nibẹ,
ohun niwọn kii fi jẹran Ẹsin titi doni. Ẹ-nla kọ, ko rubọ. Ohun ni Ẹ-nla se dẹran inu igbo. Ẹ-nla dabi malu, ti
yoo ga, ti yoo tobi. O kọ, ko rubọ. Ẹsin deniyan jingbinni ni tirẹ, o dọba, o nilaari. Nigba tire ile wọn de,
tiwọn fẹ jọba. Ẹ-nla tilọ soko ni tirẹ, kosi nile, o ti kuro nile. Ẹni tiwọn ba nile, niwọn mu tiwọn fi jọba. Ẹyin
o rohun tawọn awo wi, ohun tawọn awo sọ:

Dijieron al caballo y Ẹ-nla que deben hacer el sacrificio juntos, para que la vida les vayan bien a los dos
juntos. Solamente el caballo hizo el sacrificio, por eso no se come la carne del caballo hasta la fecha de hoy.
Ẹ-nla se nego en hacer el sacrificio, por eso se converrtio en el animal del bosque. Ẹ-nla es un animal como
una vaca, es alto y grande. Se nego en hacer el sacrificio. El caballo se convertio en una persona con
adornos, se convertio en el Rey y prospero. Cuando llego la bendicion de la casa de ellos para coronarse del
Rey de la casa. E-nla se fue al campo, no estaba en casa. Cogieron al caballo que encontraron en casa para
coronarle como el Rey de la casa. Ustedes no han vistos lo que los awos han adivinados y cantados; QUE:

Wọn ni: Hinn. (Dijieron que: Hinn)


Tẹdi-tẹdi awo Ẹsin. (Tẹdi-tẹdi Awo del caballo)
Wọn ni: Hinn. (Dijieron que: Hinn)
Lo difa fun Ẹsin. (Adivino Ifa para el caballo)
Wọn ni: Hinn. (Dijieron que: Hinn)
A bu fun Ẹ-nla. (Tambien adivino Ifa para E-nla)
Eyiti nsọmọ iya-rẹ. (Que era su hermano de la misma madre)
Ẹbọ niwọn ni kiwọn o se. (Dijieron que deben hacer el sacrificio)
Kole ba dara funwọn papọ. (Para que la vida les vayan bien a los dos juntos)
Ẹsin gbẹbọ nibe, o rubọ (El caballo hizo el sacrificio)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino do Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹyin o wa rohun jingbinni lọrun Ẹsin. (Ustedes no han vistos el caballo repletos de adornos en
su cuello)
Esu aisẹbọ. (La tentacion de no hacer el sacrificio)
Ẹgba aiteru. (La paralisis de no apasiguar a Esu pronto)
Ohun lo muki Ẹ-nla dẹran igbo. (Por eso Ẹ-nla se convertio en el animal del bosque)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ laarin ọmọ iya meji, kiwọn o rubọ nibẹ, koma ba a jẹpe nigba toba dara
fẹnikan, koni dara fẹnikan loju irẹtẹ-di.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio entre dos hermanos de la misma madre, deben
hacer el sacrificio juntos, para que no sea el caso de que la vida le va ir bien para uno y mal para el otro,
para que la vida les vayan bien a los dos juntos.
ẸSẸ KEJI.

Ire gbogbo. (Todas las bendiciones)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, ki gbogbo-ise rẹ lee baa ma soju rẹ. Itumọ gbogbo-ise ni wipe, teleyi ba bimọ,
tọmọ rẹ fẹ segbeyawo, kole soju rẹ, kiwọn ma seyawo, kiwon ma bimọ loju eleyii, kise rẹ ma dara, ki gbogbo
ọmọ rẹ duro dada. Keniyan ma jere gbogbo isẹ teniyan ba fọwọ rẹ se laiye. Ifa ni keleyii o rubọ ki gbogbo-ise
rẹ lee baa ma soju rẹ, kawọn ọmọrẹ dara loju ararẹ. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que puede estar presente a la hora de disfrutar de sus
esfuerzos. Disfrutar de esfuerzo quiere decir que si esta persona tiene hijo y su hijo quiere casarse, para que
esta persona puede presenciar la boda de su hijo y estar presente a la hora del nacimiento de sus nietos,
para que le vaya bien en su trabajo y para que le vayan bien a sus hijos. Para que esta persona puede sacar
los frutos de sus esfuerzos en la vida. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que puede estar
presente a la hora de disfrutar de sus esfuerzos. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ada tẹdi ọgẹdẹ mọlẹ. (El machete piso la nalga del platano al suelo)
A dia fun Ipakọ. ( Se adivino Ifa para el cogote)
Eyiti nlọ re sowo ọmọ lori ẹni. (El que iba a hacer el comercio de hijo sobre la estera)
Wọn ni toba ti rubọ. (Dijieron que si hace el sacrifio)
Gbogbo ọmọ ti yoo ma wale aiye, koni sẹyin rẹ. (Que todos los hijos que van a venir al mundo, no sera
detras del cogote)
Ipakọ gbọ riru, o ru. (Cogote oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ o hahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que dsalio en el tablero de la adivinacion)

Wọn ni kipakọ o rubọ, ki gbogbo-ise rẹ lee ma soju rẹ. Ipakọ rubọ. Nigba tipakọ ti rubọ tan, tipakọ bati
fẹyin ti bayi, gbogbo nkan nipakọ yoo ma ri. Bi gbogbo nkan se nsoju ipakọ niyi. Nipakọ ba nyin awọn awo
wipe oun ma dupẹ. Ẹyin o wo wipe gbogbo Ifa tawo ki loma sẹ. Gbogbo ohun tawọn babalawo sọ, gbogbo
rẹ loma ri bẹẹ. Nipakọ ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ
lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Dijieron al cogote que debe hacer el sacrificio, para que puede estar presente a la hora de disfrutar de
sus esfuerzos. Cogote hizo el sacrificio. Cuando el cogote termino de hacer el sacrificio, cada vez que el
cogote se apoya en algo, el cogote tiene todas las cosas a su vista. Asi empezo como el cogote empieza a estar
presente en todas las cosas. El cogote empezo a alabar y dar las gracias a sus awos. Ustedes no han vistos
que el Ifa que el awo adivino se hizo realidad. Todos lo que los babalawos han dichos, se han hechos
realidades. El cogote estaba feliz, empezo a bailar y cantar; Que asi mismo lo han adivinados y
cantados sus awos; QUE:

Ada tẹdi ọgẹdẹ mọlẹ. (El machete piso la nalga del platano al suelo)
A dia fun Ipakọ. ( Se adivino Ifa para el cogote)
Eyiti nlọ re sowo ọmọ lori ẹni. (El que iba a hacer el comercio de hijo sobre la estera)
Wọn ni toba ti rubọ. (Dijieron que si hace el sacrifio)
Gbogbo ọmọ ti yoo ma wale aiye, koni sẹyin rẹ. (Que todos los hijos que van a venir al mundo, no sera
detras del cogote)
Ipakọ gbọ riru, o ru. (El cogote oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ o hahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que dsalio en el tablero de la adivinacion)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino do Opo, pelegrino de Ọffa)
Ire gbogbo soju Ipakọ nile aiye. (El cogote esta presente en todas las bendiciones de su vida)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino do Opo, pelegrino de Ọffa)
Ire gbogbo soju Ipakọ nile aiye. (El cogote esta presente en todas las bendiciones de su vida)
Ko pẹ o, ko jinna. (Pronto y no tan lejano)
Ẹ wa bani nijẹbutu ire. (Ustedes ven a encontranos en la celebracion de bendicion)
Ijẹbutu ire, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion se encuentra uno a los pies del Rey
de los Orisas)

ASẸ-IFÁ:- Bire gbogbo se nsoju ipakọ niyi, oju rẹ nto gbogbo nkan. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa nire
gbogbo eleyii yoo soju eleyii.

ASẸ-IFÁ:- Asi empezo como el cogote empieza a estar presente de todas las cosas, sus ojos pueden ver
todas las cosas. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona estara presente en
todas las bendiciones de su vida.

14.5. AATẸ-ROSUN (IRẸTẸ-IROSUN)

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo ogun buruku. (Investigar las guierras/batallas mala)


Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kọran buruku ma ba yale eleyii. Kọran buruku ma yale tọ eleyii, ko rubọ nibẹ loju
Irẹtẹ-Irosun. Ifa ni orun teleyii nsun ko dara, Ifa leleyii nlala, Ifa ni ko rubọ nibẹ, kọran buruku ma baa yale
eleyii wa. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que los asuntos malos no entra en la casa/vida de esta
persona, para que la guierra/batalla mala no entra en la casa/vida de esta persona. Ifa dice que esta persona
debe hacer el sacrificio en el signo de Irẹtẹ-Irosun. Ifa dice que esta persona no esta dormiendo bien, Ifa
dice que esta persona esta teniendo suenos malos cuando duerme. Ifa dice que debe hacer el sacrificio para
que los asuntos malos no entra en su casa. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Irẹtẹ-Irosun. (Irẹtẹ-Irosun)
Ajankoro dugbẹdugbẹ. (Ajankoro dugbẹdugbẹ)
A dia fun Ọlọfin. (Se adivino Ifa para Ọlọfin)
Ọba Ajakaiye. (El Rey Ajakaye)
Tiwọn ni ko rubọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Nitori ajalu ọran. (Para que no entra en problemas o asuntos malos)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)

Wọn ni k’Ọlọfin, Ọba Ajakaye o rubọ, kọran buruku ma ba yale rẹ. Ọlọfin ni orun toun nsun ko dara. Ni
Ọlọfin ba kesi gbogbo awọn awo wipe kiwọn dafa foun. Nigba tiwọn dafa fun-un. Wọn lorun to sun ko dara,
wipe ko rubọ kọran buruku ma ba yale rẹ, wọn yan-an lẹbọ. Ọlọfin rubọ, o si se gbogbo ohun tiwọn ni kose
ni kiakia.
Bayi ni wahala kan se sẹlẹ ninu ilu, bi wahala yi se sẹlẹ to, wahala yii ko denu ile Ọlọfin Ajakaye, ọran
kankan ko wọle Ọlọfin. Ọlọfin ni Olodumare loma ni koun tete rubọ, wipe gbogbo isẹlẹ buruku to sẹlẹ larin
ilu yi, koba dele oun naa o.
Iji lo sẹlẹ ninu ilu, to bẹrẹ sini gbe gbogbo ile lọ ninu ilu yi. Sugbọn ẹbọ t’Ọlọfin Ajakaye ru, ni kojẹ kiji yi
dele Ọlọfin, niko jẹ kiku wọle rẹ, niko jẹ kọran wọle rẹ. Iji to jalu wọle lọ, o paniyan lọ ni. Ni Ọlọfin ba njo, o
nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo tawọn wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo
tawọn sọ:

Dijieron al Ọlọfin, el Rey Ajakaye que debe hacer el sacrificio, para que los asuntos malos no entran en su
casa. Ọlọfin dijo que los suenos que estaba teniendos no son buenos. Ọlọfin llamo a todos los awos para
consultarse con Ifa. Cuando consultaron al Ọlọfin, le dijieron que estaba teniendo suenos malos, le dijieron
que debe hacer el sacrificio, para que los asuntos malos no entran en su casa y le mandaron todos lo que
debe tener en su sacrificio. Ọlọfin hizo el sacrificio y todos lo que le mandaron a hacer rapidamente.
Ocurrio asuntos malos dentro de la ciudad, estos asuntos malos no entro en la casa de Ọlọfin Ajakaye, no
hubo problema en la casa de Ọlọfin. Ọlọfin dijo que fue Olodumare que le hizo hacer el sacrificio
rapidamente porque estos asuntos malos hubieran entrados en su casa.
Hubo una tormenta en la ciudad que se llevo todas las casas de la ciudad, pero esta tormenta no entro en la
casa de Ọlọfin Ajakaye. Porque el sacrificio que Ọlọfin hizo, se levanto y se acepto. Su sacrificio no déjà que
la tormenta entra en la casa de Ọlọfin, su sacrificio no déjà que la muerte entra en la casa de Ọlọfn, su
sacrificio no déjà que los problemas entran en la casa de Ọlọfin. La tormenta que entro en la ciudad y
derumbo las casas, la tormenta mato a las gentes. Ọlọfin estaba feliz, empezo a bailar y cantar; Que asi
mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Irẹtẹ-Irosun. (Irẹtẹ-Irosun)
Ajankoro dugbẹdugbẹ. (Ajankoro dugbẹdugbẹ)
A dia fun Ọlọfin. (Se adivino Ifa para Ọlọfin)
Ọba Ajakaiye. (El Rey Ajakaye)
Tiwọn ni ko rubọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Nitori ajalu ọran. (Para que no entra en problemas o asuntos malos)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
Aseyin wa o, aseyin bọ. (Despues de todos)
Ogun ọran buruku ma re kọja nile Ọlọfin. (Problemas o asuntos malos no entro en la casa de
Ọlọfin)
Ifa ma majẹ kogun buruku sọọjọ sile ẹni. (Ifa no déjà que los problemas o asuntos malos
entran en la casa de uno)

ASẸ-IFÁ:- Ifa logun buruku koni sọọjọ sile eleyii, ko rubọ nibẹ. Ifa lajalu koni beleyii, ko rubọ silẹ, kajalu
buruku to nbọ yi ma yale eleyii.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que los asuntos malos no van a entrar en la casa de esta persona. Ifa dice que esta
persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que los problemas y asuntos malos no van a caer encima de esta
persona. Ifa dice que debe hacer el sacrificio ante-mano, para que los problemas y asuntos malos que
vienen, no entran en la casa de esta persona.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Investigar el vencimiento de enimigo)

Ifa laarin ọta leleyii wa. Ifa ni keleyii o rubọ isẹgun laarin wọn, kole baa sẹgun laarin wọn. Ifa lawọn ọta lo
yeleyii ka, keleyii o rubọ nibẹ. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:
Ifa dice que esta persona esta en el medio de los enimigos. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio
para vencer en el medio de sus enimigos. Ifa dice que los enimigos estan alrededor de esta persona y que
debe hacer el sacrificio. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Irẹtẹ-Irosun. (Irẹtẹ-Irosun)
Aiku lẹgbọn iwa. (La longetividad/al no murirse es el hermano mayor de la caracter)
Toba wale aiye. (Si viene al mundo)
Ẹ fiwa funmi. (Ustedes dame la caracter)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Baba yoo tẹ budo saarin ọta. (El padre iba a establecerse en el medio de los enimigos)
Nibi tiwọn ti nfojoumọ pawọn jẹ. (En el lugar donde se matan las gentes todos los dias)
Bi ẹniti npẹran. (Como alguien que estaba matando a los animales)
Ẹbọ niwọn niki baba o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ifa wa bani laarin iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio del vencimiento)
Aarin iṣẹgun nla a bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies del Rey de
los Orisas)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa laarin ọta leleyii wa. Tiko ba rubọ, ko sunmọ awọn babalawo kiwọn
jewe Ifa fun-un, wọn koni jẹ keleyii o nilari loju Aatẹ-rosun.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona esta rodeado de
enimigos, que esta persona ersta en el medio de los enimigos. Ifa dice que si esta persona no hace el
sacrificio y acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas cde Ifa, Ifa dice que no le van a dejar
prosperar en el signo de Aatẹ-rosun.

14.6. IRẸTẸ-ỌLỌTA (ỌWỌNRIN)

ẸSẸ KINNI.
Ayẹwo ọfọ. (Investigar las pedidas)

Irẹtẹ-ọlọta ni a npeni Irẹtẹ -Ọwọnrin, a tun npee ni “A tẹẹ lẹsẹ mọlẹ, o wọnri sinu”. Ifa lọna ọla yoo si feleyii.
Ifa ni keleyii o rubọ, ko sunmọ awọn babalawo dada, kiwọn sefa fun-un, kire ọla naa ma bọ meleyii lọwọ.
Ifa leleyii yoo rọna ọla, ti yoo rowo pupọ, tojẹ powo yii koni parẹ lailai. Sugbọn teleyii ko bati rubọ nibẹ,
eleyii yoo ma gburo owo yini, ti yoo ma wo eleyii lọọkan bayi, koni tẹ eleyii lọwọ. Ifa ni keleyii lọ BỌFA nibẹ
ni. Ifa ni kawọn babalawo beleyii BỌFA nibẹ, kọla yii le teleyii lọwọ, ti yoo le na ọla naa titi dọjọ alẹ.
Ohun ta npeni ọla ni keniyan ni laari. Teleyii koba rubọ, yoo sọla yii nu. Keleyii RUBỌ FESU nibẹ, nitoripe
wọn lee peleyii fun Aarẹ-ilu, sugbọn takoko bato, wọn lee yọrukọ rẹ pada wipe wọn koni fi jaarẹ-ilu mọ,
toba kusẹju diẹ. Sugbọn teleyi bati rubọ, wọn yoo fi jaarẹ-ilu naa.
Ifa ni teleyii bati rubọ, ire naa ma teleyii lọwọ. Ifa leleyii yoo la, yoo nilaari loju Irẹtẹ-ọlọta. Ibi tifa wa gba
tofi sọ bẹẹ re o, wipe eleyii yoo ma wo ọla lọọkan bayi ni, wipe ọla naa yoo bọ meleyii lọwọ, tiko bati rubọ
FESU nibẹ. Esu ni yoo deleyii laamu, ti yoo dina ire yii meleyii, ti yoo dina ọla meleyii. Ifa na sọ pe:

Irẹtẹ-ọlọta es lo que llamamos Irẹtẹ -Ọwọnrin, tambien lo llamamos “A tẹẹ lẹsẹ mọlẹ, o wọnri sinu” (Le
pisamos los pies al suelo y se movio la cabeza para dentro, que tenia rencor). Ifa dice que el camino de las
riquezas va a abrir para esta persona. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe acercarse a los
babalawos muy bien, para que los babalawos le preparan las hierbas de Ifa, para que no sele escapa esa
bendicion del camino de las riquezas.
Ifa dice que esta persona va a encontrar el camino de las riquezas, va a conseguir mucho dinero que no
desaparecera jamas. Pero si esta persona no hace el sacrificio, esta persona va a estar oiendo de ese dinero
desde lejos, va a estar viendo ese dinero desde lejos y que ese dinero no llegara a sus manos jamas. Ifa dice
que esta persona debe DAR DE COMER A IFA. Ifa dice que los babalawos le ayudan a DAR DE COMER A
IFA, para que esas riquezas llega a las manos de esta persona y para que esas riquezas le dura hasta los
ultimos dias de su vida.
Las prosperidades es lo que llamamos las riquezas. Si esta persona no hace el sacrificio, pedera las riquezas.
Ifa dice que esta persona debe DAR DE COMER A ESU, pueden llamar a esta persona para presentarse
como el candidato al presidente del pais, cuando falta unpoco para la eleccion, cambiaran su nombre como
el candidato al presidente del pais. Pero si esta persona hace el sacrificio, sera elegido como el presidente del
pais.
Ifa dice que si esta persona debe hace el sacrificio, conseguira la bendicion. Ifa dice que esta persona sera
rico y prosperara en el signo de Irẹtẹ-ọlọta. Ifa lo dice con este verso que escapara las riquezas a esta
persona, si NO DAR DE COMER A ESU. Es esu que va estorbarle, es esu que va a bloquiar a esta persona, es
esu que va a bloquiarle en el camino de las bendiciones, es esu que va a bloquiarle en el camino de las
riquezas de esta persona; QUE:

Ẹiyẹ yẹkẹ. (El pajaro que resvala)


Ẹiyẹ yẹtu. (El pajaro que se pone de pie)
Ẹiyẹ to yẹkẹ o, ẹiyẹ to yẹtu. (El pajaro que resvala, el pajaro que se pone de pie)
Tosi mọ pohun ọla nbẹ ninu rẹ. (El pajaro sabia que hay riqueza dentro de si)
A dia fun Alati-ẹluju. (Se adivino Ifa para Alati-ẹluju)
Eyi tiwọn lọdọdun nisẹ tan (El que le dijieron cada ano que la pobreza se acabara)
Alati-ẹluju ko rẹni a kosẹ ẹ fun mọ. (Alati-ẹluju ya no vio a quien puede pasarle su pobreza)
Pansa fọ. (Se rompio la aula)
Ẹiyẹ tun lọ. (El pajaro tambien se volo)

Ẹ o ri nkan bi. Alati-Ẹluju ọkunrin kan ni, ọkunrin yii ma ndẹ okun tofi ma nmawọn ẹiyẹ ninu igbo ni. Ni
ọjọ kan, Alati-Ẹluju wa dẹ okun, o mẹiyẹ kan, ẹiyẹ yii rẹwa pupọ. Ni Alati-Ẹluju ba mẹiyẹ yi wale. Nigba tesu
rẹiyẹ yii, ni Esu-Ọdara bawa ba Alati-Ẹluju. Esu ni, iwọ Alati-Ẹluju ti lowo o. Esu ni Alati-Ẹluju ti la. Esu
lawọn Ọba yoo ma wa sile Alati-Ẹluju lati kowo lẹiyẹ yi lori. Esu ni k’Alati-Ẹluju mati gbẹiyẹ yii fawọn Ọba o.
Esu ni k’Alati-Ẹluju masọ poun yoo wa gbẹiyẹ bawọn nile ni.
Esu batun salọ sile Ọba Alara. Esu niwọ Ọba Alara, Esu lẹiyẹ kan nbẹ nile Alati-Ẹluju bayi, wipe ile iwọ Ọba
Alara loyẹ kẹiyẹ yi wa, o lẹiyẹ rẹwa pupọ. Ọba Alara lẹiyẹ kan wa nile Alati-Ẹluju. Esu lẹiyẹ naa wa nibẹ,
wipe ẹiyẹ naa rẹwa pupọ. Esu ni kọba Alara gbowo lẹiyẹ yi lori, ko tete lọ ba Alati-Ẹluju bayi.

Ni Esu batun kuro lọdọ Ọba Alara, lo batun salọ sọdọ Alati-Ẹluju. Esu sọfun Alati-Ẹluju wipe Ọba Alara ti
nbọ o, wipe o ti nkowo bọ o, wipe to bati kowo lẹiyẹ yii lori wipe oun fẹ rẹiyẹ yi, o ni k’Alati-Ẹluju o ma
gbowo yi lọwọ Ọba alara o, kosọ fun-un wipe oun yoo gbẹiyẹ yi wa bọba Alara nile ni o. Ọba Alara jẹkan
ninu awọn Ọlọja nisalaiye nigbayi. Ọba mẹrindinlogun lowa lode isalaye nigbayi.
Nigba tọba Alara wa ransẹ wa sile Alati-Ẹluju. O ni koma gbowo lọ, wipe oun yoo gbẹiyẹ yii bọba Alara nile
ni o. Esu tun ti salọ sile Ọba Ajero. Ikan ninu awọn Ọlọja lọba Ajero nisalaiye nigba yi. Esu lẹiyẹ kan nbẹ nile
Alati-Ẹluju bayi, wipe ile iwọ Ọba Ajero loyẹ kẹiyẹ yi wa, o lẹiyẹ rẹwa pupọ. Ọba Ajero lẹiyẹ naa nbẹ nile
Alati-Ẹluju. Esu lẹiyẹ naa wa nibẹ, wipe ẹiyẹ na rẹwa pupọ. Esu ni kọba Ajero ransẹ lọ sile Alati-ẹluju bayi,
ko kowo funwọn, wipe kiwọn baun rẹiyẹ yii wa.

Esu tun sa kuro lọdọ Ọba Ajero, o tilọ sile Alati-Ẹluju, wipe Ọba Ajero ti nkowo bọ o, wipe to bati kowo lẹiyẹ
yii lori wipe oun fẹ rẹiyẹ yi, o ni k’Alati-Ẹluju o ma gbowo yi lọwọ Ọba Ajero o, ko sọ fun-un wipe oun yoo
gbẹiyẹ yi wa bọba Ajero nile ni o.
Esu tun kuro lọdọ Alati-Ẹluju. Esu tun gbọdọ Ọloja miran lọ, ti a npeni Ọba Ọrangun Aga. Bọba Ajero se
ransẹ dọdọ Alati-Ẹluju, wọn sọrọ wipe iye bayi loun yoo tẹiyẹ yi. Alati-Ẹluju ni wipe kiransẹ yi ma rinso,
wipe oun koti gbowo bayi, wipe toun ba dọdọ Ọba Ajero, oun yoo gbowo, wipe kiranse yii ma rinso, oun
ngbẹiyẹ yii bọ.
Esu tun salọ sọdọ Ọba Ọrangun Aga. Esu niwọ Ọba Ọrangun Aga. Esu lẹiyẹ kan nbẹ nile Alati-Ẹluju bayi,
wipe ile iwọ Ọba Ọrangun Aga loyẹ kẹiyẹ yii wa, o lẹiyẹ rẹwa pupọ. Ọba Ọrangun Aga lẹiyẹ kan wa nile
Alati-Ẹluju. Esu lẹiyẹ naa wa nibẹ, wipe ẹiyẹ naa rẹwa pupọ. Esu ni kọba Ọrangun Aga gbowo lẹiyẹ yii lori,
ko tete lọ ba Alati-Ẹluju bayi. Ọba Ọrangun Aga ba kowo ran iransẹ wipe kiwọn o lọ rẹiyẹ yii wa.

Kiranse yi to dele Alati-Ẹluju. Esu tunti dele Alati-Ẹluju. Esu ni Ọba Ọrangun Aga nransẹ bọ pẹlu owo lati
rẹiyẹ yii o, wipe to bati kowo lẹiyẹ yii lori wipe oun fẹ rẹiyẹ yi, o ni k’Alati-Ẹluju o ma gbowo yi lọwọ Ọba
Ọrangun Aga o, ko sọ fun-un wipe oun yoo gbẹiyẹ yii wa ba Ọba Ọrangun Aga nile ni o.
Biransẹ Ọba Ọrangun Aga se dọdọ Alati-Ẹluju, wọn sọrọ wipe iye bayi loun yoo tẹiyẹ yii. Alati-Ẹluju ni wipe
kiranse yi ma rinso, wipe oun koti gbowo bayi, wipe toun ba dọdọ Ọba Orangun Aga, oun yoo gbowo, wipe
kiranse yi ma rinso, oun ngbẹiyẹ yi bọ. Alati-Ẹluju sa nparọ fun gbogbo wọn.
Esu batun gbọdọ Ọba Alaka-Esu lọ. Esu niwọ Ọba Alaka-Esu. Esu lẹiyẹ kan nbẹ nile Alati-Ẹluju bayi, wipe ile
iwọ Ọba Alaka-Esu loyẹ kẹiyẹ yii wa, o lẹiyẹ rẹwa pupọ. Ọba Alaka-Esu lẹiyẹ kan wa nile Alati-Ẹluju. Esu
lẹiyẹ naa wa nibẹ, wipe ẹiyẹ naa rẹwa pupọ. Esu ni kọba Alaka-Esu gbowo lẹiyẹ yi lori, ko tete lọ ba Alati-
Ẹluju bayi. Ọba Alaka-Esu ba kowo ran iransẹ wipe ko lọ rẹiyẹ yii wa.

Kiransẹ yi to dele Alati-Ẹluju. Esu tunti dele Alati-Ẹluju. Esu ni wipe Ọba Alaka-Esu nransẹ bọ pẹlu owo lati
rẹiyẹ yii o, wipe to bati kowo lẹiyẹ yii lori wipe oun fẹ rẹiyẹ yii, o ni k’Alati-Ẹluju o ma gbowo yi lọwọ Ọba
Alaka-Esu o, ko sọ fun-un wipe oun yoo gbẹiyẹ yi wa bọba Alaka-Esu nile ni o. Biranse Ọba Alaka-Esu se
dọdọ Alati-Ẹluju, wọn sọrọ wipe iye bayi loun yoo tẹiyẹ yi. Alati-Ẹluju ni wipe kiranse yi ma rinso, wipe oun
koti gbowo bayi, wipe toun ba dọdọ Ọba Alaka-Esu, oun yoo gbowo, wipe kiransẹ yii ma rinso, oun ngbẹiyẹ
yii bọ. Iransẹ Ọba Alaka-Esu balọ.
Esu tun lọ sọdọ ọlọja miran, besu se kakiri gbogbo awọn ọlọja mẹrindinlogun yii niyi. Esu batun lọ sọdọ
Alati-Ẹluju. Esu niwọ Alati-Ẹluju eti rẹ melo. Alati-Ẹluju leti meji loun ni. Esu ni kinni Alati-Ẹluju nfeti rẹ
gbọ. Alati-Ẹluju lọrọ loun nfeti oun gbọ. Esu ni Ọba Alara to kọkọ wa, wipe ibẹ ni k’Alati-Ẹluju ma gbẹiyẹ yii
lọ bayi. Esu ni Ọba Alara yoo fun Alati-Ẹluju lowo to pọ gidi.

Esu tunti lọ bọba Alara wipe ohun tiko jẹ k’Alati-Ẹluju gbẹiyẹ yii silẹ ni wipe, owo tọba Alara fẹ san fẹiyẹ yii
kere pupọ. Esu ni kọba Alara san ilọpo meji owo yii, nitoripe gbogbo awọn Ọlọja niwọn fẹ rẹiyẹ yii o, k’Alati-
Ẹluju le baa tẹiyẹ fun yin. Ọba Alara tiko ilọpo meji owo fun iransẹ rẹ wipe ko lọ b’Alati-Ẹluju, wipe iyekiye
ti Alati-Ẹluju bafẹ tẹiyẹ yii, wipe oun yoo rẹiyẹ yii o. Alati-Ẹluju siti kan pansa fẹiyẹ yii. Ohun ti njẹ pansa
nile-ẹiyẹ. Sugbọn pansa yii ko duro dada, ti pansa yi babọ sile, yoo fọ ni.
Bi Alati-Ẹluju se ngbẹiyẹ yii lọ, Esu tibọ sọna, o di Alati-Ẹluju loju. Alati-Ẹluju ko rina mọ, loba subu lulẹ, ni
pansa bafọ. Lẹiyẹ yii ba folọ sinu igbo pada. Bi Alati-Ẹluju ko seri nkankan mọ niyi. Esu dina mọ Alati-Ẹluju,
nitoripe Alati-Ẹluju ko wounjẹ fesu. Ibanujẹ wa ba Alati-Ẹluju. Alati-Ẹluju ko rojutu ile aiye rẹ mọ rara.
Alati-Ẹluju ko mohun tole se mọ. Alati-Ẹluju wa niran wipe ẹbọ tawọn babalawo ni koun ru, wipe oun ko
rubọ yii, wipe ase bayi leniyan se ndolosi. Alati-Ẹluju bẹrẹ sini ronu, inu rẹ bẹrẹ sini bajẹ. Alati-Ẹluju ni
gbogbo ohun tawọn babalawo sọ lowa sẹ bayi, wipe oun yoo foju rọla bayi, wipe toun ko bati rubọ, ọla naa
koni tẹun lọwọ. Alati-Ẹluju ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Alati-Ẹluju era un hombre que atrapa a los pajaros con la soga en el bosque. Un dia, la trampa de soga del
Alati-Ẹluju capturo a un pajaro. Este pajaro era demasioado bello. Alati-Ẹluju llevo el pajaro a su casa.
Cuando esu vio el pajaro. Esu-Ọdara fue a hablar con Alati-Ẹluju. Esu dijo que: tu Alati-Ẹluju se ha
convertido en un hombre rico. Esu dijo que los Reyes van a venir con dinero a la casa de Alati-Ẹluju para
comprarle el pajaro. Esu dijo al Alati-Ẹluju que no entrega el pajaro a los Reyes. Esu aconsejo al Alati-Ẹluju
no prometer a todos los Reyes que iba a llevarle el pajaro a su casa.
Enseguida Esu fue a la casa del Rey Alara. Esu dijo al Rey Alara que hay un pajaro en la casa de Alati-Ẹluju
ahora mismo, dijo que era el Rey Alara que debia tener ese pajaro en su casa, dijo que el pajaro era
demasiado bello. El Rey Alara pregunto al esu si el pajaro estaba en la casa de Alati-Ẹluju. Esu contesto que
si, que el pajaro estaba en la casa de Alati-Ẹluju y el pajaro era demasiado bello. Esu dijo al Rey Alara que
debe ir rapidamente a la casa de Alati-Ẹluju y poner dinero para comprarle el pajaro.

Esu dejo la casa del Rey Alara y volvio a la casa de Alati-Ẹluju. Esu dijo al Alati-Ẹluju que el Rey Alara venia
en el camino a la casa de Alati-Ẹluju, dijo que el Rey Alara venia con el dinero para comprarle el pajaro a
Alati-ẹluju, dijo que Alati-Ẹluju no debe coger el dinero del Rey Alara y que prometa al Rey Alara en llevarle
el pajaro a su casa y cobrarle el dinro. El Rey Alara era uno de los duenos de los mercados en el mundo en
aquella epoca. Habian deiciseis Reyes en el mundo en aquella epoca.
Cuando el Rey Alara mando una persona a la casa de Alati-Ẹluju con el dinero para comprarle el pajaro.
Alati-Ẹluju no acepto el dinero, le dijo que se vaya con el dinero, que iba a llevarle el pajaro a su casa y
cobrarle. Esu salio corriendo a la casa del Rey Ajero que era uno de los duenos de los mercados en el mundo
en aquella epoca. Esu dijo al Rey Ajero que hay un pajaro en la casa de Alati-Ẹluju ahora mismo, dijo que era
el Rey Ajero que debia tener ese pajaro en su casa y que el pajaro era demasiado bello. El Rey Ajero
pregunto al esu si el pajaro estaba en la casa de Alati-Ẹluju. Esu contesto que si, que el pajaro estaba en la
casa de Alati-Ẹluju y que el pajaro era demasiado bello. Esu dijo al Rey Ajero que debe ir rapidamente a la
casa de Alati-Ẹluju y poner dinero para comprarle el pajaro.

Esu dejo la casa del Rey Ajero y volvio a la casa de Alati-Ẹluju. Esu dijo a Alati-Ẹluju que el Rey Ajero vienia
en el camino a la casa de Alati-Ẹluju, que el Rey Ajero venia con dinero para comprarle el pajaro a Alati-
Ẹluju, que Alati-Ẹluju no debe coger el dinero del Rey Ajero y que prometa al Rey Ajero en llevarle el pajaro
a su casa y cobrarle el dinro. El Rey Ajero era uno de los duenos de los mercados en el mundo en aquella
epoca.
Esu dejo la casa de Alati-Ẹluju y se fue a la casa de otro Rey que se llama el Rey Ọrangun Aga. Cuando el
Rey Ajero mando una persona a la casa de Alati-Ẹluju con el dinero para comprarle el pajaro. Alati-Ẹluju no
acepto el dinero, le dijo que se vaya con el dinero, dijo que iba a llevarle el pajaro a su casa y cobrarle.
Esu fue a la casa del Rey Ọrangun Aga y le dijo que hay un pajaro en la casa de Alati-ẹluju ahora mismo, dijo
que era el Rey Ọrangun Aga que debia tener ese pajaro en su casa y que el pajaro era demasiado bello. El
Rey Ọrangun Aga pregunto al esu si el pajaro estaba en la casa de Alati-Ẹluju. Esu contesto que si, que el
pajaro estaba en la casa de Alati-Ẹluju y que el pajaro era demasiado bello. Esu dijo al Rey Ọrangun Aga que
debe ir rapidamente a la casa de Alati-Ẹluju y poner dinero para comprarle el pajaro. El Rey Ọrangun Aga
mando una persona con el dinero para comprarle el pajaro al Alati-Ẹluju.

Antes de que esa persona llega a la casa de Alati-Ẹluju. Esu ya estaba en la casa de Alati-Ẹluju. Esu dijo al
Alati-Ẹluju que el Rey Ọrangun Aga ya mando alguien que vienia en el camino a la casa de Alati-Ẹluju, dijo
que el Rey Ọrangun Aga Alara venia con el dinero para comprarle el pajaro a Alati-Ẹluju, dijo que Alati-Ẹluju
no debe coger el dinero del Rey Ọrangun Aga Alara y que prometa al Rey Orangun Aga Alara en llevarle el
pajaro a su casa y cobrarle el dinro. El Rey Ọrangun Aga era uno de los duenos de los mercados en el mundo
en aquella epoca.
Cuando el mensajero del Rey Ọrangun Aga llego a la casa de Alati-Ẹluju, hablaron del precio que iba a
vender el pajaro y llegaron acuerdo del precio. Alati-Ẹluju no acepto el dinero, le dijo que se vaya con el
dinero, que iba a llevarle el pajaro a su casa y cobrarle. Alati-Ẹluju estaba enganando a todos ellos.
Esu se fue rapidamente a la casa del Rey Alaka-Esu. Esu dijo al Rey Alaka-Esu que hay un pajaro en la casa
de Alati-Ẹluju ahora mismo, dijo que era el Rey Alaka-Esu que debia tener ese pajaro en su casa y que el
pajaro era demasiado bello. El Rey Alaka-Esu pregunto al esu si el pajaro estaba en la casa de Alati-Ẹluju.
Esu contesto que si, que el pajaro estaba en la casa de Alati-Ẹluju y que el pajaro era demasiado bello. Esu
dijo al Rey Alaka-esu que debe ir rapidamente a la casa de Alati-Ẹluju y poner el dinero para comprarle el
pajaro. El Rey Alaka-Esu mando alguien con el dinero para comprarle el pajaro al Alati-Ẹluju.

Antes de que el mensajero llego a la casa de Alati-Ẹluju. Esu ya estaba en la casa de Alati-Ẹluju.
Esu dijo al Alati-Ẹluju que el Rey Alaka-Esu ya mando alguien que vienia en el camino a la casa de Alati-
Ẹluju, dijo que el Rey Alaka-Esu venia con el dinero para comprarle el pajaro a Alati-Ẹluju. Esu dijo que
Alati-Ẹluju no debe coger el dinero del Rey Alaka-Esu y que prometa al Rey Alaka-Esu en llevarle el pajaro a
su casa y cobrarle el dinro. Cuando el mensajero del Rey Alaka-Esu llego a la casa de Alati-Ẹluju, hablaron
del precio que iba a vender el pajaro y llegaron acuerdo del precio. Alati-Ẹluju no acepto el dinero, le dijo
que se vaya con el dinero, que iba a llevarle el pajaro a su casa y cobrarle. El mensajero del Rey Alaka-Esu se
fue.
Esu fue a las casas de otros duenos de los mercados. Esu fue a las casas de todos los dieciseis duenos de los
mercados haciendo las mismas gestiones. Esu volvio a la casa de Alati-Ẹluju. Esu le pregunto a Alati-Ẹluju
que cuantos orejas tenia. Alati-Ẹluju contesto al esu que tenia dos orejas. Esu pregunto a Alati-Ẹluju lo que
hacia con sus orejas. Alati-Ẹluju contesto que sus orejas estan para escuchar las palabras. Esu le dijo que el
Rey Alara que vino primero al Alati-Ẹluju para comprarle el pajaro, le dijo que a la casa Del Rey Alara era
donde Alati-Ẹluju debia llevar el pajaro ahora mismo. Esu dijo que el Rey Alara iba a pagar Alati-Ẹluju
muchismo dinero mas.
Esu fue a la casa del Rey Alara, le dijo que Alati-Ẹluju no queria venderle el pajaro porque el dinero que iba a
pagar el Rey Alara era muy poco. Esu dijo al Rey Alara que tenia que pagar el doble, para que Alati-Ẹluju le
vende el pajaro a usted. Esu le dijo al Rey Alara que los demas Reyes querian comprar el pajaro. El Rey
Alara doblo el precio, mando a su mensajero con el dinero a la casa de Alati-Ẹluju y que queria comprarle el
pajaro a cualquier precio. Alati-Ẹluju ya habia hecho una aula “Pansa” para el pajaro. Esa aula no estaba
bien hecha. Si esa aula cae al suelo, se rompe.
Cuando Alati-Ẹluju estaba llevando el pajaro a la casa del Rey Alara. Esu le cruzo en el camino. Esu le tapo
los ojos y no vio nada en absoluto. Alati-Ẹluju caio al suelo con la aula y la aula se rompio. El pajaro escapo y
se volo al bosque otra vez. Alati-Ẹluju no vio nada. Esu le bloquio el camino porque Alati-Ẹluju no dio de
comer al esu. Alati-Ẹluju estaba infeliz. Alati-Ẹluju no entendia nada de lo que le estaba pasando en su vida.
Alati-Ẹluju no sabia lo que podia hacer. Le vino a la memoria al Alati-ẹluju el sacrificio que los babalawos le
mandaron a hacer y no hizo el sacrificio. Alati-Ẹluju dijo que asi era como una persona vuelve a ser pobre.
Alati-Ẹluju empezaba a pensar y estaba infeliz. Alati-Ẹluju dijo que todos lo que han dichos los babalawos se
hizo realidad, que el iba a ver las riquezas de lejos y si no hace el sacrificio, que no iba a conseguir las
riquezas. Alati-Ẹluju dijo que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Ẹiyẹ yẹkẹ. (El pajaro que resvala)


Ẹiyẹ yẹtu. (El pajaro que se pone de pie)
Ẹiyẹ to yẹkẹ o, ẹiyẹ to yẹtu. (El pajaro que resvala, el pajaro que se pone de pie)
Tosi mọ pohun ọla nbẹ ninu rẹ. (El pajaro sabia que hay riqueza dentro de si)
A dia fun Alati-ẹluju. (Se adivino Ifa para Alati-ẹluju)
Eyi tiwọn lọdọdun nisẹ tan (El que le dijieron cada ano que la pobreza se acabara)
Wọn ni komu tẹbọ se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O pawo leke o. (Llamo al awo mentiroso)
O pesu lole. (Llamo al esu ladron)
Esu aisẹbọ. (La tentacion de no hacer el sacrificio)
Ẹgba aiteru. (La paralisis de no apasiguar a Esu pronto)
Ohun lomu k’Alati-Ẹluju dẹni isẹ. (Por eso Alati-Ẹluju se convertio en una persona pobre)
Alati-Ẹluju ko rẹni a kosẹ ẹ fun mọ. (Alati-Ẹluju ya no vio a quien puede pasarle sus pobrezas)
Pansa fọ. (Se rompio la aula)
Ẹiyẹ tun lọ. (El pajaro tambien se volo

ASẸ-IFÁ:-Bayi ni Alati-Ẹluju se dolosi titi doni oloni. Ifa yii nkọni lẹkọ wipe gbogbo ohun tiwọn bani keniyan
mase, keniyan ma se nkan yi, koma dẹjà. Ifa ni keleyii ma dẹjà. Ifa ni teleyi ba dẹjà, Ifa leleyii yoo dolosi
kẹyin ni.
Ifa ni nkan ire, nkan ọla kan wa niwaju eleyii, tiwọn yoo ro kan eleyii, tabi ko tẹ eleyii lọwọ. Ifa ni keleyii
TETE rubọ nibẹ, ko sunmọ awọn babalawo kiwọn jewe Ifa fun-un, kire yii le beleyii kalẹ, keleyii ma baa ku
sinu osi loju Irẹtẹ-Ọwọnrin. Ifa ni keleyii lọ BỌFA nibẹ. Ifa ni keleyii RUBỌ FESU nibẹ.

ASẸ-IFÁ:- Asi fue como Alati-Ẹluju se convertio en un pobre hasta la fecha de hoy. Este Verso de Ifa nos esta
dando leccion que uno debe hacer todos le que le mandan a hacer, que uno no debe dudarse de los mensajes
de Ifa. Ifa dice que esta persona no debe dudarse de los mensajes de Ifa. Ifa dice que si esta persona duda a
los mensajes de Ifa, Ifa dice que esta persona sera pobre al final.
Ifa dice que hay bendicion y riquezas enfrente de esta persona, en lo que van a pensar de esta persona o lo
va a conseguir esta persona. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio URGENTEMENTE, debe
acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa, para que esas bendiciones y riquezas le
duran hasta los ultimos dias de su vida, para que esta perosna no muere en la pobreza. Ifa dice que esta
persona debe DAR DE COMER A IFA. Ifa dice que esta persona debe DAR DE COMER A ESU tambien.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo iku. (Investigar la muerte)

Ifa lohun teleyIi nri, toba sun lalẹ ko dara. Orun teleyIi nsun ko dara. Ifa ni keleyIi o rubọ nibẹ, kiwọn ma
baa seku peleyIi. Ifa ni keleyIi o rubọ nibẹ. Ifa ni koni IRỌRI RẸ lẹbọ nibẹ, koni OBUKỌ KAN lẹbọ nibẹ. Ifa ni
keleyIi o rubọ nibẹ, kiwọn ma baa seku peleyIi. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que los senales que esta viendo esta persona en sus suenos por las noches no son buenos. Ifa dice
que esta persona no esta dormiendo bien. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que no le
matan. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que debe tener SU ALMUHADA en su
sacrificio y debe tener UN CABRA MACHO en su sacrificio. Ifa dice que esta persona debe hacer el
sacrificio, para que no le matan. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)


A dia fun Ọlọta. (Se adivino para Ọlọta)
Nijọ tifimi njiwọn-mi loju orun. (El dia que la muerte estaba tragandos a ellos en el sueno)
Wọn ni ko rubọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Kofi IRỌRI RẸ ati OBUKỌ KAN fi rubọ. (Dijieron que debe tener SU ALMUHADA y UN CABRA MACHO
en su sacrificio)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Ijo ni njo o, ayọ ni Ọlọta nyọ. (Ọlọta estaba feliz y estaba bailando)

Ọba ni Ọlọta. Orun ti nsun lojojumọ ko dara. Iku ati arun ni nbẹ Ọlọta wo loju orun, tiwọn fẹ pa Ọlọta, o ti
nririkuri. Ifa lorun teleyii nsun ko dara. Ifa lawọn alujọnnu fẹ peleyii. Ibi irọri teleyii fi nrọri lawọn alujọnnu
yii duro si. Ifa ni kofi IRỌRI RẸ ati OBUKỌ KAN rubọ nibẹ. Ifa ni gbogbo nkan yii ma lojutu.
Wọn ni k’Ọlọta o rubọ, nitoripe t’Ọlọta bati sun, awọn ẹbọra, awọn irunmọlẹ wọn yoo wa ma duro nigberi
rẹ, tiwọn yoo ma kọrin si Ọlọta leti, wọn koni jẹ k’Ọlọta sun. Wọn yoo masọ wipe:
Wọn nse: ORIN

Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta.


Wọn ni ko tẹni, ko sun.
Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta.

Ọlọta ko rorun sun, gbogbo nkan to nsẹlẹ ko y’Ọlota, ko mọtumọ gbogbo nkan yii. Ni Ọlọta ba kesi awọn
awo kiwọn yẹun wo. Lawọn awo ba dafa f’Ọlọta. Wọn lorun ti kabiyesi nsun lojojumọ ko dara, wipe iku ati
arun ni nbẹ Ọlọta wo loju orun, tiwọn fẹ p’Ọlọta, o ti nririkuri. Wọn nibi irọri-rẹ lawọn alujọnnu wa. Wọn
ni kofi IRỌRI RẸ ati OBUKỌ KAN kun ẹbọ ru nibẹ. Wọn ni Ọlọta yoo sẹgun.
Ni Ọlọta ba rubọ, awọn babalawo jewe Ifa fun-un. Ni ogun ba sẹ f’Ọlọta. Ni Ọlọta ba njo, o nyọ, o nyin awọn
awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo
toun sọ:

Los senales que el Rey Ọlọta estaba recibiendo en sus suenos todos los dias no son buenos. La muerte y la
enfermedad estaban visitandos al Rey Ọlọta en su suenos, querian matarle. Ọlọta estaba viendo cosas malas
en sus suenos. Ifa dice que esta persona esta dormiendo mal. Ifa dice que esta persona esta recibiendos
senales malas en sus suenos. Ifa dice que los espritus malos quieren matar a esta persona. Ifa dice que esos
espiritus malos se quedan el la almuhada que esta persona usa para dormir. Ifa dice que esta persona debe
tener SU ALMUHADA y UNA CABRA MACHO en su sacrificio. Ifa dice que todas estas cosas se solucionara y
vencera.
Dijieron al Ọlọta que debe hacer el sacrificio, porque cuando duerme Ọlọta, los espiritus malos, las diedades
se quedan en su almuhada y cantaban al Ọlọta en las orejas, no dejan al Ọlọta dormir. Los espiritus malos y
las diedades cantaban que:

Wọn nse: ORIN (CANCION)

Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta o. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)


Won ni ko tẹni, ko sun. (Dijieron que desplega la estera y que duerme)
Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)

Ọlọta no podia dormer. Ọlọta no entendia nada de lo que le estaba pasando, no tenia explicaciones a lo que
estaba ocurriendole. Ọlọta llamo a los awos para consultarse con Ifa. Consultaron al Ọlọta y le dijieron que
los senales que el Rey Olọta estaba recibiendo en sus suenos todos los dias no son buenos. Le dijieron que la
muerte y la enfermedad estaban visitando al Rey Ọlọta en su suenos, querian matarle, estaba viendo cosas
malas en sus suenos cuando duerme el Rey Ọlọta, los espiritus malos y las diedades se quedan en su
almuhada. Que debe tener SU ALMUHADA y UN CABRA MACHO en su sacrificio. Dijieron al Ọlọta que
vencera.
Ọlọta hizo el sacrificio, los babalawos le preparanron las hierbas de Ifa. Ọlọta vencio la batalla. Ọlọta estaba
feliz, empezo a bailar y cantar; Que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)


A dia fun Ọlọta. (Se adivino para Ọlọta)
Nijọ tifimi njiwọn-mi loju orun. (El dia que la muerte estaba tragando a ellos en sus suenos)
Wọn ni ko rubọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Kofi IRỌRI-RẸ ati OBUKỌ KAN fi rubọ. (Le dijieron que debe tener SU ALMUHADA y UNA CABRA
MACHO en su sacrificio)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de Ifa)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Ijo ni njo o, ayọ ni Ọlọta nyọ. (Ọlọta estaba feliz y estaba bailando)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ifa wa bani laarin ṣegun. (Ifa ven a encontranos en el medio del vencimiento)
Aarin ṣegun, n la a bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies del Rey
de los Orisas)

O nse: ORIN. (CANCION)

Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)


Wọn niki njẹun, ki n sun. (Dijieron que como y que duermo)
Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)
Wọn niki ntẹni, ki n sun. (Dijieron que desplego la estera y que duermo)
Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)
Wọn niki nsu osuka, ki nsun o. (Dijieron que pongo la almuhada y que duermo)
Ajeje-niranjẹ awo Ọlọta. (Ajeje-niranjẹ era el awo del Ọlọta)

ASẸ-IFÁ:- Nigbati Ọlọta sẹgun tan, loba njo, inu-rẹ dun. Ifa ni keleyii rubọ nibẹ. Ifa leleyii yoo sẹgun. Keleyii
sunmọ awọn babalawo kiwọn baa jewe Ifa nibẹ. Ifa nisẹgun yoo de. Ifa ni teleyii ba dẹjà, Ifa niwọn yoo
peleyii danu ni laitọjọ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, wipe orun teleyii nsun ko dara. Kiwọn maa baa seku peleyii.
Ifa ni koni IRỌRI-RẸ lẹbọ nibẹ, koni OBUKỌ KAN lẹbọ nibẹ. (Ọrunmila sawo lọ sode Ọta loju Irẹtẹ Ọlọta).

ASẸ-IFÁ:- Cuando Ọlọta vencio, esta feliz y cantando. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa
dice que esta persona vencera. Ifa dice que debe acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas
de Ifa. Ifa dice que le llegara el vencimiento a esta persona. Ifa dice que si esta persona duda a los mensajes
de Ifa, Ifa dice que murira antes del tiempo. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio porque las
senales que esta recibiendo en sus suenos no son buenos, para que no le matan en el signo de Irẹtẹ-ỌOlọta.
Ifa dice que debe tener SU ALMUHADA en su sacrificio y debe tener UN CABRA MACHO en su sacrificio.
(Ọrunmila fue a predicar Ifa en la ciudad de Ọta en el signo de loju Irẹtẹ-Ọlọta)
14.7. IRẸTẸ-ỌBARA.

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Investigar el vencimiento de los enimigo)

Ifa ni kasọ feleyii ko rubọ nibẹ, kole baa sẹgun ọta ni gbogbo igba. Ifa lawọn ọta ngbogun teleyii. Ifa ni
keleyii o rubọ nibẹ, koni OBUKỌ KAN lẹbọ nibẹ, koni AGBEBỌ ADIE KAN lẹbọ nibe, koni
ẸGBẸTALELOGUN OWO lẹbọ nibẹ, keleyii le ba ma sẹgun awọn ọta-rẹ ni gbogbo igba tiwọn ba ngbogun
teleyii. Keleyii sunmọ awon babalawo kiwọn baa jewe Ifa. Ifa leleyii yoo sẹgun ni gbogbo igba tawọn ọta rẹ
bati ngbogun teleyii. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa le esta diciendo a esta persona que debe hacer el sacrificio para que puede vencer a sus enimigos en
todos los momentos. Ifa dice que los enimigos estan levantando guierras contra esta persona. Ifa dice que
esta persona debe hacer el sacrificio, debe tener UN CABRA MACHO en su sacrificio, debe tener UNA
GALLINA en su sacrificio, debe tener CUATRO MIL SEIS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio, para
que puede vencer a sus enimigos en todos los momentos que levantan guierra contra esta persona. Ifa dice
que debe acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa. Ifa dice que esta persona vencera
en todos los momentos que sus enimigos levantan guierra contra esta persona. Ifa lo dice asi con este verso;
QUE:

Ko sẹni tapa Olodumare ko ka. (No hay nadie que es superior a Olodumare)
Ko sibi tatẹlẹsẹ ko lee tẹ. (No hay ningun sitio que los pies no pueden pisar)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba nbẹ laarin ọta. (El dia que el padre esta en el medio delos enimigos)
Ẹbọ niwọn niki baba o se. (Dijieron al padre que debe hacer el sacrificio)
Ko lee sẹgun wọn. (Para que puede vencer a sus enimigos)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de
Ifa)

Ọrunmila wa laarin ọta, wọn ngbogun ti baba. Ọrunmila ni gbogbo nkan yii ko yeun. Ni Ọrunmila ba ji nijọ
kan, loba gbefa kalẹ. Niwọn ba dafa f’Ọrunmila. Wọn niki baba o fi OBUKỌ KAN rubọ nibẹ, wipe laarin ọta
ni baba wa o, koni AGBEBỌ ADIẸ KAN lẹbọ nibẹ, koni ẸGBẸTALELOGUN OWO lẹbọ nibẹ. Wọn ni
t’Ọrunmila bati rubọ, tawọn babalawo si jewe Ifa fun-un, wipe Ọrunmila yoo ma sẹgun ni gbogbo igba
tiwọn bati gbogun t’Ọrunmila. Ni Ọrunmila ba rubọ, ni baba ba sẹgun. Ni Ọrunmila ba njo, o nyọ, o nyin
awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹe lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Ọrunmila estaba en el medio de los enmigos, estaban levantandos guierras contra el padre. Ọrunmila decia
que no entendia todos lo que le estaba pasando. Un dia, Ọrunmila saco Ifa y le consultaron. Dijieron al padre
que debe tener UN CABRA MACHO en su sacrificio poque estaba en el medio de los enimigos, debe tener
UNA GALLINA en su sacrificio, debe tener CUATRO MIL SEIS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio.
Dijieron al Ọrunmila que si hace el sacrificio y acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de
Ifa, dijieron que Ọrunmila vencera en todos los momentos que sus enimigos levantan las guierras contra
Ọrunmila. Ọrunmila hizo el sacrificio y el padre vencio. Ọrunmila estaba feliz, empezo a bailar y cantar;
Que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Ko sẹni tapa Olodumare ko ka. (No hay nadie que es superior a Olodumare)
Ko sibi tatẹlẹsẹ ko lee tẹ. (No hay ningun sitio que los pies no pueden pisar)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba nbẹ laarin ọta. (El dia que el padre esta en el medio delos enimigos)
Ẹbọ niwọn niki baba o se. (Dijieron al padre que debe hacer el sacrificio)
Ko lee sẹgun wọn. (Para que puede vencer a sus enimigos)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de
Ifa)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹ wa bani laarin iṣẹgun. (Ustedes ven a encontranos en el medio del vencimiento)
Aarin iṣẹgun, nla a bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies
del Rey de los Orisas)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa nisẹgun tide feleyii. Ifa leleyii yoo sẹgun ni gbogbo igba tawọn ọta rẹ
bati ngbogun teleyii. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koni OBUKỌ KAN lẹbọ nibẹ, koni AGBEBỌ ADIE KAN lẹbọ
nibe, koni ẸGBẸTALELOGUN OWO lẹbọ nibẹ.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que llegara el vencimiento para esta
persona. Ifa dice que esta persona vencera en todos los momentos que sus enimigos levantan las guierra
contra esta persona. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe tener UN CABRA MACHO en
su sacrificio, debe tener UNA GALLINA en su sacrificio y debe tener CUATRO MIL SEIS CIENTOS DE
DINERO en su sacrificio.
ẸSẸ KEJI.

Ire irin-ajo. (Bendicion de viaje)

Ifa leleyii fẹ bẹnikan lọ sibikan, boya wọn fẹ rinrin ajo ni, eleyii fẹ bawọn ẹnikan kọọwọ rin lọ sibikan. Ifa ni
keleyii o rubọ nibẹ, Ifa nire nibẹ yoo jasi, ibẹ yoo dara. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona quiere ir a un sitio, puede ser que quieren ir de viaje, que esta persona quiere ir
con otras personas a un sitio. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que conseguira
bendicion donde quiere ir, que ese sitio sera bueno para esta persona. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

A se jẹjẹ jaiye Awo Ile Alara. (“El que vivia la vida pacificamente” era el awo de la casa de
Alara)
A se warawara sawo, awo Oke Ijero. (“El que predicaba a Ifa con prisa” era el awo de la montana
de Ijero)
Kinni Irẹtẹ-Ọbara nwa (?Que es lo que esta buscando Irẹtẹ-Ọbara?)
Bi o se ewe-ẹrọ. (Si no fuera la hierba de ẹrọ “apasiguamiento”)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba yoo ba ọkanlelogun irunmọlẹ lọ sode ọrun. (El dia que el padre iba a ir con las venti-una
diedades al cielo)
Ti yoo si mewe ẹrọ lọwọ. (Que iban a llevar las hierbas de ẹrọ en sus manos)
Kinni o jẹko rọwọn lọrun lalede ọrun. (?porque se encuentran tranquilos en el cielo)
Ẹrọ wọọ niti Tẹtẹ. (Ẹrọ wọọ “apasiguamiento” es de la hierba de Tẹtẹ
Ẹrọ wọọ niti Ọdundun. (Ẹrọ wọọ “apasiguamiento” es de la hierba de Ọdundun)
Ẹrọ wọọ niti Rinrin. (Ẹrọ wọọ“apasiguamiento” es de la hierba de Rinrin)
Ọwọ bewe “pipẹrọ aleede”. (Tenemos la hierba de “pipẹrọ aleede” en las manos)
Ka sai ni jẹ kiku pọmọ awo. (No dejara que la muerte mata al hijo del awo)
Ọwọ bewe “pipẹrọ aleede”. (Tenemos la hierba de “pipẹrọ aleede” en las manos)
Ka sai ni jẹ kiku pọmọ awo. (No dejara que la muerte mata al hijo del awo)

ASẸ-IFÁ:- Ifa nibi tiwọn nlọ yii, ẹrọ wa, wọn yoo pẹrọ siwọn ninu, wọn yoo pẹrọ siwọn lẹnu. Ifa ni alọ ati
abọ wọn dara, Ifa nibikan leleyii nlọ yii. Ifa ni ko rubọ nibẹ koto lọ, kawọn babalawo beleyii jewe ẸRỌ. Ifa
lewe ẹrọ ni yoo jẹ kara o rọwọn, ni yoo jẹki gbogbo rẹ tutu rinrin, ti koni si wahala Kankan rara. Ewe
“pipẹrọ aleede” ni yoo dabo bowọn. Ewe ”pipẹrọ aleede” ka-sai ni jẹ kiku pọmọ awo. Ifa ni keleyii o rubọ
nibẹ koto malọ.
ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que hay apasiguamiento en el sitio donde van. Las gentes se van a estar apasiguados en
sus interiores, las gentes van a estar apasiguados en sus bocas. Ifa dice que tantos la ida y la vuelta seran
buenos. Ifa dice que esta persona quiere ir a un sitio. Ifa dice que debe hacer el sacrificio antes de irse y que
los babalawos le preparan las hierbas de Ifa con la hierba de “ẸRỌ”. Ifa dice que la hierba de “ẸRỌ” hara
que ellos se encuentran tranquilos alli. La hierba de “rinrin” es lo que hara que ellos se encuentra fresco
como el “Rinrin” alli y no tendra ningun problema. La hierba de “pipẹrọ aleede” protegera a ellos alli. La
hierba de “pipẹrọ aleede” no dejara que la muerte mata al hijo del awo. Ifa dice que esta persona debe hacer
el sacrificio antes de irse.

14.8. IRẸTẸ-ỌKANRAN.

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Investigar el vencimiento de los enimigos)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kolọ BỌFA pẹlu EWURẸ. Tiwọn ba bọfa feleyii tan, kawọn babalawo tun jewe Ifa
feleyii, nitoripe aarin ọta nibi teleyii wa, kiwọn ma baa seku peleyii nibẹ.
Ifa ni keleyii o BỌ BABA ati IYA RẸ. Kofi OBI bọ baba ati iya rẹ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa leleyii yoo
sẹgun. Ko FEWURẸ BỌFA pẹlu ẸGBẸTALALOGUN OWO. Ifa ni yoo sẹgun nijọ toba bọ saarin awọn ọta
tiwọn fẹ seku peleyii.
Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa niwọn yoo pete pero, tiwọn yoo sowọpọ leleyii lori, tiwọn yoo fẹ peleyii,
nitoripe wọn ko fẹran eleyii. Wọn ni soun nikan lo gọn ju ni. Ifa ni keleyii ma sọra rẹ laarin awọn eniyan,
nitori pe wọn ti nbinu seleyii, wipe soun nikan ni nbẹ lawujọo, tiwọn yoo fẹ peleyii ni gbogbo ibikibi.
Ọrunmila loke, Ọrunmila nisalẹ, Ọrunmila ni gbogbo ibikibi. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kosi sọrarẹ lati ma
yan kakiri laarin awọn eniyan, wipe awọn lawọn wa nibẹ, kiwọn ma baa seku peleyii. Kiwọn silọ BỌFA
feleyii ni. Kosi sunmọ awọn babalawo, kiwọn jewe Ifa fun-un, kole ba sẹgun ọta. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re
o. Ifa na sọ pe:
Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe DAR DE COMER A IFA con CHIVA. Despues de
que termina de dar de comer a Ifa, que los babalawos le preparan las hierbas de Ifa, porque esta persona se
encuentra en el medio de los enimigos en el lugar que se encuentra, para que no le causan la muerte a esta
persona.
Ifa dice que esta persona debe DAR DE COMER A SU PADRE y SU MADRE (Rogar la cabaza su padre y
de su madre). Ifa dice que debe dar de comera su padre y su madre con COLAS. Ifa dice que esta persona
debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona vencera. Ifa dice que debe DAR DE COMER A IFA con
CHIVA y con CUATRO MIL SEIS CIENTOS DE DINERO. Ifa dice que esta persona vencera cuando entra
en el medio de los enimigos que quieren causarle la muerte.
Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que estan planiandose y conspirandose para matar
a esta persona, porqiue no quieren a esta persona. Estan diciendos que si esta persona era el mas inteligente
entre ellos. Ifa dice que esta persona debe tener cuidado entre las gentes, porque estan enfadados con estas
persona, que si el era la unica persona en la comunidad y van a querrer matar a esta persona en cualquier
lugar.
Las gentes hablaban de Ọrunmila arriba y abajo, hablaban de Ọrunmila por todos los sitios. Ifa dice que esta
persona debe hacer el sacrificio y que debe tener cuidado en sacar el pecho entre las gentes, para que no le
causan la muerte a esta persona. Ifa dice que deben DAR DE COMER A IFA para esta persona. Que los
babalawos le preparan las hierbas fde Ifa para esta perona, para que puede vencer. Ifa lo dice asi con este
verso; QUE:

Irẹtẹ Ọkanran (Irẹtẹ Ọkanran)


Ni agbarijọ awo da. (Era el signo que salio de los conjuntos de awos)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ tiwọn ndafa fun-un nile Ọlọfin. (El dia que consultaron Ifa para el en la casa de Ọlọfin)
Wọn ni ko sẹbọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Kiwọn ma baa seku paa lalede aiye. (Para que no le causan la muerte en el mundo)
Wọn ni ko FEWURẸ BỌFA . (Dijieron que debe DAR DE COMER A IFA con CHIVA)
Pẹlu ẸGBẸTALALOGUN OWO. (Con CUATRO MIL SEIS CIENTOS DE DINERO)
Ọrunmila gbọ riru, o ru. (Ọrunmila oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de Ifa)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Wọn ransẹ kesi Ọrunmila nile Ọlọfin. (Mandaron a buscar a Ọrunmila desde la casa de Ọlọfin)

Nijọ kan, gbogbo awọn babalawo ti sepade Ọrunmila silẹ, nitoripe Ọrunmila ni nma nkifa to jana laarin
wọn, ti koni parọ, ti yoo sohun towa ninu Ifa fonikaluku wọn. Ti Ọrunmila ba kifa tan, ẹniti Ọrunmila kifa
fun, yoo wa fẹran Ọrunmila pupọ. Awọn awo ni s’Ọrunmila nikan logbọn ju laarin awọn ni. Ọlọfin naa ni
s’Ọrunmila nikan logbọn ju laarin awọn ni, wipe tawọn be seku paa, tiku ba p’Ọrunmila, wipe Ọrunmila
yoo mọ. Wọn ni s’Ọrunmila nikan logbọn ju nile aiye ni. Ọrunmila nikan ni Olodumare si kọgbọn ile aiye le
lọwọ.
Niwọn ba ransẹ s’Ọrunmila nile Ọlọfin, wipe k’Ọrunmila wa o.Nigbati Ọrunmila dele Ọlọfin. Wọn ti rolẹ silẹ
d’Ọrunmila. Ẹmu gbigbẹ towa ninu agbe, wọn ti fọwọ sinu ẹmu yii, wọn niki Ọrunmila mẹmu yii, ohun tole
peniyan niwọn ni k’Ọrunmila o mu. Bi Ọrunmila se dele Ọlọfin, loba joko kalẹ laarin wọn, niwọn ba gbẹmu
jade, lẹmu yii nho yayaya. Ọrunmila ni kinni eleyii. Wọn lẹmu ni. Wọn ni k’Ọrunmila mẹmu. Ọrunmila ni
kii sẹmu leleyii, wipe ọwọ leleyii. Ọrunmila ni: Irẹtẹ- Ọkanran, awo kii mẹmu. Ọrunmila ba gbẹmu yii ju
silẹ, ko mẹmu yii.
Un dia, todos los babalawos conspiraron contra Ọrunmila, porque orunmila era el sabia de la adivinacion de
Ifa entre todos ellos, es el que no miente en las adivinaciones de Ifa. Ọrunmila hablaba lo que salio en en el
tablero de Ifa para cada uno de ellos. Despues de que Ọrunmila termina las adivinacioes de Ifa, a todos los
que Ọrunmila les adivino Ifa, todos ellos querian a Ọrunmila cada vez mas. Los demas awos decian que si
Ọrunmila era la unica persona mas inteligente entre ellos. Ọlofin tambien decia que si Ọrunmila era la unica
persona mas inteligente entre ellos. Se conspiraron para causarle la muerte al Ọrunmila. Dijieron que si
Ọrunmila era la unica persona mas inteligente en el mundo. Dijieron que si Ọrunmila era la unica persona
que Olodumare entrego la soga de las inteligencias en el mundo.
Mandaron a buscar a Ọrunmila desde la casa de Ọlofin para que venga. Cuando Ọrunmila llego a la casa de
Ọlofin. Ya habian preparado medicinas malas para matar a Ọrunmila. Pusieron las medicinas malas, veneno
en el vino blanco de la palmera que estaba dentro de una jicara, para que Ọrunmila bebe el vino que puede
matar a una persona. Cuando Ọruinmila llego a la casa de Ọlofin, Ọrunmila sento en el medio de todos ellos,
sacaron el vino blanco de la palmera, ese vino estaba echando espumas. Ọrunmila pregunto por lo que era
esa cosa que esta echando tantas espumas dentro de la jicara. Contestaron que era vino blanco. Dijieron a
Ọrunmila que bebe el vino blanco. Ọrunmila contesto que eso no era vino blanco y que han metido algo
malo dentro. Ọrunmila dijo que: Irete Ọkanran, Awo no puede bebe el vino blanco. Ọrunmila dejo el vino
blanco en el suelo, Ọrunmila no bebio el vino.

Niwọn ba nsọrọ lọ. Nigba topẹ diẹ, niwọn batun gbẹmu-ọgọrọ towa ninu agbe jade. Niwọn batun gbee
f’Ọrunmila. Wọn ni k’Ọrunmila mu ẹmu-ọgọrọ yii. Ọrunmila ni kinni nho yayaya ninu agbe yii. Wọn ni
ọgọrọ ni. Ọrunmila ni Irẹtẹ-Ọkanran ko mẹmu loni. Ọrunmila lọwọ lowa nibẹ, kii sẹmu-ọgọrọ. Ọrunmila
ba gbẹmu yii ju silẹ, ko mẹmu yii. Wọn sa nwọna tiwọn yoo se seku p’Ọrunmila ni. Sugbọn
Ọrunmila mọ, Ọrunmila ti rubọ tẹlẹ, Ọrunmila ti bọfa. Ẹbọ Ọrunmola ti fin.
Ara ọmọ Ọlọfin kan ko ya. Niwọn bani ki gbogbo awọn babalawo kiwọn dafa sọrọ ọmọ yii, biko seni ku
mọhun lọwọ. Niwọn ba gbe Ifa kalẹ, niwọn ba dafa. Gbogbo awọn awo kifa lọ sasasa. Ọrunmila sa nwo
gbogbo wọn ni, ko sọrọ. Nigba tawọn awo kifa tan, wọn lọmọ yii koni ku. Ọlofin lọmọ yii koni ku. Awọn
awo ni hinn. Ọlọfin bani k’Ọrunmila baun kifa, ko da sọrọ yii. Ọrunmila ba kifa, Ọrunmila ni t’Ọlọfin ko bati
rubọ, wipe ọmọ yii yoo ku o. Ọlọfin ni kinni ẹbọ oun. Ọrunmila ni ASỌ IGUNWA RẸ ati ITẸ RẸ lẹbọ nibẹ.
Bi Ọlọfin se gbohun ẹbọ yii, inu Ọlọfin dun pupọ. Nitoripe Ọlọfin ti nwọna lati p’Ọrunmila tẹlẹ. Ọlọfin si mọ
wipe awọn le fogun buruku sara asọ-igunwa yii lati p’Ọrunmila. Nigbati Ọlọfin wọ yara lọ, loba fogun
buruku sinu asọ yii, wipe toun bati gbasọ yi sita, ti Ọrunmila dasọ yii bora, tabi toba joko le asọ yii lori, wipe
Ọrunmila yoo ku.
Nigbati Ọlọfin jade sita. Lẹiyẹ kan bafo de, lẹiyẹ yii ba nsọsi Ọrunmila leti, wipe asọ-igunwa ati itẹ ti Ọlọfin
mu wa yii, k’Ọrunmila mafi joko, koma sifi bora o. Ọrunmila ti gbọ bẹiyẹ yii se wi. Bi Ọlọfin se ko awọn
nkan yi jade, lẹiyẹ yii ba nkọrin wipe:

O nse: ORIN.

Ọrunmila o, Ọrunmila.
Ma ma joko sori asọ loni o.
Ma ma joko sori asọ loni o.
Seni ko joko silẹlẹ
Ọrunmila se o ngbọ.
Ma ma joko sori asọ loni o.
Ma ma joko sori asọ loni o.
Seni ko joko silẹlẹ

Seguieron hablandos. Despues de poco tiempo, sacaron otro vino de “ọgọrọ” que estaba echandos espumas,
se lo dieron a Ọrunmila para que bebiera el vino de“ọgọrọ”. Ọrunmila pregunto por lo que era esa cosa que
estaba echandos tantas espumas dentro de la jicara. Dijieron que era el vino de“ọgọrọ”. Ọrunmila dijo que:
Irẹtẹ-Ọkanran no bebe el vino blanco hoy, Ọrunmila dijo que han metido algo denro del vino de“ọgọrọ”.
Ọrunmila dejo el vino blanco de“ọgọrọ” en el suelo, Ọrunmila no bebio el vino de“ọgọrọ”. Estaban
buscandos los medios para matar a Ọrunmila. Pero Ọrunmila lo sabia, Ọrunmila ya habia hecho el
sacrificio. Ọrunmila DIO DE COMER A IFA. El sacrificio que Ọrunmila hizo se levanto y se acepto.
Uno de los hijos de Ọlọfin estaba enferma. Dijieron a todos los awos presente en hacer la consulta para el
hijo de Ọlọfin que estaba enferma, para saber lo hay que hacer para salvar el hijo de Ọlọfin en murirse.
Sacaron Ifa y hicieron la consulta. Todos los awos presente adivinaron el Ifa. Ọrunmila estaba mirando a
todos los awos que adivinaron el Ifa y no dijo nada. Cuando todos ellos terminaron de adivinar el Ifa. Todos
los awos dijieron que el hijo de Ọlọfin no iba a murir. Ọlọfin dijo que su hijo no iba a murir. Los awos
dijieron que no, que el hijo del Ọlọfin no iba a murir . Ọlọfin dijo al Ọrunmila en contribuir al asunto en
adivinar el Ifa. Ọrunmila adivino el Ifa y dijo que si Ọlọfin no hace el sacrificio, su hijo murira. Ọlọfin
pregunto por los ingredientes de su sacrificio. Ọrunmila dijo que SU ROPA DE LA CORONACION y SU
ESTERA DEL REY son los ingredientes del sacrificio.
Cuando Ọlọfin oio los ingredients del sacrificio. Ọlofin estaba contento, porque Ọlọfin estaba buscando los
medios para matar a Ọrunmila y sabia que podia meter las medicinas malas que podian matar a una
persona en la ropa de su coronacion del Rey. Cuando Ọlọfin entro en su habtacion, metio las medicinas
malas en la ropa de su coronacion, pensando que si Ọrunmila se tapaba su cuerpo con esa ropa o si se sienta
encima de esa ropa, seguramente que Ọrunmila muriera.
Cuando Ọlọfin salio fuera , entro un pajaro, este pajaro hablo con Ọrunmila en la oreja que esas ropa y
estera que Ọlofin ha traidos, dijo que Ọrunmila no se tapaba con la ropa y no debia sentar por encima de la
estera. Ọrunmila ya entendio lo que el pajaro le estaba diciendo. Segun Ọlọfin saco esas cosas fuera, este
pajaro empezo a cantar que:

O nse: ORIN. (CANCION)

Ọrunmila o, Ọrunmila. (Ọrunmila o, Ọrunmila)


Ma ma joko sori asọ loni o. (No te sientas por encima de la ropa hoy)
Ma ma joko sori asọ loni o. (No te sientas por encima de la ropa hoy)
Seni ko joko silẹlẹ (Tienes que sentarte en el suelo)
Ọrunmila se o ngbọ. (!Lo has entendido Ọrunmila!)
Ma ma joko sori asọ loni o. (No te sientas por encima de la ropa hoy)
Ma ma joko sori asọ loni o. (No te sientas por encima de la ropa hoy)
Seni ko joko silẹlẹ (Tienes que sentarte en el suelo)

K’Ọlọfin tode. Kiakia ni Ọrunmila ti joko silẹlẹ, o ti tẹfa silẹ. B’Ọlọfin se kasọ yii jade wipe awọn nkan ẹbọ
naa niyi o. Ọrunmila ni kiwọn o kawọn nkan yi silẹlẹ, wipe nilẹlẹ naa loun yoo ti setutu. B’Ọrunmila se bẹrẹ
sini setutu niyi. Ọlọfin koba lee sọ nkankan mọ. Nigbti Ọrunmila rubọ tan. Ọrunmila ni k’Ọlọfin kawọn asọ
yii lọfi bọra, wipe Ifa ni Ọlọfin gbọdọ fasọ yii bọra ni. Ọrunmila timọ wipe ogun wa ninu asọ yii. B’Ọlọfin
seku niyi. Ọlọfin dalẹ. Ọrunmila ba kuro laarin gbogbo awọn awo. Bayi ni Ọrunmila se sẹgun. Ni Ọrunmila
ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ
lawọn awo toun sọ:

Antes de que Ọlọfin salio fuera de la habitacion. Ọrunmila ya habia sentado en el suelo rapidamente y puso
el Ifa en el suelo. Cuando Ọlọfin saco las cosas del sacrificio para enregarlas al Ọrunmila. Ọrunmila le dijo al
Ọlọfin que lo déjà en el suelo, Ọrunmila dijo que iba a hacer el sacrificio en el suelo. Orunmila empezo a
hacer el sacrificio. Ọlọfin no podia decir nada en absoluto. Cuando Ọrunmila termino de hacer el sacrificio.
Ọrunmila dijo al Ọlọfin que tenia que taparse su cuerpo con la ropa, que Ifa ha dicho que Ọlọfin tenia que
taparse su cuerpo con la ropa de su coronacion. Ọrunmila sabia que habia medicina en esa ropa de la
coronacion. Asi fue como murio el Ọlọfin. Ọlọfin traiciono a Ọrunmila. Ọrunmila se levanto entre los awos
y se fue. Ọrunmila vencio. Ọrunmila estaba feliz, empezo a bailar y cantar; Que asi mismo lo han
adivinados y cantados sus awos; QUE:

Irẹtẹ Ọkanran (Irẹtẹ Ọkanran)


Ni agbarijọ awo da. (Era el signo que salio de los conjuntos de awos)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ tiwọn ndafa fun-un nile Ọlọfin. (El dia que consultaron Ifa para el en la casa de Ọlọfin)
Wọn ni ko sẹbọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Kiwọn ma baa seku paa lalede aiye. (Para que no le causan la muerte en el mundo)
Wọn ni ko FEWURẸ BỌFA . (Dijieron que debe DAR DE COMER A IFA con CHIVA)
Pẹlu ẸGBẸTALALOGUN OWO. (Con CUATRO MIL SEIS CIENTOS DE DINERO)
Ọrunmila gbọ riru, o ru. (Ọrunmila oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de Ifa)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Wọn ransẹ kesi Ọrunmila nile Ọlọfin. (Mandaron a buscar a Ọrunmila desde la casa de Ọlọfin)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ifa wa bani laarin Iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio del vencimiento)
Aarin Iṣẹgun, nla a bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies del
Rey de los Orisas)

ASẸ-IFÁ:- Ifa leleyii yoo lọ sibikan, Ifa niwon yoo rolẹ lẹ deleyii nibẹ, Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, keleyii to lọ,
kiwọn ma baa seku peleyii nibẹ loju Irẹtẹ-Ọkanran. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kolọ BỌFA pẹlu EWURẸ. Ifa
ni keleyii o BỌ BABA ati IYA RẸ. Kofi OBI bọ baba ati iya rẹ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa leleyii yoo sẹgun.
Ko FEWURẸ BỌFA pẹlu ẸGBẸTALALOGUN OWO.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona quiere ir a un sitio, ifa dice que van a preparar las medicinas malas alli,
esperando a esta persona que venga para matarle. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio antes de
irse, para que no le matan en el signo de Irẹtẹ-Ọkanran. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio,
debe DAR DE COMER A IFA con CHIVA. Ifa dice que esta persona debe DAR DE COMER A SU PADRE
y SU MADRE con COLA. (Rogar las cabazas su padre y de su madre con cola). Ifa dice que esta
persona debe DAR DE COMER A IFA con CHIVA y con CUATRO MIL SEIS CIENTOS DE DINERO.

ẸSẸ KEJI.

Ifa ni keleyii ma gbagbe abawaiye-rẹ, koma baa se wahala lasan. Ifa leleyii yoo kan ma sisẹ, koni rere, koni
roju owo, koni kole, koni sehun to dara, eleyii yoo sisẹ-sisẹ, koni nisinmi. Ifa ni keleyii ma malọ soko lọjọ
isinmi.
Toba jẹ musulumi leleyii, ko malọ soko lọjọ Friday. Toba jẹ christian leleyii, koma lọ soko lọjọ Sunday. Toba
jẹ babalawo leleyii, ko malọ soko lọjọ ọsẹ-Ifa, koma ya ọjọ ọsẹ-Ifa si mimọ lati mafi sin Oosa, keleyii o ma
baa mase wahala lasan. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona no debe olividarse de como ha venido al mundo, no debe olividarse de sus
principio, para no seguir trabajando sin frutos. Ifa dice que esta perona esta trabajando sin frutos, sin
ganancias, que no puede recuperar el dinero invertido en su negocio, no puede edificar ni comprar casa, no
ha hecho nada buena y esta trabajando sin descansar. Ifa dice que esta persona no debe ir al campo a
trabajar en los dias de descanso, que no debe ir a trabajar en los dias de descanso.
Si esta persona es musluman, no debe ir a trabajar los viernes. Si esta persona es cristiano, no debe ir a
trabajar los domingos. Si esta persona es babalawo, no debe ir a trabajar los dias de “ọsẹ-Ifa”. Que debe
respetar los dias de“ọsẹ-Ifa” como el dia del Santo y sagrado, para adorar y alabar a los Santos, para que
esta persona no siga trabajando sin tener frutos. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Irẹtẹ-Ọkanran. (Irẹtẹ-Ọkanran)
Tani jẹ gbagbe abawaiye ẹni. (?Quien puede olividarse de como ha venido al mundo / sus
principios)
Ẹni ba gbagbe abawaiye rẹ. (El que se olivida de como ha venido al mundo)
A sisẹ-sisẹ ku o. (Trabajara hasta murirse)
A dia fun Ọrunmila. (Se advino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba nfọjọ Edu roko. (El dia que el padre iba al campo el dia de Edu a trabajar)
Ẹbọ niwọn niki baba o se. (Dijieron al padre que debe hacer el sacrificio)
Baba gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (El padre lo hizo)
Riru ẹbọ ni fin ti gbeni. (Haciendo el sacrificio que se levanta y se acepta es lo que
ayuda a uno)
A tete ru tesu a dara danu. (Apasiguando a esu pronto desvia la mala suerte)
Baba gbọ riru, o ru. (El padre oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbo loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Ẹ ma majẹ ka fọjọ Ẹdun roko. (Ustedes no déjà que vamos al campo en los dias de Ẹdun)
Nitori atila ẹni. (Para que uno puede prosperar)
Ko pẹ o, ko jinna. (Pronto y no tan lejano)
Ifa wa bani nijẹbutu ire. (Ifa ven a encontranos en la celebracion de bendicion)
Ijẹbutu ire nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion se encuentra uno a los pies
del Rey de los Orisas)

ASÉ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni keleyii ma malọ soko lọjọ isinmi, keleyii le ba saseyọri nibi isẹ rẹ.

ASÉ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona debe respetar los dias
de Santo como un dia sagrado para descansar, para alabar y adorar a los Santos, lo cual permitira a esta
persona prosperar en su trabajo.

14.9. IRẸTẸ-EGUNTAN (OGUNDA)

ẸSẸ KINNI.

Ire Gbogbo. (Todas las bendiciones)

Irẹtẹ-Eguntan la npeni Irẹtẹ-Ogunda. Ifa nwi feleyii wipe kolọ TẸFA, ki gbogbo egun ti nbẹ lori rẹ lee tan,
awọn egun idile, awọn egun buruku, towa lori rẹ, ko lee tan, keleyii lee baa debiti Eledumare kọ feleyii wipe
yoo de.
Ifa ni keleyii lọ TẸFA ni loju Irẹtẹ-Eguntan, ki gbogbo oke isoro eleyii lee baa lọ silẹ. Teleyii ba tẹfa, tiko ba
rọmọ bi, yoo bimọ. Tiko rojutu isẹ rẹ, yoo lojutu. Gbogbo nkan eleyii yoo dara. Egun yoo kuro lori eleyii. O
se se kojẹ pawọn baba eleyii niwọn legun yii, towa ran eleyii. Teleyii bati TẸFA, gbogbo awọn egun yii yoo
kuro lori eleyii. Eleyii yoo wa debiti Olodumare kọ silẹ feleyii ninu akọsilẹ. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa
na sọ pe:

Irẹtẹ-Eguntan es lo que llamamos Irẹtẹ-Ogunda. Ifa le esta diciendo a esta persona que debe INICIARSE EN
IFA, para que todas las maldiciones y las maldiciones malas de la familia que esta persona lleva encima se
terminan para siempre, para que esta persona puede llegar a donde Olodumare ha destinado que tenia que
llegar.
Ifa dice que esta persona debe INICIARSE EN IFA en el signo de Irẹtẹ-Eguntan . Si esta persona se inicia en
Ifa, si ha tenido problema para tener hijo, tendra hijo. Si no ha prosperado en su trabajo, prosperara en su
trabajo. Todas las cosas de esta persona iran bien. Vencera las maldiciones totalmente. Puede ser que esas
maldiciones lo tenain sus abuelos y lo esta pagando esta persona. Si esta persona se inicia en Ifa, terminara
con todas esas maldiciones y vencera a todas esas maldiciones. Apartir de alli, esta persona llegara a donde
Olodumare ha destinado que tenia que llegar. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Irẹtẹ-Ogunda rọ aatẹ. (Irẹtẹ-Ogunda apasiguo a aatẹ)


Kara o rọọ o. (Que le apasiguar el cuerpo)
A dia fun Peregun. (Se adivino Ifa para Peregun)
Ti sọmọ wọn nigba igbawasẹ. (Que era el hijo de ellos al pricipio del mundo)
Wọn niki Peregun wa rubọ. (Dijieron a Peregun que debe hacer el sacrificio)
Kara o lee rọọ. (Para que su cuerpo sea apasiguado)
Kowa TẸFA. (Que debe INICIARSE EN IFA)
Kọna rẹ lee ma la. (Para que sus caminos se abren)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Aiye wa rọọ Peregun titi aiyeraiye. (La vida del Peregun ha sido apasiguado para siempre)
O wa donigba asọ. (Se convertio en el dueno de dos cientos ropas)

Ara ko rọọ Peregun tẹlẹ, ko lasọ lara. Oju asọ, ọmọ ati ire gbogbo npọn Peregun. Peregun jẹ ara awọn igi
oko. Peregun ba rubọ, o se gbogbo ohun tawọn babalawo ni kose, niwọn ba tẹ Peregun NIFA. Ọrunmila lo
tẹ gbogbo ẹran oko nifa, Ọrunmila naa lo tẹ gbogbo igi oko nifa. Nitori p’Ọrunmila gbede gbogbo ẹran oko,
o gbede gbogbo igi oko, o gbede gbogbo ọmọ eniyan.

Olodumare ti f’Ọrunmila salakoso lori ohun gbogbo. Ohun laye se gba peregun titi doni ninu igbo igbalẹ.
Tiwọn bafẹ tẹgbo kan, bi igbo irunmọlẹ, Peregun la o ba nibẹ. Peregun lasọ, o rẹwa, ọkan rẹ balẹ, o tuba, o
tusẹ. Nigba ti gbogbo nkan dara tan, ni Peregun ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa;
O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Peregun no estaba bien anteriormente, no estaba tranquillo, no tenia ropas. Peregun estaba apurado por
tener ropas, hijos y todas las bendiciones. Peregun era uno de los arboles del campo. Peregun hizo el
sacrificio y los demas cosas que le mandaron a hacer los babalawos, INICIARON PEREGUN EN IFA.
Ọrunmila fue el que inicio a todos los animales del campo en Ifa. Ọrunmila fue el que inicio a todos los
arboles del campo en Ifa. Ọrunmila entiende las idiomas de todos los animales, los arboles del campo y los
seres humanos.
Olodumare hizo a Ọrunmila el jefe y el Ọrunmila manda sobre todas las cosas en el mundo. Por eso
Peregun se encuentra comfortable en el bosque sagrado de Ifa hasta la fecha de hoy. Si quieren hacer la
iniciacion en Ifa en un bosque, como el bosque sagrado de las diedades, es Peregun que vamos a encontrar
alli. Peregun se convertio en duenos de ropas, peregun es bello, Peregun logro su bien estar, todas las cosas
iban bien para Peregun. Peregun estaba feliz, empezo a bailar y cantar; Que asi mismo lo han
adivinados y cantados sus awos; QUE:

Irẹtẹ-Ogunda rọ aatẹ. (Irẹtẹ-Ogunda apasiguo a aatẹ)


Kara o rọọ o. (Que le apasiguar el cuerpo)
A dia fun Peregun. (Se adivino Ifa para Peregun)
Ti sọmọ wọn nigba igbawasẹ. (Que era el hijo de ellos al pricipio del mundo)
Wọn niki Peregun wa rubọ. (Dijieron a Peregun que debe hacer el sacrificio)
Kara o lee rọọ. (Para que su cuerpo sea apasiguado)
Kowa TẸFA. (Que debe INICIARSE EN IFA)
Kọna rẹ lee ma la. (Para que sus caminos se abren)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Aiye wa rọọ Peregun titi aiyeraiye. (La vida del Peregun ha sido apasiguado para siempre)
O wa donigba asọ. (Se convertio en el dueno de dos cientos ropas)

O nse: ORIN. (CANCION)

Ara wa rọọ Peregun titi aiyeraiye. (La vida de Peregun ha sido apasiguado para siempre)
Peregun wa doni gba asọ. (Peregun se convertio en el dueno de dos cientos ropas)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Ara wa rọọ Peregun titi aiyeraiye. (La vida de Peregun ha sido apasiguado para siempre)
Peregun wa doni gba asọ. (Peregun se convertio en el dueno de dos cientos ropas)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kolọ TẸFA. Ifa ni gbogbo egun towa lori rẹ patapata, gbogbo isoro
teleyii ni, gbogbo idamu teleyii ni, gbogbo wọn yoo wọlẹ. Teleyii yoo donire gbogbo, teleyii yoo sẹgun. Ifa
leleyii yoo sẹgun, koni si wahala Kankan mọ nigbesi aiye eleyii. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe INICIARSE EN IFA. Ifa dice que todas las
maldiciones que lleva esta persona encima, todos sus apuros, todos sus problemas se terminaran y se
venceran para siempre. Ifa dice que esta persona tendra todas las bendiciones y vencera. Ifa dice que esta
persona vencera para siempre y no tendra ningun problema en su vida jamas. Ifa dice que esta persona
debe hacer el sacrificio.
ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun ohun gbogbo. (Investigar el vencimiento de todas las cosas)

Ifa laarin ipọnju leleyii wa. Ifa tun nsọ feleyii lẹkeji, wipe kolọ TẸFA, Kole sẹgun lori ohun gbogbo. Tiwọn
bani eniyan wa ninu ipọnju, itumọ rẹ ni wipe eleyii wa ninu wahala gidi. Teleyii ba sẹbọ, gbogbo ipọnju yi
yoo kuro lara eleyii, ti koni waiye mọ. Eleyii gbọdọ TẸFA to bafẹ sẹgun. Ifa lodi dandan keleyii o TẸFA,
ohun leleyii file saseyọri, ohun lofi lee lowo, ohun lofi lee lọla, ohun lofi lee nire gbogbo, ohun lẹmi rẹ fi lee
gun. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona esta en apuros. Ifa vuelve a institir a esta persona por segunda vez que esta
persona debe INICIARSE EN IFA, para que puede vencer sobre todas las cosas. Cuando dicen que una
persona esta en apuros, eso quiere decir que esa persona tiene problema seriamente. Si esta persona hace el
sacrificio, vencera a sus apuros totalmente y esos apuros no volveran a repetirse jamas. Ifa dice que esta
persona debe iniciarse en Ifa si quiere vencer. Ifa dice que esta persona debe INICIARSE EN IFA
OBLIGATORIAMENTE, eso es lo que va hacer a esta persona prosperar, eso es lo que va a hacer a esta
persona tener dinero, eso es lo que va a hacer a esta persona tener las riquezas, eso es lo que va a hacer a
esta persona tener todas las bendiciones, eso es lo que va a hacer a esta persona tener la larga vida. Ifa lo
dice asi con este verso; QUE:

Irẹ ntẹ mi lọwọ. (El grillo “Irẹ” esta imprimiendo en mi mano)


Irẹ ntẹmi lori. (El grillo “Irẹ” esta imprimiendo en mi cabeza)
Taba mabawaiye ẹni. (Si sabemos como hemos venido al mundo/ los principios de uno)
Asi sisẹ kun-un. (Debemos trabajar aun mas)
Ori a yani. (Uno se siente mas animado)
Inu ẹni a sidun jọjọ. (Uno se siente bastante feliz)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Alade nbẹ laarin ipọnju. (El Coronado estaba en el medio de los apuros)
Wọn ni ko rubọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Ọdun ni, ọrọ-rẹ de o. (Que este ano le llegara sus riquezas)
Alade gbọ riru, o ru. (El Coronado oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Seni ara rọọ alade bi koko towa lakurọ. (El cuerpo del Coronado se apasiguo como el recipiente arcilla en
la refineria tradicional de aceite rojo)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ara wa rọọ alade bi koko towa lakurọ. (El cuerpo del Coronado se apasiguo como el recipiente arcilla en
la refineria tradicional de aceite rojo)
Ara wa rọọ Alade nigba to TẸFA tan, gbogbo wahala towa ninu aiye rẹ, ara wa rọọ patapata. O wa dẹni to
nsisẹ, to nrojutu rẹ. O dẹni to nire gbogbo. Loba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin
Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

El cuerpo del Coronado se apasiguo despues de iniciarse en Ifa, todos los problemas y apuros de su vida se
apasiguaron totalmente. Se convertio en una persona que esta trabajando y sacando frutos de sus trabajos.
Se convertio en dueno de todas las bendiciones. El coronado estaba feliz, empezo a bailar y cantar, que
asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Irẹ ntẹ mi lọwọ. (El grillo “Irẹ” esta imprimiendo en mi mano)


Irẹ ntẹmi lori. (El grillo “Irẹ” esta imprimiendo en mi cabeza)
Taba mabawaiye ẹni. (Si sabemos como hemos venido al mundo/ los principios de
uno)
Asi sisẹ kun-un. (Debemos trabajar aun mas)
Ori a yani. (Uno se siente mas animado)
Inu ẹni a sidun jọjọ. (Uno se siente bastante feliz)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Alade nbẹ laarin ipọnju. (El Coronado estaba en el medio de los apuros)
Wọn ni ko rubọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Ọdun ni, ọrọ-rẹ de o. (Que este ano le llegara sus riquezas)
Alade gbọ riru, o ru. (El Coronado oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Seni ara rọọ alade bi koko towa lakurọ. (El cuerpo del Coronado se apasiguo como el recipiente arcilla en
la refineria tradicional de aceite rojo)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ara wa rọọ alade bi koko towa lakurọ. (El cuerpo del Coronado se apasiguo como el recipiente arcilla en
la refineria tradicional de aceite rojo)
Asẹyin wa o, asẹyin bo. (Despues de todos)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes han visto lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ko pẹ o, ko jinna. (Pronto y no tan lejano)
Ifa wa bani laarin iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio de vencimiento)
Aarin iṣẹgun, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies del
Rey de los Orisas)

O nse: ORIN. (CANCION)

Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes han visto lo que el awo adivino se hizo realidad)
Ẹ wa wofa awo ki biti nsẹ. (Ustedes han visto lo que el awo adivino se hizo realidad)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Nse lara wa rọọ alade bi koko towa lakurọ. (El cuerpo del Coronado se apasiguo como el recipiente
arcilla en la refineria tradicional de aceite rojo)
Gbẹdẹ lara rọọ wa o. (Tranquilamente nos apasiguaran el cuerpo)
ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa lara yoo rọọ eleyii nibẹ. Ifa ni keleyii lọ TẸFA nibẹ, ko lee sẹgun
ni gbogbo igbesi aiye rẹ. Gbẹdẹ lara o rọọ eleyii.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que el cuerpo de esta persona se
apasiguara. Ifa dice que esta persona debe INICIARSE EN IFA, para que puede vencer en toda su vida.
Tranquilamente se apasiguara el cuerpo de esta persona.

14.10. A rọtẹ tan, o nsa. (Irẹtẹ -Ọsa)

ẸSẸ KINNI.

Ire ilọsiwaju (Bendicion de prosperidad)

Irẹtẹ -Ọsa ni a npeni “A rọtẹ tan, o nsa”. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni gbogbo idaamu ti nbeleyii, gbogbo
ohun toju eleyii nri, yoo feleyii silẹ, teleyii yoo tẹ gbogbo rẹ molẹ patapata. Ifa leleyii yoo si nilaari. Gbogbo
idamu, gbogbo wahala ni yoo feleyii silẹ, teleyi yoo nilaari, yoo lowo, teleyii bati rubọ nibẹ. Ibi tifa wa gba
tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Irẹtẹ -Ọsa es lo que llamamos “A rọtẹ tan, o nsa” (Ya hemos visto las conspiraciones y te hecha a correr). Ifa
dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que todos los problemas que esta pasando esta
persona, todos lo que esta sufriendo esta persona seran vencidos, superara a todos sus problemas y apuros
totalmente. Ifa dice que esta persona prosperara. Esta persona vencera a todos sus apuros y problemas
totalmente, Ifa dice que esta persona prosperara y tendra dinero si hace el sacrificio. Ifa lo dice asi con este
verso; QUE:

A rọtẹ tan, o nsa. (Ya hemos visto las conspiraciones y te hecha a correr)
Egun aja lo taja din. (El hueso del perro es capaz de freir al perro)
Akọọ lo tejo min. (Akọọ es capaz de tragar el serpiente)
Ọba loto ori esunsun jẹ. (El Rey es el que es capaz de comer las cabezas de “Esunsun”)
A difa fun Segbemi. (Se adivino Ifa para Segbemi)
Eyiti nsọmọ Ọba lẹyin ajo. (El que era el hijo del Rey en el extranjero)
Ẹbọ niwọn ni o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)
Riru ẹbọ ni fin ti gbeni. (Haciendo el sacrificio que se levanta y se acepta es lo que ayuda a
uno)
A tete rutesu a dara danu. (Apasiguando a Esu pronto desvia la mala suerte)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Segbemi wa dolokun, o donidẹ. (Segbemi se convertio en dueno de los oceanos y bronces)

Segbemi jọmọ Ọba kan lẹyin ajo. Nigba ti segbemi yoo fi kuro nile, o tini wahala. Ko rọrun fun-un lati lowo,
ko rowo na, ko rọrun fun-un lati se nkankan dada. Ni Segbemi balọ sirin ajo. Nigba to dọhun. Niwọn ba
dafa fun-un. Wọn niki Segbemi o rubọ o. Wọn ni to bati rubọ, wọn ni gbogbo idamu toju rẹ nri, wipe
gbogbo rẹ ni yoo tẹ mọlẹ, ti yoo si nilaari.
Segbemi ko pawo leke. Ko pesu lole. Segbemi gbọ riru, o ru. O gbọ titu, o tu. O gbọ ọhahaha ẹbọ loju
ọpọn, o ha. Bayi layipada sede ba Segbemi. Segbemi sẹgun ọta mọrẹ. Ọna Segbemi la. Segbemi dẹni tiwọn
nkesi lawujọ. Segbemi dẹni taraiye nduro de kiwọn tose nkan. Bayi ni Segbemi se ranti awọn awo tiwọn
dafa fun-un. Segbemi ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ
lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Segbemi era el hijo de un Rey en el extranjero. Cuando Segbemi iba a déjà su pueblo natal, ya tenia
problemas. No le resulta facil conseguir dinero, no le resulta facil enfrentar los gastos de sus nesecidades, no
le resulta facil hacer nada. Segbemi se fue de viaje, cuando llego al sitio que iba, le hicieron consulta con Ifa.
Dijieron al Segbemi que debe hacer el sacrificio. Dijieron que si el Segbemi hace el sacrificio, vencera a todos
sus apuros y sufrimientos que eataba pasando totalmente.
Segbemi no llamo al awo mentoroso. No llamo al esu ladron. Segbemi oio el sacrificio y sacrifico. Oio el
ofrecimiento y ofrecio. Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de Ifa. Asi fue como cambio la
vida de Segbemi. Segbemi vencio a sus enimigos totalmente. Los caminos de segbemi abrieron. Segbemi se
convertio en una persona que la comunidad invita a las ocaciones. Segbemi se convertio en alguien que todo
el mundo le espera antes de hacer cualquier cosa. Segbemi se acuerda de sus babalawos. Segbemi estaba
feliz, empezo a bailar y cantar; Que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

A rọtẹ tan, o nsa. (Ya hemos visto las conspiraciones y te hecha a correr)
Egun aja lo taja din. (El hueso del perro es capaz de freir al perro)
Akọọ lo tejo min. (Akọọ es capaz de tragar el serpiente)
Ọba loto ori esunsun jẹ. (El Rey es el que es capaz de comer las cabezas de “Esunsun”)
A difa fun Segbemi. (Se adivino Ifa para Segbemi)
Eyiti nsọmọ Ọba lẹyin ajo. (El que era el hijo del Rey en el extranjero)
Ẹbọ niwọn ni o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)
Riru ẹbọ ni fin ti gbeni. (Haciendo el sacrificio que se levanta y se acepta es lo que ayuda a
uno)
A tete rutesu a dara danu. (Apasiguando a Esu pronto desvia la mala suerte)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Segbemi wa dolokun, o donidẹ. (Segbemi se convertio en dueno de los oceanos y bronces)
Ko pẹ o, ko jinna. (Pronto y no tan lejano)
Ifa wa bani laarin iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio del vencimiento)
Aarin iṣẹgun, n la a bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies del Rey de
los Orisas)

O nse: ORIN. (CANCION)

Segbemi wa dolokun, o donidẹ. (Segbemi se convertio en dueno de los oceanos y bronces)


Segbemi wa dolokun, o donidẹ. (Segbemi se convertio en dueno de los oceanos y bronces)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Segbemi wa dolokun, o donidẹ. (Segbemi se convertio en dueno de los oceanos y bronces)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni gbogbo wahala toju eleyi nri yi, to bati rubọ, yoo tẹ gbogbo rẹ
mọlẹ patapata. Ifa ni yoo si nilaari loju Irẹtẹ-Ọsa.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que todos los problemas que esta
pasando esta persona, si hace el sacrificio, vencera a sus problemas y apuros totalmente. Ifa dice que esta
persona prosperara en el signo de Irete-Ọsa.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun awọn aiye. (Investigar el vencimiento de los brujos/as)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kole baa yọ lọfin aiye. Ọlọrun koni jẹ ki eleyii o ja sọfin-aiye o. Ohun to njọfin-aiye
ni wahala lọtun, wahala losi, koni sisinmi feleyii, ko silọsiwaju feleyii. Awọn aiye koni jẹ keleyii se nkan to
dara, awọn iyami kojẹ keleyii gbadun aiye rẹ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koto niru isoro bayi, keleyii ma
baa ja sọfin-aiye. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio para escapar de las trampas de los brujos/as. Olodumare
no va permitir que esta persona entra en las trampas de los brujos/as. Lo que se llama las trampas de los
brujos/as son problemas por la derecha, problema por la izquierda, problemas por todos lados, problemas
que no le déjà descansar, problemas que no déjà prosperar a esta persona. Los brujos/as no le dejan hacer
las cosas buenas. Las brujos/as no le dejan disfrutar su vida. Ifa dice que esta persona debe hacer el
sacrificio antes de tener este tipo de problema, para que esta persona no entra en las trampas de los
brujos/as. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Opẹri kẹtẹ-yẹkutẹ. (Opẹri kẹtẹ-yẹkutẹ)


Ohun lo tidi bọgbẹ. (Se metio la nalga/culo en el bosque)
O tẹwọ rẹrẹrẹ soloko. (Extendio las manos al dueno del campo cultivo)
A dia fun Kudina. (Se adivino Ifa para Kudina)
Eyiti baba rẹ yoo gba igba ori-ẹran. (El que su padre iba pedirle dos cientos cabezas de
animales)
Oosa lo bẹ lọwẹ. (Pidio ayuda a Oosa)
Wipe ko baun wa igba ori-ẹran. (Para que le busca dos cientas cabezas de animales)
Oosa wa ndẹgbo lọ. (Oosa se iba de caza en el bosque)

Oosa ni Kudina bẹ lọwẹ wipe ko boun wa igba ori-ẹran toun yoo fibọ baba oun. Nigba t’Oosa nwori-ẹran lọ,
awọn tẹnbẹlẹkun wa gboju ọna. Awọn ọta niwọn npeni tẹnbẹlẹkun. Wọn dii lọna, wọn lawon koni jẹ kolọ.
Wọn ti dẹgbo-dẹgbo-dẹgbo, wọn ko rẹran pa. Biwọn se bọpọlọ ninu koto niyi , Wọn nwo ọpọlọ ninu koto
lọọkan. Ọpọlọ nibo niwọn nlọ. Oosa ni wipe Kudina lo bẹun lọwẹ, wipe oun fẹ bọri baba oun, wipe koun
baun wa igba ori-ẹran. Ọpọlọ nigba ori-ẹran bawo. Ọpọlọ nigba ori ẹni tolee kọrin fun-un ni Kudina nwa.
Ọpọlọ bani kiwon o yọun lọfin. Biwọn se yọpọlọ niyi.
Nijọ ti gbogbo wọn njin sọfin aiye. Wọn ni kwọn o rubọ. Ọpọlọ rubọ nibẹ, loba sẹgun. Asẹyin wa o, asẹyin
bọ. Ẹnlọjọ ọpọlọ yọ lọfin aiye. Ni Oosa ati ọpọlọ balọ sọdọ Kudina. Nigba tiwọn dọdọ Kudina wipe awọn
koma rigba ori-ẹran. Kudina loun kope k’Oosa baun wagba ori-ẹran, wipe igba ori ẹniti yoo baun jo, nigba
toun ba nsọdun loun ni ko baun wa. Bi gbogbo awọn ọpọlọ se debẹ niyi, tiwon njo orisirisi ijo, tigba eniyan
lee jo.

Kudina pidio la ayuda al Oosa para que le ayuda buscar a los dos cientas cabezas de animales, para dar de
comer su padre. Cuando Oosa iba de caza en el bosque, los “tẹnbẹlẹkun” enimigos le cruzaron el camino.
Los enimigos dijieron que no iban a dejarle ir a ningun sitio. Oosa ya habia recorrido el bosque durante
mucho tiempo sin encontrar a ningun animal para cazar. De repente vieron un sapo en un agujero
profundo. Estaba mirando al sapo en el agujero. El sapo pregunto al Oosa por donde iba. Oosa contesto al
sapo que Kudina le pidio en ayudarle para buscar dos cientas cabezas de animales, para dar de comer su
padre. El sapo dijo que:! dos cientas cabezas de animales!. El sapo dijo que son dos cientas cabezas de las
personas que pueden cantar para Kudina en el fiesta de dar de comer a su padre. El sapo suplico a Oosa que
le saca del agujero y que iba a ir con Oosa a Kudina. Oosa saco el sapo del agujero.
El dia que todos ellos estaban entrandos en las trampas de los brujos/as, dijieron que deben hacer el
sacrificio. El sapo hizo el sacrificio y vencio. Despues de todos. Todos los sapos salieron de de las trampas de
brujos/as. Oosa y el sapo se fueron a ver al Kudina que no han encontrado dos cientas cabezas de animales.
Kudina dijo que no estaba buscando dos cientas cabezas de animales, sino que el queria dos cientas cabezas
de las personas que podian bailar con el en su fiesta. Asi se reunieron todos los sapos y empezaron a bailar
todos tipos de bailes que podian bailar dos cientas personas.
ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, keleyii ma baa jasi ọfin aiye.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio para que no entra en las trampas de los
brujos/as.

14.11. ATẸ-KA (IRẸTẸ-IKA)

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo iku. (Investigar la muerte)

Ifa ni keleyii o rubọ nitori iku, kẹmi-rẹ baa lee gun. Ifa ni teleyii ko baku, Ifa nire gbogbo yoo soju eleyii. Ifa
ni keleyii o rubọ iku, kiku ma peleyii, kẹmi rẹ baa lee gun. Ifa ni teleyii ko baku, Ifa leleyii yoo ma rire
gbogbo loju Aatẹ-ka . Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio por la muerte, para que tenga larga vida. Ifa dice que si no
muere esta persona, Ifa dice que presenciara y disfrutara de todas las bendiciones. Ifa dice que esta persona
debe hacer el sacrificio por la muerte, para que tenga larga vida. Ifa dice que si no muere esta persona, Ifa
dice que esta perona conseguira todas las bendiciones en el signo de Aatẹ-ka . Ifa lo dice asi con este verso;
QUE:

Aatẹ-ka awo Olubadan. (Aatẹ-ka es el Awo del Rey de la ciudad de Ibadan)


Lo difa fun Olugbẹgi-Edu. (Adivino Ifa para Olugbẹgi-Edu)
Bi Olugbẹgi-Edu o baku o. (Si Olugbẹgi-Edu no muere)
Gbogbo awo ni yoo kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Ọtarigi babalawo, babalawo to gbona gidigidi ni Olugbẹgi-Edu. Wọn ni k’Olugbẹgi-Edu o rubọ. Wọn ni
t’Olugbẹgi-Edu bati rubọ, wọn lẹmi rẹ yoo gun, koni tete ku. Wọn ni tiko bati tete ku, gbogbo awọn awo
towa lẹgbẹ rẹ, towa labẹ rẹ, gbogbo wọn ni o kakila. Olugbẹgi-Edu gbọ riru, o ru. O gbọ titu, o tu. O gbọ
ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. Olugbẹgi-Edu sunmọ awọn babalawo, wọn jewe Ifa fun-un. B’Olugbẹgi-Edu se
dẹlẹmi gungun niyi. Olugbẹgi-Edu njo, ti nyọ, ti gbogbo nkan rẹ ndara, ti gbogbo nkan rẹ ntoro, o niyi
kaiye. Ta bade Kogi ni Ilesha, o lokiki. Ni Olugbẹgi-Edu ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ
si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Olugbẹgi-Edu eran un babalawo muy muy bueno y con buen conocimiento de Ifa. Dijieron a Olugbẹgi-Edu
que debe hacer el sacrificio. Dijieron que si Olugbẹgi-Edu hace el sacrificio, que tendra larga vida, que no iba
a murir pronto. Dijieron que si Olugbẹgi-Edu no muere pronto, que todos los awos que esta a su alrededor y
los Awos que estan bajo su control, que todos ellos adivinaran a Ifa para hacerse ricos. Olugbẹgi-Edu oio el
sacrificio y sacrifico. Oio el ofrecimiento y ofrecio. Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de
Ifa. Olugbẹgi-Edu se acerco a los babalawos y le prepararon las hierbas de Ifa. Olugbẹgi-Edu se convertio en
alguien con larga vida. Olugbẹgi-Edu estaba feliz y bailando cuando las cosas le salieron bien, era popular
por todo el mundo. Olugbẹgi-Edu es popular en Kogi en la provincial de Ilesha. Olugbẹgi-Edu estaba feliz,
empezo a bailar y cantar; Que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Aatẹ-ka awo Olubadan. (Aatẹ-ka es el Awo del Rey de la ciudad de Ibadan)


Lo difa fun Olugbẹgi-Edu. (Adivino Ifa para Olugbẹgi-Edu)
Bi Olugbẹgi-Edu o baku o. (Si Olugbẹgi-Edu no muere)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Ẹbọ niwọn ni o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)
Olugbẹgi-Edu gbọ riru, o ru. (Olugbẹgi-Edu oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ebọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ifa wa bani laarin iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio del vencimiento)
Aarin iṣẹgun, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies
del Rey de los Orisas)

O nse: ORIN. (CANCION)

Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Bi Olugbẹgi-Edu o baku o. (Si Olugbẹgi-Edu no muere)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)
Bi Olugbẹgi-Edu o baku o. (Si Olugbẹgi-Edu no muere)
Gbogbo awo ni o kakila. (Todos los awos adivinaran el Ifa para hacerse ricos)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kiku ma peleyii. Ẹbọ ẹmi gungun ni keleyii o ru nibẹ. Ifa ni teleyii koba
tiku, Ifa nire gbogbo ni yoo soju eleyii loju Aatẹ-ka.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que la muerte no le mata. Ifa dice que esta
persona debe hacer el sacrificio para larga vida. Ifa dice que si no muere esta persona, Ifa dice que
vera/presenciara a todas las bendiciones con sus propios ojos en el signo de Aatẹ-ka.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo iku ọmọ. (Investigar la muerte de hijo)

Ifa nsọ fẹni to nifa yii wipe ko rubọ, kọmọ araiye ma baa peleyii lọmọ. Kiwọn ma tibi ọmọ meleyii. Kawọn
ọmọ araiye ma ma peleyii lọmọ jẹ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koni ỌBẸ IKE lẹbọ nibẹ, koni ABẸRẸ lẹbọ nibẹ.
Ifa ni teleyii bati rubọ, wọn koni lee peleyii lọmọ.
Ifa ni laarin ọmọ- iya mẹta ni kiwọn rubọ, kawọn ọmọ araiye ma ma pawọn lọmọ jẹ. Ifa nisọri mẹta niwọn,
kawon isọri mẹtetea yi rubọ. Boya ọkọ wọn niyawo mẹta, kawọn isọri mẹta yi rubọ nibẹ, kaiye ma baa ma
tibi ọmọ muwọn. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa le esta diciendo a esta persona debe hacer el sacrificio para que las gentes no matan a sus hijos. Para que
las gentes no atrapan a esta persona atravez de sus hijos. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio,
debe tener NAVAJITA DE IKE en su sacrificio, debe tener AGUJA en su sacrificio. Ifa dice que si esta
persona hace el dsacrificio, no van a poder matar sus hijos.
Ifa dice que deben hacer el sacrificio entre tres hermanos de la misma madre, para que las gentes no matan
a sus hijos. Ifa dice que son tres hermanos de la misma familia, que esos tres hermanos deben hacer el
sacrificio. Puede ser que el marido tiene tres esposas, que las tres deben hacer el sacrificio, para que las
gentes no atrapan a estas personas atravez de sus hijos. Ifa lo esta diciendo a esta persona. Ifa lo dice asi con
este verso; QUE:
Aatẹ-ka awo Ila. (Aatẹ-ka era el awo del Kimbobo. “Ila”)
Lo difa fun Ila. (Adivino Ifa para el Kimbobo. “Ila”)
Aatẹ-ka awo Ikan. (Aatẹ-ka era el awo del Huevo de jardin. “Ikan”)
Lo difa fun Ikan. (Adivino Ifa para el Ikan)
Aatẹ-ka Awo Bobo-Awodi. (Aatẹ-ka es el awo de Bobo-Awodi)
Lo difa fun Bobo-Awodi. (Adivino Ifa para el “Bobo-Awodi”)
Wọn ni kiwọn o rubọ. (Dijieron que deben hacer el sacrificio)
Bobo-Awodi nikan lo gbebọ nibẹ, to rubọ. (Solamente el Bobo-Awodi hizo el sacrificio)
Ila ati Ikan, wọn kọ, wọn ko rubọ. (Ila y Ikan se negaron en hacer el sacrificio)
Esu aisẹbọ. (La tentacion de no hacer el sacrificio)
Ẹgba aiteru. (La paralisis de no apasiguar a Esu pronto)
Ohun lomu Ila ati Ikan di jijẹ fọmọ araiye. (Por eso Ila y Ikan se convertieron en algo de comer
para las gentes del mundo)
Bobo-Awodi gbọ riru, o ru. (Bobo-Awodi oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la
adivinacion)

Ọmọ- iya mẹta ni Ila, Ikan ati Bobo-Awodi. Bobo-Awodi la npeni “ma fọwọ kan ọmọ mi”. Ila ati Ika, wọn kọ,
wọn ko rubọ. Bobo-Awodi nikan lo rubọ. ABẸRẸ tofi rubọ nijọ naa, ohun lẹgun towa lara ọmọ rẹ. ỌBẸ IKE
tofi rubọ nijọ naa, ohun lo lẹmọ ara ọmọ rẹ. Bobo-Awodi ti rubọ ni tirẹ. Sugbọn Ila ati Ikan, wọn ko rubọ,
ohun lose di wipe awọn ọmọ araiye nka ọmọ mọ a ati Ikan lara lati jẹ. Bobo Awodi ti rubọ ni tirẹ, ti eniyan
bafẹ mọmọ Bobo Awodi, abẹrẹ towa lara ọmọ-rẹ yoo gun onitoun ni, tẹjẹ yoo yọ nibẹ. Esu aisẹbọ. Ẹgba
aiteru. Ohun lomu Ila ati Ikan di jijẹ fọmọ araiye.

Ila, Ikan y Bobo-Awodi son hermanos de la misma madre. Bobo-Awodi significa que : “no toca a mis hijos”.
Ila y Ikan se negaron en hacer el sacrificio. Solamente el Bobo-Awodi hizo el sacrificio. La aguja con la que
Bobo-Awodi hizo el sacrificio, esa es la que lleva su hijo hasta la fecha de hoy. Bobo-Awodi hizo su sacrificio.
Ila y Ikan se negaron en hacer el sacrificio, por eso se convertieron en algo de comer para las gentes del
mundo. Bobo-Awodi hizo su sacrificio, si una persona quiere coger el hijo de Bobo-Awodi, la aguja que lleva
el hijo de Bobo-Awodi pinchara a esa persona hasta sangrarse. La tentacion de no hacer el sacrificio. La
paralisis de no apasiguar a Esu pronto. Por eso Ila y Ikan se convertieron en algo de comer para las gentes
del mundo.

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kaiye ma tibi ọmọ meleyii loju Aatẹ-ka, kiwọn ma ma paleyii lọmọ jẹ.
Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koni ỌBẸ IKE lẹbọ nibẹ, koni ABẸRẸ lẹbọ nibẹ.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que las gentes del mundo no atrapan a esta
persona atravez de sus hijos, para que las gentes no matan a los hijos de esta persona. Ifa dice que esta
persona debe hacer el sacrificio, debe tener NAVAJITA DE IKE en su sacrificio, debe tener AGUJA en su
sacrificio.
ẸSẸ KẸTA.

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kagbara rẹ lee ka gbogbo ohun toba nsakoso le lori. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ,
kagbara rẹ lee ka a. Ifa ni koni IGBA-ỌPẸ lẹbọ nibẹ, koni ẸGBA OWO lẹbọ nibẹ. Kagbara rẹ lee ka gbogbo
ohun toba nsakoso le lori, kasẹ-rẹ mulẹ, kiwọn lee ma gbọ teleyii loju Aatẹ-ka . Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ibi
tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que sea capaz de controlar y mandar todos los que
estan bajo sus autoridades/mandos. Ifa dice que debe hacer el sacrificio, debe tener IGBA-OPE “la soga que
se usa para subir al palmero”, debe tener DOS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio, para que sea capaz
de controlar y mandar todos los que estan bajo sus autoridades/mandos, para que sus ordenes sean firmes
y para que las gentes le hagan caso a todos lo que dice esta persona. Ifa dice que esta persona debe hacer el
sacrificio. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Aatẹ-ka a niyi kaiye. (Aatẹ-ka que tiene popularidad por todo el mundo)
Aatẹ-ka a niyi kalu. (Aatẹ-ka que tiene popularidad por toda la ciudad)
Aatẹ-ka lo difa fun Olu-Benin. (Aatẹ-ka adivino Ifa para el Rey de Benin)
Agba Ilẹsi (El mayor de Ilẹsi)
Ọmọ a dakẹtẹ penpe pari ogun. (Hijo del que pone la gorra chiquitita para termina la guierra)
Ẹbọ niwọn ni o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Nitori kọwọ-rẹ lee baa ka gbogbo ohun to nsakoso le lori. (Para que sea capaz de controlar y mandar
todos que estan bajo sus autoridades)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Nigba ti Olu-Benin gori oye (Cuando el Rey de Benin subio a la corona)
Lara ma ma to rọni. (Era cuando uno se encuentra comfortable)
Nigba ti Olu-Benin gori oye (Cuando el Rey de Benin subio a la corona)
Lara ma ma to rọni. (Era cuando uno se encuentra comfortable)
Nigba ti Olu-Benin gori oye (Cuando el Rey de Benin subio a la corona)
Lara tuni sẹsẹsẹ. (Era cuando uno encuentra su bien estar)
Wọn ni k’Olu Benin o rubọ, kọwọ rẹ lee baa ka gbogbo ohun to nsakoso le lori. Wọn ni koni IGBA-ỌPẸ lẹbọ
nibẹ, koni ẸGBA OWO lẹbọ ati gbogbo nkan iyoku. Olu Benin ba rubọ. Ni gbogbo nkan tusẹ, gbogbo nkan
tu sẹsẹsẹ, ara rọọ wọn, kosi wahala kankan fun tọmọde tagba, tiwọn njẹ, tiwọn nmu nirorun titi doni. Ni
Olu-Benin ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun
wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Dijieron al Rey de Benin que debe hacer el sacrificio, para que sea capaz de controlar y mandar todos
que estan bajo sus autoridades/mandos. Que debe tener IGBA-OPE “la soga que se usa para subir al
palmero” en su sacrificio, que debe tener DOS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio y los demas cosas del
sacrificio. El Rey de Benin hizo el sacrificio. Todas las cosas empezaron a ir bien, las gentes empezaron a
vivir comfortable, tantos jovenes como mayores comian y bebian bien hasta la fecha de hoy. El Rey de Benin
estaba feliz, empezo a bailar y cantar, que asi mismo lo han adivinados y cantados sus Awos; QUE:

Aatẹ-ka a niyi kaiye. (Aatẹ-ka que tiene popularidad por todo el mundo)
Aatẹ-ka a niyi kalu. (Aatẹ-ka que tiene popularidad por toda la ciudad)
Aatẹ-ka lo difa fun Olu-Benin. (Aatẹ-ka adivino Ifa para el Rey de Benin)
Agba Ilẹsi (El mayor de Ilẹsi)
Ọmọ a dakẹtẹ penpe pari ogun. (Hijo del que pone la gorra chiquitita para termina la guierra)
Ẹbọ niwọn ni o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
Nitori kọwọ-rẹ lee baa ka gbogbo ohun to nsakoso le lori. (Para que sea capaz de controlar y mandar
todos que estan bajo sus autoridades)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Nigba ti Olu-Benin gori oye (Cuando el Rey de Benin subio a la corona)
Lara ma ma to rọni. (Era cuando uno se encuentra comfortable)
Nigba ti Olu-Benin gori oye (Cuando el Rey de Benin subio a la corona)
Lara ma ma to rọni. (Era cuando uno se encuentra comfortable)
Nigba ti Olu-Benin gori oye (Cuando el Rey de Benin subio a la corona)
Lara tuni sẹsẹsẹ. (Era cuando uno encuentra su bien estar)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ifa wa bani laarin iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio de vencimiento)
Aarin iṣẹgun, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio de vencimiento se encuentra uno a los pies del Rey
de los Orisas)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni nkankan leleyii fẹ sakoso le lori yii, ko rubọ, kọwọ rẹ lee baa ka
gbogbo ohun to nsakoso le lori, ti koni si wahala Kankan rara loju Irẹtẹ-Ika. Ifa ni koni IGBA-ỌPẸ lẹbọ
nibẹ, koni ẸGBA OWO lẹbọ nibẹ.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona quiere mandar sobre
algo, que quiere tener autoridades sobre algo, que debe hacer el sacrificio, para que sea capaz de controlar y
mandar todos que estan bajo sus autoridades/mandos, para que no tenga ningun problema en el signo de
Irẹtẹ-Ika. Ifa dice que debe hacer el sacrificio, debe tener IGBA-OPE “la soga que se usa para subir al
palmero”, debe tener DOS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio.

14.12. IRẸTẸ-TUTU (OTURUPỌN)

ẸSẸ KINNI.

Ire-Ọmọ. (Bendicion de hijo)

Irẹtẹ-Oturupon ni a npeni Irẹtẹ-tutu. Ifa ni keleyii o rubọ nitori ọmọ. Ifa leleyii yoo bimọ pupọ. Ifa latiran
diran eleyii koni daamu nitori ọmọ. Ifa lọmọ koni soro funwọn rara. Ifa ni koni EWURẸ lẹbọ nibẹ, koni
AGBEBỌ ADIẸ lẹbọ nibẹ, koni ẸGBA MẸRINDINLOGUN OWO lẹbọ nibẹ. Ifa ni keleyii o rubọ silẹ, Ifa
latiran diran ọmọ eleyii ni yoo ma jahunfani ẹbọ yi lọ titi lailai, tiwọn koni daamu lori ọmọ, tiwọn yoo ma
bimọ nirọrun, ti koni si wahala, tọmọ yoo pọ funwọn loju Irẹtẹ-tutu. Ifa ni teleyii bafẹ se gbogbo nkan yi
dada, keleyii lọ TẸFA. Irọrun ni gbogbo igbesi aiye eleyii yoo jẹ, ti koni si wahala kankan feleyii. Ibi tifa wa
gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Irẹtẹ-Oturupon es lo que llamamos Irẹtẹ-tutu. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio por hijo. Ifa
dice que esta persona tendra muchos hijos. Ifa dice que todas las proximas generaciones de esta persona no
tendran problemas para tener hijos. Ifa dice que los hijos no va a ser problema para ellos. Ifa dice que esta
persona debe tener CABRA en su sacrificio, debe tener GALLINA en su sacrificio, debe tener TRES MIL
DOS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio ante-mano,
Ifa dice que sus proximas generaciones disfrutara de este sacrificio para siempre, no tendran ningun
problema sobre hijos, tendran hijos con comodidades y tenran muchos hijos. Ifa dice que si esta persona
quiere hacer todas las cosas bien, debe INICIARSE EN IFA. Ifa dice que tendra una vida comfortable y no
tendra ningun problema. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Jiji ti Irẹtẹ-tutu ji. (Nada mas que Irẹtẹ-tutu se levanto por la manana)
Seni nrọmọ gbe-jo. (Encontro hijo para bailar)
Seni nrọmọ gbe-pọn. (Encontro hijo para montarse en la esplada)
Seni nrọmọ gbe-sere. (Encontro hijo para jugar)
A dia fun Adan. (Se adivino Ifa para Adan “mucialago”)
A bu fun Oobẹ. (Tambien se adivino Ifa para Oobẹ)
Wọn ni kiwọn o rubọ nitori ọmọ. (Dijieron que deben hacer el sacrificio por hijo)
Nitori kiwọn o le baa bimọ pupọ. (Para que pueden tener muchos hijos)
Wọn gbọ riru, wọn ru. (Oieron el sacrificio y sacrificaron)
Wọn gbọ titu, wọn tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecieron)
Wọn gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, wọn ha. (Hicieron caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion
de Ifa)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Ẹyin o ripe ati ọlẹ dọlẹ niti Adan ati oun Oobẹ. (Ustedes no lo han vistos que de vientre a vientre es de
Adan y Oobẹ)

Adan atoun Oobẹ ọmọ-iya kanna niwọn. Wọn ni kiwọn o rubọ. Wọn gbọ riru, wọn ru. Wọn gbọ titu, wọn
tu. Wọn gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, wọn ha. Niwọn ba bimọ pupọ. Titi doni, tadan ba bimọ loni, ọlẹ-ọmọ
yoo tun sọ ninu rẹ. Tadan ba bimọ loni, ta batun lanu ile-ọmọ rẹ wo, a o tun bọmọ nibẹ. Atọlẹ dọlẹ niti adan
ati oun oobẹ. Ẹbọ tadan ati oobẹ ru ni titi doni oloni. Ni Adan ati Oọbẹ ba njo, wọn nyọ, wọn nyin awọn
awo wọn, awọn awo wọn si nyin Ifa; Wọn ni, bee gege lawọn awo tawọn wi, bee gege lawọn awo
tawọn sọ:

Adan y Oobẹ son hermanos de la misma madre. Dijieron que deben hacer el sacrificio. Oieron el sacrificio y
sacrificaron. Oio el ofrecimiento y ofrecieron. Hicieron caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de
Ifa. Tuvieron muchos hijos. Hasta la fecha de hoy, si Adan dar la luz a su hijo hoy, hay hijo dentro del
vientre su hijo. Si Oobẹ dar la luz a su hijo hoy, hay hijo dentro del vientre su hijo. Era el sacfiricio que Adan
y Oobẹ hicieron en su dia. Adan y Oobẹ estaban felices, empezaron a bailar y cantar; Que asi mismo lo
han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Jiji ti Irẹtẹ-tutu ji. (Nada mas que Irẹtẹ-tutu se levanto por la manana)
Seni nrọmọ gbe-jo. (Encontro hijo para bailar)
Seni nrọmọ gbe-pọn. (Encontro hijo para montarse en la esplada)
Seni nrọmọ gbe-sere. (Encontro hijo para jugar)
A dia fun Adan. (Se adivino Ifa para Adan “mucialago”)
A bu fun Oobẹ. (Tambien se adivino Ifa para Oobẹ)
Wọn ni kiwọn o rubọ nitori ọmọ. (Dijieron que deben hacer el sacrificio por hijo)
Nitori kiwọn o le baa bimọ pupọ. (Para que pueden tener muchos hijos)
Wọn gbọ riru, wọn ru. (Oieron el sacrificio y sacrificaron)
Wọn gbọ titu, wọn tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecieron)
Wọn gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, wọn ha. (Hicieron caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion
de Ifa)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Ẹyin o ripe ati ọlẹ dọlẹ niti Adan ati oun Oobẹ. (Ustedes no lo han vistos que de vientre a vientre es de
Adan y Oobẹ)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹ wa bani nijẹbutu ọmọ. (Ustedes ven a encontranos en la celebracion de
bendicion de hijo)
Ijẹbutu ọmọ laa nbani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion de hijo se encuentra uno a
los pies del Rey de los Orisas)

ASẸ-IFÁ:-Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa latiran diran eleyii ni yoo ma gbadun ọmọ titi lailai. Ifa leleyii koni ri
wahala lori ọmọ. Ifa ni koni EWURẸ lẹbọ nibẹ, koni AGBEBỌ ADIẸ lẹbọ nibẹ, koni ẸGBA
MẸRINDINLOGUN OWO lẹbọ nibẹ. Ifa ni teleyii bafẹ se gbogbo nkan yi dada, keleyii lọ TẸFA.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que las proximas generaciones de esta
persona disfrutaran de hijos para siempre. Ifa dice que esta persona no tendra problema sobre hijo. Ifa dice
que esta persona debe tener CABRA en su sacrificio, debe tener GALLINA en su sacrificio, debe tener
TRES MIL DOS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio. Ifa dice que si esta persona quiere hacer todas las
cosas bien, debe INICIARSE EN IFA.

ẸSẸ KEJI.

Ire igbega. (Bendicion de prosperidad/progreso)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kosi sunmọ awọn babalawo kiwọn baa jewe Ifa. Ifa leleyii yoo jolori, tiwọn yoo
sima gbọran seleyii lẹnu, tiwọn yoo ma gbọ tirẹ pẹlu gbogbo nkan teleyii bati sọ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ.
Keleyii si sunmọ awọn babalawo kiwọn SẸFA fun-un, ki gbesi aiye rẹ le ba a rọrun. Ifa leleyii yoo jolori,
tiwọn yoo sima gbọran seleyii lẹnu. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, Ifa ni gbogbo ohun teleyii bati sọ, niwọn yoo
ma gbọ. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y debe acercarse a los babalawos para que le preparan las
hierbas de Ifa. Ifa dice que esta persona va a ser jefe, las gentes le van a obedecer y le van a querrer con
todos lo que dice o hace. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y debe acercarse a los babalawos
para que le ENTREGA UNA MANO DE IFA, para tener una vida comfortable. Ifa dice que esta persona va
a ser jefe y las gentes le van a obedecer. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:
Ọka lo gbele baba-rẹ loro tirẹ lẹnu. (El sepiente de cascabel lleva la casa de su padre en la boca como
veneno)
Ere lo gbele baba-rẹ lọwọn. (El piton lleva la casa de su padre como ọwọn “Escaces”)
Ọla t’Olodumare ferin tiko figa. (El poder que Olodumare dio a elefante que no es alto de altura)
Ni ọwọja rẹ figun gbọgbọ-gbọrọ. (Por eso tiene la trompa tan larga)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba o jọba le gbogbo Irunmolẹ lori. (El dia que el padre iba coronarse como el Rey sobre todas
las diedades)
Wọn niki baba o rubọ. (Dijieron al padre que debe hacer el sacrificio)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Gbogbo ohun ti baba nsọ ma ma jatẹgba fun gbogbo Irunmọlẹ. (Todos lo que el padre decia fueron
aceptados por todas las diedades)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Gbogbo ohun ti baba n sọ ma ma jẹ atẹwọgba fun gbogbo irunmọlẹ. (Todos lo que el padre decia fueron
aceptados por todas las diedades)
Ko pẹ o, ko jinna. (Pronto y no tan lejano)
Ifa wa bani nijẹbutu ire. (Ifa ven a encontranos en la celebracion de bendicion)
Ijẹbutu ire, laa nbani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion se encuentra uno a los pies del Rey de
los Orisas)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa leleyii yoo jolori. Ifa ni gbogbo ohun teleyii basọ, yoo ma jatẹwọgba
fun gbogbo awọn ọmọ araiye. Ifa nigba teleyii ba jolori tan, gbogbo asẹ rẹ, atẹwọ gba ni yoo jẹ, gbogbo wọn
niwọn yoo fẹran eleyii loju Irẹtẹ-tutu. Keleyii si sunmọ awọn babalawo kiwọn SẸFA fun-un, ki gbesi aiye rẹ
le ba a rọrun.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona va a ser jefe en algo.
Ifa dice que esta persona va a ser jefe, las gentes le van a obedecer y le van a querrer con todos lo que dice o
hace en el signo de Irẹtẹ-tutu. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y debe acercarse a los
babalawos para que le ENTREGA UNA MANO DE IFA, para tener una vida comfortable.

14.13. IRẸTẸ-OTURA.

ẸSẸ KINNI.
Ayẹwo iku. (Investigar la muerte)

Ifa ni keleyii TETE lọ TẸFA, kiku ma baa peleyii. Teleyii o ba lowo ifa titẹ lọwọ, ko kesi awọn babalawo,
kiwọn baa BỌFA nibẹ. Kiwọn si belelyii jewe Ifa lẹyin igba tiwọn bati beleyii BỌFA tan, kẹmi eleyii lee baa
gun.
Keleyii FEWURẸ BỌFA, kole ba sẹgun iku naa. Ifa ni keleyii ma dẹjà rara. Ifa ni teleyii ba dẹjà, iku yoo
peleyii, laiti tọjọ toyẹ keleyii o ku. Sugbọn teleyii ba TẸFA, Ifa leleyii yoo sẹgun gbogbo awọn ọta rẹ
patapata, tigbesi aiye eleyii yoo si dara, tọna yoo si tun la feleyii. Ibi tawọn ọta kofẹ jẹ keleyii de, eleyii yoo
wa raye debẹ. Ifa ni keleyii TETE LỌ TẸFA, ko gbọdọ pẹ rara. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe INICIARSE EN IFA URGENTEMENTE, para que la muerte no mata a esta
persona. Si esta persona no tiene dinero para iniciarse en Ifa, debe llamar a los babalawos para que le
ayudan DAR DE COMER A IFA. Despues de dar de comer a Ifa, que los babalawos le preparer las hierbas
de Ifa, para que tenga larga vida.
Esta persona debe DAR DE COMER A IFA con CABRA para vencer la muerte. Ifa dice que esta persona no
debe dudar a los mensajes de Ifa. Ifa dice que si esta persona duda los mensajes de Ifa, que murira antes del
tiempo. Pero si esta persona se INICIA EN IFA, Ifa dice que esta persona vencera a sus enimigos
totalmente, tendra buena vida y sus caminos abriran. Ifa dice que llegara a donde sus enimigos no quieren
que llega. Ifa dice que esta persona debe INICIARSE EN IFA URGENTEMENTE y que no debe demorarse
en iniciarse en Ifa. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Irẹtẹ-Otura. (Irẹtẹ-Otura)
Kiku o ma baa pa a. (Que la muerte no le mata)
Irẹtẹ-Otura. (Irẹtẹ-Otura)
Kiku o ma baa pawo. (Que la muerte no mata a Awo)
Irẹtẹ-Otura. (Irẹtẹ-Otura)
Kiku o ma baa ponisegun. (Que la muerte no mata a la hierbalista)
Irẹtẹ-Otura o. (Irẹtẹ-Otura)
Kiku o ma baa pawo. (Que la muerte no mata a Awo)
Irẹtẹ-Otura. (Irẹtẹ-Otura)
Kiku o ma baa ponisegun (Que la muerte no mata a la hierbalista).
Iku pọlọba, o s’Ọba Ejio kanrin-kanrin. (La muerte mato al Rey Ejio kanrin-kanrin)
Iku porigidi ọmọ Orisa. (Que la muerte mato a Origidi el hijo de Orisa)
Iku pa Eji-Okoko Agbebi-pọn wọla. (La muerte mato a Eji-Okoko Agbebi-pọn wọla)
Afẹfẹ ọwọ ọtun, nsewe-agbọn riyẹ-riyẹ. (Las brisas de la mano derecha movia las hojas del
cocotero para aca y para alla)
Afẹfẹ ọwọ osi, nsewe-agbọn riyẹ-riyẹ. . (Las brisas de la mano izquierda movia las hojas del
cocotero para aca y para alla)
A dia fun Ọrunmila, Bara Agbọnmiregun. (Se adivino Ifa para Ọrunmila, Bara Agbọnmiregun)
Nijọ ti nlọ ree tẹku nifa. (El dia que iba a iniciar la muerte en Ifa)
Ti yoo si f’Ago sotumọna rẹ. (Que iba a poner Ago “La aula tradicional para
gallina” como su guia)
Iku tii ba pawo, ko bawo. (La muerte que iba a matar al awo, no encontro a
Awo)
Ago lafi deku mọlẹ; Ago. (Hemos tapado la muerte al suelo con Ago “La aula
tradicional para gallina”)
Arun tii ba sawo, ko bawo. (La enfermedad que iba enferma ai awo, no
encuentra al awo)
Ago lafi darun mọlẹ; Ago. (Hemos tapado a la enfermedad al suelo con Ago “La
aula tradicional para gallina”)
Ofo tii ba sawo, ko bawo. (La pedida que iba a pasar a Awo, no encuentra a
Awo)
Ago lafi dofo mọlẹ; Ago. (Hemos tapado a la pedida al suelo con Ago “La aula
tradicional para gallina”)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Keleyii FAGO ADIẸ KAN kun ẹbọ ru nibẹ. Ifa niku yi koni peleyii mọ.
Teleyii koba mura, ko TETE setutu, iku yoo peleyii mọbẹ. Teleyii koba lowo lọwọ lati TẸFA, Keleyii kesi
awon babalawo kiwon baa BỌFA nibẹ. Inu ago yii niwon yoo setutu rẹ si, tiwon yoo gbee sibi tifa bani
kiwọn o gbee si, tiku ko fini peleyii mọ, tẹmi rẹ yoo fi gun, leleyii yoo fi se gbogbo ohun toyẹ ki eniyan se
laiye loju Irẹtẹ-Otura.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacri ficio. Ifa dice que debe tener UNA AULA
TRADICIONAL DE GALLINA en su sacrificio. Ifa dice que la muerte no va a matar a esta persona. Si esta
persona hace el sacrificio URGENTEMENTE, la muerte le matara. Si esta persona no tiene dinero para
iniciarse en Ifa, que debe llamar a los babalawos para que le ayudan DAR DE COMER A IFA. Las cosa de su
sacrificio se pone dentro de la aula tradicional para gallina y se lleva a donde Ifa determina que se lleva el
sacrificio, para que la muerte no mata a esta persona, para que esta persona tenga larga vida y para que esta
persona cumple con todos lo que tenia que hacer en esta vida en el signo de Irẹtẹ-Otura.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Investigasr el vencimiento de los enimigos)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kawọn ọta lee jẹ keleyii saseyọri. Kawọn babalawo beleyii jewe Ifa nitori ẹmi
gungun nibẹ. Ifa laarin ọta leleyii wa, Ifa leleyii gbọdọ rubọ nibẹ, kiwọn lee jẹ keleyii saseyọri. Lẹyin igba
teleyii ba rubọ tan, ko sunmọ awọn babalawo kiwọn beleyii jewe Ifa nibẹ. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa
na sọ pe:
Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que sus enimigos le dejan prosperar. Que los
babalawos le preparan las hierbas de Ifa para tener la larga vida. Ifa dice que esta persona esta en el medio
de los enimigos. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que le dejan prosperar. Despues de
hacer el sacrificio, debe acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa. Ifa lo dice asi con
este verso; QUE:

Irẹtẹ-Otura awo aiye. (Irete-Otura era el awo del mundo)


O tẹku mọlẹ, o yan fahunda-fahunda. (Piso la muerte al suelo y se iba andando con las
elegancias)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ tọmọ araiye yoo ma roku ro o. (El dia que las gentes del mundo estaban deseandole
la muerte)
Won ni ko sẹbo, kole ba a rere aiye jẹ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio para que puede
disfrutar de los beneficios de su vida)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Baba sẹgun iku o, ko kumọ. (El padre vencio la muerte y no murio)
Oju wa tasebi. (Los maldinos se quedaron en verigueza)
Iku wa pọdalẹ. (La muerte mato a los traidores)

Wọn ni k’Ọrunmila o tete rubọ, kiku ma baa pa a. Ọrunmila o pawo leke. O mu tẹbọ se, o sise gbogbo ohun
tawọn babalawo ni kose. Bayi ni Ọrunmila se sẹgun awọn ọta rẹ. Ọrunmila sẹgun gbogbo awọn tiwọn njẹ,
tiwọn nmu lọdọ Ọrunmila, tiwọn wa nb’Ọrunmila sọta. Biku se npawọn ọta Ọrunmila niyi, tifa npawọn jẹ,
tifa npawọn ọdalẹ. Ni Ọrunmila ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ
gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Dijieron a Ọrunmila que debe hacer el sacrificio para que la muerte no le mata. Ọrunmila no llamo
a Awo mentiroso. Hizo el sacrificio y todos los demas que le mandaron a hacer los babalawos.
Ọrunmila vencio a todos sus enimigos. Ọrunmila vencio a todos los que comian y bebian con el y
que le estan haciendos enimigos. La muerte mato a todos los enimigos de Ọrunmila, Ifa mato a
todos ellos, Ifa mato a los traidores. Ọrunmila estaba feliz, empezo a bailar y cantar, que asi mismo
lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Irẹtẹ-Otura awo aiye. (Irete-Otura era el awo del mundo)


O tẹku mọlẹ, o yan fahunda-fahunda. (Piso la muerte al suelo y se iba andando con
elegancia)
A dia fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba nbẹ laarin ọta. (El dia que el padre estaba en el medio de
enimigos)
Ẹbọ niwọn niki baba o se. (Dijieron al padre que debe hacer el sacrificio)
O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Baba wa tẹku mọlẹ, baba o kumọ. (El padre piso la muerte al suelo y no murio)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ (Despues de todos)
Oju wa tasebi. (Los maldinos se quedaron en verigueza)
Iku wa pọdalẹ. (La muerte mato a los traidores)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ifa wa bani laarin iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio del
vencimiento)
Aarin iṣẹgun, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los
pies del Rey de los Orisas)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa lẹnikan ni ndalẹ eleyii. Ifa ni teleyii bati rubọ, Ifa niku ti setan ti yoo
pẹniti ndalẹ eleyii loju Irẹtẹ-Otura.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que hay una persona que esta
traicionando a esta persona. Ifa dice que si esta persona hace el sacrificio, que la muerte esra preparado
para matar a esa persona que esta traicionanadole en el signo de Irẹtẹ-Otura.

14.15. IRU-ẸKUN. (IRẸTẸ-ỌSẸ)

ẸSẸ KINNI.

Ire aje. (Bendicion de dinero)

Iru-Ẹkun ni a npeni Irẹtẹ-Ọsẹ, ohun naa latun npeni “irẹtẹ nsaje”. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kiwọn ma baa
dina aje meleyii. Ifa ni koni IGBIN KAN lẹbọ nibe, koni IYERE lẹbọ nibẹ, kawọn babalawo baa jewe ifa,
kiwọn baa serubọ. Ifa lọna aje yoo si feleyii.
Igbin yi niwọn yoo fi sasejẹ feleyii. Ewe kan nbẹ loko ti njẹ EWE AMUYAN, a o lọ ewe amuyan yii, a o se
mọgbin yii, a o muyere-osun ẹbọ, lẹyin igba tiwọn bati sẹbọ tan, a o tẹẹ ni “irẹtẹ nsaje”, a o daa pọ mọbẹ
asejẹ yii, eleyii yoo jọbẹ asejẹ yi. Ifa leleyii yoo ri taje se. Eleyii yoo ma rowo, ọna yoo la feleyii.
Tawọn eniyan bani awọn koni dọdọ eleyii sawo mọ, teleyii bati jasejẹ yi, wọn yoo ma dọdọ rẹ se nkan. Wọn
yoo ma beleyii nisẹ, ọna yoo si feleyii, eleyii yoo ma ri taje se. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ibi tifa wa gba tofi sọ
bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Iru-Ẹkun es lo que llamamos Irẹtẹ-Ọsẹ, tambien se llama “Irẹtẹ nsaje” (Irẹtẹ esta haciendo dinero). Ifa dice
que esta persona debe hacer el sacrificio para que no le bloquiar su bendicion de dinero. Ifa dice que esta
persona debe tener UN CARACOL en su sacrificio, debe tener IYERE en su sacrificio, que los babalawos le
preparan las hierbas de Ifa y hacer el sacrificio. Ifa dice que el camino de bendicion de dinero abrira para
esta persona.
Con el caracol, se hace una salsa para que lo come esta persona. Se muele la HIERBA DE AMUYAN y se
cocina con el caracol para hacer la salsa, se coge el iyere-osun del sacrificio, se imprime el signo de “Irẹtẹ
nsaje” y se hecha en la salsa, la entregan a esta persona para comer la salsa. Ifa dice que esta persona
conseguira medios economicos. Ifa dice que esta persona conseguira dinero y los caminos le abriran.
Si las gentes decian que no iban a ir a su casa para hacer los trabajos de awo, si esta persona come la salsa
de caracol, todos ellos van a volver a la casa de esta persona a hacer el trabajo de awo. Van a buscarle para
hacer el trabajo de awo, los caminos abriran para esta persona, conseguira dinero. Ifa dice que esta persona
debe hacer el sacrificio. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Olugbọn se Olu (Olugbọn fue preferido)


Arẹsa se Olu. (Arẹsa fue preferido)
Solu nsolu lobinrin ngbaale fun. (Preferido o no preferido, por eso la mujer acepta a otro
hombre extral-matrimonial)
A dia fun Olukọtun Ẹyingeedee. (Se adivino ifa para Olukọtun Ẹyingeedee)
Nijọ tiwọn lawọn koni dọdọ rẹ sawo mọ. (El dia que dijieron que no iban a ir a su casa a hacer el
trabajo de Awo)
Ẹbọ niwọn ni o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de
Ifa)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Olukọtun wa donire gbogbo. (Olukotun se convertio en alguien con todas las
bendiciones)
Ọlọkunrin, olobinrin to basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Hombres y mujeres que decian que no
iban a venir a me a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹ-gẹrẹ, lawọn iyami osoronga o ma wọwọn wa o, gẹrẹ-gẹrẹ. (Directamente, mi madre “osoronga” va a
traer a ellos a me, directamente)
Ọlọkunrin, olobinrin to basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Hombres y mujeres que decian que no
iban a venir a me a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹ-gẹrẹ, lawọn iyami osoronga o ma wọwọn wa o, gẹrẹ-gẹrẹ. (Directamente, mi madre “osoronga” va a
traer a ellos a me, directamente)
Kiti niyere sowo tirẹ lara igi oko. (En bruto y rapidamente el iyere hace su
dinero entre los arboles del campo)
Nijọ tigbin ba dẹnu delẹ, nii jẹfa ilẹ. (El mismo dia que el caracol pone su
boca al suelo, disfruta de los beneficios del suelo)
Ọrunmila dakun dabọ jẹ un rifa aje jẹ. (Ọrunmila por favor, dejame disfrutar
de los benficios de la bendicion del dinero)

Gbogbo awọn eniyan n ditẹ Ọrunmila, wọn ni awọn koni dọdọ Ọrunmila se awo mọ. Ọrunmila ko sọrọ.
Niwọn ko ba wa mọ nitotọ. Nijọ kan, ni Ọrunmila ba dafa. Ifa niki Ọrunmila o rubọ, ki Ọrunmila fi IGBIN
kun ẹbọ ru, o jewe ifa, gbogbo ohun tiwọn niki Ọrunmila se, gbogbo nkan yi ni Ọrunmila se. Nigba ti
Ọrunmila ti rubọ, tẹbọ rẹ fin. Ọrunmila ni gbogbo awọn tiwọn ni awọn koni dọdọ oun se awo mọ, Ọrunmila
ni ifa ni yoo ma wọ wọn wa. Bayi nifa se n wọ gbogbo wọn wa. Ọrunmila ba n jo, o n yọ, o n yin awọn
Awo rẹ, awọn awo rẹ si n yin Ifa, o ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn Awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn Awo toun sọ:

Todas las gentes conspiraron que no iban a ir mas a la casa de Ọrunmila para hacer los trabajo de
Awo. Ọrunmila no dijo nada. Las gentes dejaron de ir a la casa de Ọrunmila para hacer los trabajos
de Awo. Un dia, Ọrunmila consulto a Ifa, Ifa le dijo a Ọrunmila que debe hacer el sacrificio, que
Ọrunmila debe tener CARACOL en su sacrificio y todos los demas cosas que le mandaron a hacer.
Cuando el sacrificio de Ọrunmila se levanto y se acepto. Ọrunmila dijo que: “Todos los que decian
que no iban a venir su casa a hacer el trabajo de Awo, directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente”, Todos ellos empezaron a venir a la casa de Ọrunmila para pedirle el trabajo de Awo.
Ọrunmila estaba feliz, empezo a bailar y cantar, que asi mismo lo han adivinados y cantados sus
awos; QUE:

Olugbọn se Olu (Olugbọn fue preferido)


Arẹsa se Olu. (Arẹsa fue preferido)
Solu nsolu lobinrin ngbaale fun. (Preferido o no preferido, por eso la mujer acepta a otro
hombre extral-matrimonial)
A dia fun Olukọtun Ẹyingeedee. (Se adivino ifa para Olukọtun Ẹyingeedee)
Nijọ tiwọn lawọn koni dọdọ rẹ sawo mọ. (El dia que dijieron que no iban a ir a su casa a hacer el
trabajo de Awo)
Ẹbọ niwọn ni o se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O gbọ riru, o ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)
O gbọ titu, o tu. (Oio el ofrecimiento y ofrecio)
O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, o ha. (Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion de
Ifa)
Asẹyin wa o, asẹyin bọ. (Despues de todos)
Olukọtun wa donire gbogbo. (Olukotun se convertio en alguien con todas las
bendiciones)
Ọlọkunrin, olobinrin to basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Hombres y mujeres que decian que no
iban a venir a me a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹ-gẹrẹ, lawọn iyami osoronga o ma wọwọn wa o, gẹrẹ-gẹrẹ. (Directamente, mi madre “osoronga” va a
traer a ellos a me, directamente)
Ọlọkunrin, olobinrin to basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Hombres y mujeres que decian que no
iban a venir a me a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹ-gẹrẹ, lawọn iyami osoronga o ma wọwọn wa o, gẹrẹ-gẹrẹ. (Directamente, mi madre “osoronga” va a
traer a ellos a me, directamente)
Kiti niyere sowo tirẹ lara igi oko. (En bruto y rapidamente el iyere hace su
dinero entre los arboles del campo)
Nijọ tigbin ba dẹnu delẹ, nii jẹfa ilẹ. (El mismo dia que el caracol pone su
boca al suelo, disfruta de los beneficios del suelo)
Ọrunmila dakun dabọ jẹ un rifa aje jẹ. (Ọrunmila por favor, dejame disfrutar
de los benficios de la bendicion del dinero)
Ko pẹ o, ko jinna. (Pronto y no tan lejano)
Ifa wa bani nijẹbutu ire. (Ifa ven a encontranos en la
celebracion de bendicion)
Ijẹbutu ire laa nbani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de la bendicion se
encuentra uno a los pies del Rey de los Orisas)

Ọrunmila nse: ORIN. (CANCION)

Ọlọkunrin, olobinrin to basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Hombres y mujeres que decian que no iban a
venir a me a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ. (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)
Olobinrin lo basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Mujeres que decian que no iban a venir a
pedirme a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)
Ọlọkunrin lo basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ (Hombres que decian que no iban a venir a
me a pedirme a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)
Ọmọde lo basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Jovenes que decian que no iban a venir a me
a pedirme a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ. (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)
Agbalagba lo basọ pawọn o ni dọdọ mi sawo mọ. (Mayores que decian que no iban a venir a
me a pedirme a hacer el trabajo de Awo)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)
Kiti niyere sowo tirẹ lara igi oko. (En bruto y rapidamente el iyere hace su
dinero entre los arboles del campo)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)
Nijọ tigbin ba dẹnu delẹ, nii jẹfa ilẹ. (El mismo dia que el caracol pone su boca al
suelo, disfruta de los beneficios del suelo)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)
Ọrunmila dakun dabọ jeun rifa aje jẹ. (Orunmila por favor, dejame disfrutar de
los benficios de bendicion de dinero)
Gẹrẹrẹ, Ifa ma wọwọn bọ, gẹrẹrẹ (Directamente, Ifa va a traer a ellos a me,
directamente)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni koni IGBIN KAN lebọ nibẹ, koni IYERE lẹbọ nibẹ Ifa ni keleyii o
rubọ, lẹyin igba tiwọn bati sẹbọ tan, a o lọ EWE AMUYAN yii, a o se mọgbin yii, a o tẹẹ ni “irẹtẹ nsaje”, a o
daa pọ mọbẹ asejẹ yii, a o kọrin ti Ọrunmila kọ yi sọbẹ yii, eleyii yoo jọbẹ asejẹ yi. Ifa lọna yoo si feleyii.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que debe tener UN CARACOL en su
sacrificio, que debe tener IYERE en su sacrificio, despues de hacer el sacrificio, Se muele la HIERBA DE
AMUYAN y se cocina con el caracol para hacer la salsa, se coge el iyere-osun del sacrificio, se imprime el
signo de “irete n saje” y se hecha en la salsa, se canta la cancion de Ọrunmila a la salsa, esta persona comera
la salsa. Ifa dice que los camino de bendiciones de esta persona abriran.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo

Tifa bagbin. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kesu o ma baa bagbesi aiye rẹ jẹ. Esu lee dina lati majẹ keleyii maa
rire gba. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kesu ma dina meleyii, kole ma rire gba, kole lowo lọwọ. Keleyii sunmọ
awọn babalawo, kiwọn beleyii jewe Ifa nibẹ. Ifa leleyii ma sẹgun ọta. Ifa lọna eleyii ma la. Ibi tifa wa gba tofi
sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Si Ifa dice que no. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que esu no hace que se hecha a
peder su vida. Esu puede bloquiar el camino de esta persona para que no le llegan las bendiciones. Ifa dice
que debe hacer el sacrificio, para que esu no le bloquiar en su camino, para que puede recibir las
bendiciones, para que puede tener dinero. Debe acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas
de Ifa. Ifa dice que esta persona vencera a sus enimigos. Ifa dice que el camino de esta persona abrira. Ifa lo
dice asi con este verso; QUE:
Iru-Ẹkun ọmọ alade. (Iru-Ẹkun, hijo de la corona)
O ro gogogo sọ agba niko. (Se puso bestial para dar cogotazo a la persona mayor)
Ẹiyẹ raki-raki ode ọrun. (El pajaro negro del cielo)
Awodi Oosa, ti ngboke yọfun alakọni jẹ. (Awodi Oosa que vive arriba para comer los intestinos de
los guerreros)
A difa fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba o tẹkun nifa. (El dia que el padre iba a iniciar a Ẹkun en Ifa)
Tosi gbagbara lẹkun lọwọ. (Y que iba a entregar el poder a Ẹkun)
Wọn ni kẹkun mu tẹbọ se. (Dijieron que el Ẹkun debe hacer el sacrificio)
Kole saseyọri nibi tiwọn bati ntẹẹ nifa. (Para que puede prosperar en su iniciacion en Ifa)
Ẹkun si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Ẹkun hizo el sacrificio)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹyin o ri bi baba sewa sẹkun dalagbara. (Ustedes no han vistos como el padre ha convertido a
Ẹkun en alguien de poder)

Ẹkun loun fẹ tẹfa lọdọ Ọrunmila, wipe gbogbo iyanjẹ yi ti pọju. Ẹkun ni ko yeun, bawọn ẹgbẹ oun se nsoun
yii, wipe ọgbọn wo loun fẹ da. Ọrunmila ni; nigba tiwọn ti dafa fun-un yi, wipe ko TẸFA, wipe ẹbọ tẹkun
yoo ru fesu ni wipe, nijọ tẹkun yoo ba tẹfa, kesu ma dẹkun lọna. Orunmila ni tẹkun bati rubọ fesu, yoo lee
saseyọri, sugbọn tiko ba rubọ fesu, koni saseyọri.
Ẹkun loun yoo rubọ fesu, wipe se toun bati rubọ, oun yoo lagbara, tawọn eniyan koni ma yan oun jẹ mọ.
Ọrunmila ni yoo lagbara. Ọrunmila ka gbogbo ohun tẹkun yoo fi tẹfa fun-un. Ẹkun bawa gbogbo nkan yi
patapata.
Ọrunmila ba tẹkun nifa. Bagbara sede fẹkun niyi, lo badi wipe ẹni to bati yọju sẹkun, seni ẹkun yoo
konitoun mọlẹ, ti yoo faa ya bayi. Bẹkun se sẹgun niyi. Ẹkun ni a se bayi laiye ri. A se bayi laiye mọ se. Ero
Opo, ero Ọffa. Ẹyin o rii bi baba sewa sẹkun dalagbara. Ni ẹkun ba njo, o nyọ, o nyin awọn awo rẹ, awọn
awo rẹ si nyin Ifa; O ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ:

Ẹkun queria iniciarse en Ifa con Ọrunmila, porque los demas de sus companeros le estaban enganandos.
Ẹkun dijo que no entendia porque los demas de sus companeros le estaban enganandos y queria saber lo
que podia hacer. Ọrunmila le dijo que, ya que le han consultado que debia INICIARSE EN IFA, debe hacer
el sacrificio para el esu, para que el esu no le bloquiar el camino en el dia de su iniciacion en Ifa. Ọrunmila
dijo que prosperara si hace el sacrificio para el esu, pero si no hace el sacrificio para el esu, que no iba a
prosperar.
Ẹkun dijo que iba a hacer el sacrificio para el esu. Ẹkun dijo que si hace el sacrificio para el esu se convertira
en alguien de poder y que sus companeros no van a poder enganarle mas. Orunmila le dijo que iba a
convertirse a alguien de poder. Ọrunmila le dijo todos lo que debia tener para su iniciacion en Ifa. Ẹkun
busco todos lo que Ọrunmila le mando a buscar para su iniciacion en Ifa.
Ọrunmila inicio al ẹkun en Ifa. Asi fue como ẹkun se convertio en alguien de poder, cualquier persona que
se enfrenta al ẹkun. Ẹkun le atrapa y le mata. Asi fue como el ẹkun vencio. Ẹkun estaba soprendido que el
mundo era asi. Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa. Ustedes no han vistos como el padre ha convertido al
ẹkun en alguien de poder. Ẹkun estaba feliz, empezo a bailar y cantar; Que asi mismo lo han
adivinados y cantados sus awos; QUE:
Iru-Ẹkun ọmọ alade. (Iru-Ẹkun, hijo de la corona)
O ro gogogo sọ agba niko. (Se puso bestial para dar cogotazo a la persona mayor)
Ẹiyẹ raki-raki ode ọrun. (El pajaro negro del cielo)
Awodi Oosa, ti ngboke yọfun alakọni jẹ. (Awodi Oosa que vive arriba para comer los intestinos de
los guerreros)
A difa fun Ọrunmila. (Se adivino Ifa para Ọrunmila)
Nijọ ti baba o tẹkun nifa. (El dia que el padre iba a iniciar a Ẹkun en Ifa)
Tosi gbagbara lẹkun lọwọ. (Y que iba a entregar el poder a Ẹkun)
Wọn ni kẹkun mu tẹbọ se. (Dijieron que el Ẹkun debe hacer el sacrificio)
Kole saseyọri nibi tiwọn bati ntẹẹ nifa. (Para que puede prosperar en su iniciacion en Ifa)
Ẹkun si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Ẹkun hizo el sacrificio)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹyin o ri bi baba sewa sẹkun dalagbara. (Ustedes no han vistos como el padre ha convertido a
Ẹkun en alguien de poder)
Ko pẹ o, ko jinna. (Pronto y no tan lejano)
Ifa wa bani laarin iṣẹgun. (Ifa ven a encontranos en el medio del vencimiento)
Aarin iṣẹgun, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio del vencimiento se encuentra uno a los pies
del Rey de los Orisas)

O nse: ORIN. (CANCION)

Ẹyin o ri bi baba sewa sẹkun dalagbara. (Ustedes no han vistos como el padre ha convertido a
Ẹkun en alguien de poder)
Ẹyin o ri bi baba sewa sẹkun dalagbara. (Ustedes no han vistos como el padre ha convertido a
Ẹkun en alguien de poder)
Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)
Ẹyin o ri bi baba sewa sẹkun dalagbara. (Ustedes no han vistos como el padre ha convertido a
Ẹkun en alguien de poder)

ASẸ-IFÁ:- Bagbara sede sẹkun niyi. Ifa ni keleyii o rubọ. Ifa laarin ọta leleyii wa. Ifa ni keleyii lọ TẸFA nibẹ
ni. Ifa leleyii yoo sẹgun ọta, ti yoo dọba le gbogbo awọn tiwọn ndeleyii laamu.

ASẸ-IFÁ:- Asi fue como el Ẹkun se convertio en alguien de poder. Ifa dice que esta persona debe hacer el
sacrifio. Ifa dice que esta persona esta en el medio de los enimigos. Ifa dice que esta persona debe
INICIARSE EN IFA. Ifa dice que esta persona vencera a sus enimigos y se convertira en el rey sobre todos
los que estan causandole problemas.
14.16. Irẹtẹ-Afin. (Irẹtẹ-Ọfun)

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Awọn aiye) (Investigar el vencimiento de los enimigos “Brujos/as”)

Irẹtẹ-Ọfun ni njẹ Irẹtẹ-Afin. Ifa leleyii fẹ se nkankan, Ifa ni teleyii koba rubọ si nkan yii dada, Ifa niwọn koni
jẹ keleyii se nkan yi loju Irẹtẹ-Afin. Awọn aiye yoo dina meleyii, wọn yoo ma binu eleyii loju irẹtẹ-Ọfun. Ifa
ni teleyii bati rubọ, ọna yoo si feleyii. Keleyii si sunmọ awọn babalawo, kiwọn jewe Ifa fun-un. Loju Irẹtẹ-
Afin, wọn koni jẹ keleyii se nkan naa o. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Irẹtẹ -Ofun es lo que llamamos Irẹtẹ-Afin. Ifa dice que esta persona quiere hacer algo. Ifa dice que si esta
persona no hace el sacrificio muy bien a lo que quiere hacer, Ifa dice que no van a dejarle hacer lo que
quiere hacer en el signo de Irẹtẹ-Afin. Los brujos/as van a bloquiar el camino de esta persona y van a estar
enfadados con esta persona en el signo de Irẹtẹ-Ọfun. Ifa dice que si esta persona hace el sacrificio, su
camino abrira. Debe acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa. En el signo de Irẹtẹ-
Ọfun, no van a dejar a esta persona hacer lo que quiere hacer. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

O jẹ kokoro tan, sun kọlọbọ. (Termino de comer insectos y se quedo dormido


profundamente)
A difa fun Abuke-Ira. (Se adivino Ifa para el Abuke-Ira)
Ti nlọ ree bawọn mulẹ budo. (Que iba establecerse con ellos en la aldea)
Wọn ni ko rubọ. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)
O kọti aigbọ sẹbọ. (Se nego en hacer el sacrificio)
Ko tete rubọ. (No hizo el sacrificio pronto)
Ni awọn ọta ba dii lọna. (Los enimigos le bloquiaron en su camino)
Niwọn ba nsọ fun-un pe, (Le estaban diciendo que:)
Tiko ba rubọ, ọna rẹ koni la. (Si no hace el sacrificio, su camino no abrira)
Bayi niwọn wa ji diri. (Le hicieron arepentirse enseguida)
Tosi wa ounjẹ fesu. (Dio de comer al esu)
Nigba tesu jẹun tan. (Cuando el esu termino de comer)
Lowa bọ sode loru ọjọ kan. (Esu salio fuera un dia por la madrugada)

Esu niyi, o jẹ kokoro tan, sun kọlọbọ ni. Abuke-Ira nlọ sibikan lati lọ se nkankan. Awọn babalawo si tisọ
fabuke-Ira wipe ibi to nlọ yii, o fẹ lọse nkankan ni o, wipe kio rubọ koto lọ o, wipe tiko ba rubọ, Esu koni jẹ
kolọ. Abuke-Ira koti aigbọ sẹbọ. O pawo leke. O pesu lole. O wọrun yanyanyan bi ẹnipe ilẹ koni su mọ. Ni
Abuke-Ira ba kori sibi to nlọ. Nigbati Abuke-Ira nlọ, biwọn se dabuke-Ira lọna niyi, niwọn badi abuke-Ira
loju, niko ba mọna bi yoo tise lọ mọ. Wọn ba dọna ru mabuke-Ira loju. Abuke-Ira ni bawo loun yoo ti sọran
yi. Gbogbo nkan tabuke-Ira fẹ se wa nilẹ, o fẹ kọle, o fẹ niyawo, o fẹ bimọ kile rẹ dun, koma nire gbogbo.
Sugbọn ọna isẹ tabuke-Ira yoo tima rowo, wọn ti dina ibẹ, wọn kojẹ kole lọ sibẹ. Tabuke-Ira koba rowo, kole
kọle, kole niyawo, kole bimọ. Bayi niwọn se gbẹsẹ le gbogbo ọna Abuke-Ira. Abuke-Ira ni bawo loun se fẹ
sọrọ igbesi aiye oun, wipe ọrọ yi ko yeun mọ. Ni Abuke-Ira ba niran wipe koun pada sibi tiwon ti dafa fun-
un. Abuke-Ira niran wipe nkan rere toun fẹ se, toun ko bati rubọ, wọn koni jẹ koun se nkan yi, loba pada
soko awo.
Nigba to dọdọ awọn babalawo tiwọn dafa fun-un. Abuke-Ira lọrọ igbesi aiye oun ko yeun mọ. Awọn
babalawo lẹbọ ni kabuke-Ira tete lo ru, ko WA OUNJẸ FESU. Wọn koni jẹ kọna rẹ o la. Esu ti gbẹsẹ lere aje
rẹ, wọn koni jẹ ko kọle debi wipe yoo niyawo, tabi ko bimọ.
Kiakia ni Abuke-Ira ti rubọ, o WA OUNJẸ FUN ESU. Esu ti jẹun. Esu ti yo bamu-bamu. Ni Esu ba bọ sode,
nigba to jẹun tan. Esu toti gbẹsẹ le kadara Abuke-Ira tẹlẹ, ni Esu ba bọ sode, nigba to jẹun yo tan. Ni Esu ba
nkọrin kakiri wipe:

Esu termino de comer insectos y se quedo dormido profundamente. Abuke-Ira iba a un sitio para hacer
algo. Los babalawos ya le habian dichos al Abuke-Ira que queria ir a un sitio para hacer algo, le dijieron que
debe hacer el sacrificio antes de irse. Le dijieron que si no hace el sacrificio, dijieron que el esu no va a
dejarle ir a donde quieria ir. Abuke-Ira se nego en hacer el sacrificio. Llamo al awo mentiroso. Llamo al esu
ladron. Miro el cielo tan brillante como que no iba a hacer de noche. Abuke-Ira se iba a donde queria ir.
Cuando Abuke-Ira se iba en el camino, le bloquiaron en el camino, le taparon la vista. Abuke-Ira ya no sabia
por donde iba, le confundieron del camino. Abuke-Ira penso como iba a solucionar el asunto. Todos lo que
Abuke-Ira queria hacer se quedaron pedientes. Abuke-Ira queria edificar casa, queria tener esposa, queria
tener hijos para que su casa sea felices y queria tener todas las bendiciones.
Pero ya bloquiaron el camino del trabajo de Abuke-Ira donde conseguia dinero, no le dejaron ir a su trabajo.
Si Abuke-Ira no consigue dinero en su trabajo, no podia edificarse la casa, no podia tener la esposa y no
podia tener hijos. Pisaron y bloquiaron todos los caminos del Abuke-Ira. . Abuke-Ira penso como iba a
solucionar el asunto, por que no entendia lo que le estaba pasando. Le vino a la memoria al Abuke-Ira que
debia volver a donde le han consultado, ya que le habian dichos que debe hacer el sacrificio antes de irse. Le
dijieron que si no hace el sacrificio, dijieron que el esu no va a dejarle ir a donde quieria para conseguir las
bendiones.
Cuando Abuke-Ira llego a donde estaban los babalawos que le consultaron Ifa, dijo que no entendia lo que
estaba pasando en su vida. Los babalawos dijieron al Abuke-Ira que debe hacer el sacrificio urgentemente y
que debe DAR DE COMER A ESU. Dijieron que no van a dejar que se abren sus caminos de conseguir
dinero. Le dijieron que el esu ha pisado y ha bloquiado su camino de conseguir dinero, que no van a dejarle
edificar casa, ni tener esposa, ni tener hijo.
Abuke-Ira hizo el sacrificio enseguida, DIO DE COMER A ESU. Esu comio y estaba lleno. Esu salio fuera
despues de comer. Esu que ha pisado y bloquiado el destino de Abuke-Ira, salio fuera y empezo a cantar por
alli que:

O nse: ORIN. (CANCION)

Ẹ jabuke o kọle. (Ustedes dejan que Abuke-Ira edifica casa)


Ẹ jabuke o ralẹ. (Ustedes dejan que Abuke-Ira compra terreno)
Ẹ jabuke o nire gbogbo. (Ustedes dejan que Abuke-Ira tenga todas las benciones)

Orin tesu nkọ tẹlẹtẹlẹ ni wipe: (La cancion que estaba cantando Esu anteriormente era que:)

O nse:- ORIN. (CANCION)

Abuke o lee kọle. (Abuke no podia edifica casa)


Abuke o lee ralẹ (Abuke no podia compra terreno)
Abuke o lee laya. (Abuke no podia tener esposa)
Abuke o lee bimọ. (Abuke no podia tener hijos)
Abuke o lee nire gbogbo. (Abuke no podia tener todas las bendiciones)

Nigba tesu jẹun tan, tesu wa yo bamu-bamu. Esu wa nkọrin wipe:

Cuando esu termino de comer y estaba lleno de comida, Esu empezo a cantar que:

O nse: ORIN. (CANCION)

Abuke o kọle. (Abuke no edifica casa)


Abuke o ralẹ. (Abuke no compra terreno)
Abuke o lowo. (Abuke no tenia dinero)
Abuke o lohun gbogbo. (Abuke no tenia todas las cosas)
Abuke o nire gbogbo. (Abuke no tenia todas las bendiciones)
Inu ọta wa ndun. (Lo enimigos estaban felices)
Abuke ti kọle. (Abuke ya edifico casa)
Abuke ti ralẹ. (Abuke ya compro terreno)
Abuke ti lowo. (Abuke ya tenia dinero)
Abuke ti laya. (Abuke ya tenia esposa)
Abuke ti bimọ. (Abuke ya tenia hijos)
Abuke ti nire gbogbo. (Abuke ya tenia todas las bendiciones)
Inu ọta wa nbajẹ o. (Los enimigos estaban infelices)

ASẸ-IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, ko WA OUNJẸ FESU. Ifa ni nkan teleyii fẹ seyi, Ifa leleyii yoo saseyọri
nibẹ. Tinu gbogbo awọn ọta eleyii yoo wa ma bajẹ, wipe agbara awọn ko keleyii mọ. Ifa ni keleyii lọ rubọ
nibẹ. Ifa leleyii yoo sẹgun.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y que debe DAR DE COMER AL ESU. Ifa dice
que esta persona prosperara en lo que quiere hacer. Ifa dice que todos los enimigos de esta persona seran
infelices porque no han podido contra esta persona. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa
dice que esta persona vencera.
ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo igbẹyin. (Investigar el despues se las situaciones)

Ifa leleyii fẹ se nkankan, tabi eleyii nse nkan yi lọwọ. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kẹyin nkan yi lee dara feleyii.
Ifa leleyii fẹ se nkankan, tabi eleyii nse nkan yi lọwọ. Boya eleyii ngbimọran lati kọle ati lati ralẹ. Tabi keleyii
ti ralẹ, kowa ma kọle lelẹ yi lori. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kẹyin nkan yi lee dara feleyii. Boya eleyii fẹ
segbeyawo ni, ko rubọ nibẹ, kẹyin igbeyawo yi lee dara feleyii. Ibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona quiere hacer algo o ya lo esta haciendo. Ifa dice que esta persona debe hacer el
sacrificio, para que el futuro de lo que esta haciendo sea bueno para esta persona. Puede ser que esta
persona esta planiando para edificar casa y comprar terreno. Tambien puede ser que esta persona ha
comprado el terreno y esta edificando la casa sobre el terreno. Ifa dice que esta persona debe hacer el
sacrificio, para que el futuro de lo que esta haciendo sea bueno para esta persona. Puede ser que esta
persona quiere celebrar la boda, Ifa dice que debe hacer el dsacrificio, para el futuro de la boda sea buena
para esta persona. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ka tẹ ẹ, ko fun yinrin-yinrin. (Que lo pisamos y que sapica brillantemente)


A dia fun Iwa. (Se adivino Ifa para Iwa “el caracter”)
Eyiti nsọmọ Yeye Odi (El que era el hijo de Yeye Odi)
Ti koba siwa. (Si no por la caracter “Iwa”)
Tani jẹ s’Odi lore. (!Quien puede hacer bien al Odi!)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kẹyin nkan teleyii fẹ se yi lee dara feleyii. Ifa ni teleyii koba rubọ nibẹ, ẹyin nkan
teleyii fẹ seyi koni dara, idaamu leleyii yoo ba pade nibi nkan yii, eleyii le jẹgbese nibi nkan yi, koni rowo
kankan gba. Nkan yii yoo digbese sẹniyii lọrun ni. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que el futuro de lo que esta haciendo esta persona sea
bueno. Ifa dice que si esta persona no hace el sacrificio, el futuro de lo que quiere hacer no sera bueno para
esta persona, tendra problema en lo que quiere hacer, entrara en deudas en lo que quiere hacer y no le
pagaran en lo que quiere hacer y se convertira en deudas para esta persona; QUE:

Ka tẹ ẹ, ko fun yinrin-yinrin. (Que lo pisamos y que sapica brillantemente)


A dia fun Iwa. (Se adivino Ifa para Iwa “el caracter”)
Eyiti nsọmọ Yeye Odi (El que era el hijo de Yeye Odi)
Ti koba siwa. (Si no por la caracter “Iwa”)
Tani jẹ s’Odi lore. (!Quien puede hacer bien al Odi!)

ASẸ-IFÁ:- Nigba teniyan kose nkan dada tẹlẹ-tele, bawo lonitoun se fẹ ri nkan ire, nigba to nse nkan yi
lọwọ. Ifa yi tun nkọ eniyan lẹkọ wipe, keniyan ma huwa dada, konitoun lee ri nkan rere gba lọjọ teleyii ba
nse nkan rere fararẹ, tabi fọmọ. Ifa ni keleyii ma se dada pẹlu ọmọ nikeji, keleyii lee ri nkan rere gba lọjọ
tire re bade loju Irẹtẹ- Afin, ti a npeni Irẹtẹ-Ọfun.

ASẸ-IFÁ:- Cuando una persona no ha hecho nada buena anteriormente, como esa persona puede recibir
algo bueno cuando esta haciendo o celebrando algo. Ifa nos esta dando leccion que uno debe tener buen
caracter, para que esa persona puede recibir algo bueno en el dia que le toca hacer o celebrar algo. Ifa dice
que esta persona debe comportarse bien con los demas, para que esa persona puede recibir algo bueno en el
dia que le toca hacer o celebrar algo en el signo de Irete-Afin, que tambien se llama Irẹtẹ-Ọfun.

También podría gustarte