Está en la página 1de 77

APOLA IWORI

3·2. ÌWÒRÌ OGBÈ. (Ìworí Bogbè “Iwori tapo a Ogbe”).

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun. (Investigar el vencimiento)

Ifá ni kasọ feleyii wipe nkankan ni nse lọwọ yi. Ọgan kòni torí-rẹ jìn. Ifa leleyii ni FÌLÀ-PUPA KAN ninu ilé, kófi
kun ẹbọ ru nibẹ, kóle báà sẹgun. Ifá leleyii nfa nkankan lọwọ, toba mura sadura, yoo sẹgun, láì ni siwahala
kankan. Ifá ni teleyii bafẹ dùpo kan, kì baa jọba-Ilú ni, Ifá ni wipe yoo wọlé loju Ìwòrì Bogbè. NIbi tifa wa gba
tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona esta haciendo algo hasta ahora, lo que esta haciendo, Ifa le pide que no
termina rompiéndose o estropiandose totalmente en su turno. Ifa dice que esta persona tiene UNA
GORRA O SOMBRERO ROJO en su casa, debe poner la gorra o sombrero en su sacrificio para vencer.
Ifa dice que este consultante esta luchando y intentando conseguir algo, si sigue rezando, vencerá y no
tendra ningún problema en absoluto. Si esta persona quiere presentarse a la oposición, a un cargo,
incluso presentarse para ser el Rey de una ciudad, Ifa dice que lo conseguirá en el signo de Ìwòrì
Bogbè. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ìwòrì bogbè ni jijẹ (Ìwòrì tapo a Ogbè para no dejarle comer)


Ìwòrì bogbè ni mimu. (Ìwòrì tapo a Ogbè para no dejarle beber)

Ìwòrì bogbè mọlẹ. (Ìwòrì tapo a Ogbè al suelo)

Kọmọ Ogbè máà báà kú mọ. (Para que el hijo de Ogbè no se muere jamás)

A difá fun Olukiri-nbítí. (Se adivino Ifa para Olukiri-nbítí)

Eyiti nse Ẹmẹsọ-Èlùjù. (El que era el Ẹmẹsọ-Èlùjù)

Wọn niki Olukiri-nbítí, ti nse Ẹmẹsọ-Èlùjù o rubọ. Wọn lohun ti nfa yi o, ọgan kòni torí-rẹ jìn nibẹ.
Wọn ni kóni FILA-KAN PUPA lẹbọ. Kò pawo leke. Kò pesu lole. O si rubọ nibẹ. Olukiri-nbítí lorukọ ta
npe Ẹmẹsọ-Èlùjù. Ọgan ni njẹ Olukiri-nbítí. Ó rubọ tan, lóba gbà ibẹ ránránrán, ó sẹgun, gbogbo nkan
tawọn mẹwa nfa, si bọsọwọ Ọgan nikan. Awọn awo tun sefá fun-un. Ifá ni keleyii rubọ, wipe nkan tó
nfa yi, agbàgbe ni yoo gbà nkan naa, kòni siwahala kankan nibẹ.

Nigbà tọgan debi tó nlọ, lóba nyin awọn awo to kifá fun-un, kò gbàgbe wọn, ó njo, ó nyọ, lorin awo ba
bọsi lẹnu, wipe: “Opa kuru lode ìsẹri-mogbè”. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni awọn babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni
awọn babalwo tohun sọ:

Dijieron a Olukiri-nbítí que es el Ẹmẹsọ-Ẹlùjù que debe hacer el sacrificio, por lo que esta intentando
lograr o conseguir, para que no termina rompiéndose o estropiandose totalmente en su turno. Dijieron
que debe tener UNA GORRA O SOMBERERO ROJO en su sacriticio. Olukiri-nbítí no llamo a awo
mentiroso. No llamo a esu ladron. Hizo el sacrificio. Olukiri-nbítí es el nombre que llamamos a Ẹmẹsọ-
Ẹlùjù. Es Ọgan “ el termitero” que se llama Olukiri-nbítí. Despues de hacer el sacrificio, conseguio lo
que necesitaba totalmente, venció totalmente. Lo que diez personas estaban intentandos conseguir, lo
conseguio Ọgan solamente. Los awos le prepararon las hierbas de Ifa también. Ifa dice que esta
persona debe hacer el sacrificio. Lo que esta intentando conseguir esta persona, lo conseguirá sin
ningún problema en absoluto.

Cuando Ọgan llego a donde iba, empezó a alabar a los awos que le adivinaron Ifa, no se olivido de los
awos. Ọgan estaba feliz, empezó a bailar, abrió la boca y le salió la canción de awos que: “un baston
bajito en la ciudad de Isẹri-mogbè”. Que asi mismo lo adivinaron y lo cantaron sus babalawos; QUE:

Ìwòrì bogbè ni jijẹ (Ìwòrì tapo a Ogbè para no dejarle comer)


Ìwòrì bogbè ni mimu. (Ìwòrì tapo a Ogbè para no dejarle beber)

Ìwòrì bogbè mọlẹ. (Ìwòrì tapo a Ogbè al suelo)

Kọmọ Ogbè máà báà kú mọ. (Para que el hijo de Ogbè no se muere jamás)

A difá fun Olukiri-nbítí. (Se adivino Ifa para Olukiri-nbítí)

Eyiti nse Ẹmẹsọ-Èlùjù. (El que era el Ẹmẹsọ-Èlùjù)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Le dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ, kò jinna. (Pronto y no tan lejano)

Ẹ wo Ifá Awo kì biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que Awo adivino se hizo
realidad)

Ó n se:- ORIN: (CANCION)

Ẹ wofá awo kì biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad)

Ẹ wofá awo kì biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad)

Kò pẹ, kò jinna. (Pronto y no tan lejano)

Ẹ wofá awo kì biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad)

Ẹ wofá awo kì biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad)

Kò pẹ, kò jinna. (Pronto y no tan lejano)

Ẹ wofá awo kì biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad)

À sé Olukiri-nbítí ti nsẹmẹsọ-ẹlùjù, (¡Es que Olukiri-nbítí es el nombre de Ẹmẹsọ-Ẹlùjù!)

Lorukọ ta npọgan. (Es el nomdre que llamamos a Ọgan.

Kò pẹ, kò jinna. (Pronto y no tan lejano)

Ẹ wofá awo kì biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad)
ASẸ-IFA:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá leleyii yoo sẹgun, tóba tifi FILA PUPA orí-rẹ rubọ nibẹ, sugbọn
tikò bati rubọ nibẹ, nkan yi yoo yi i lọwọ nibẹ o.

ASẸ-IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona vencerá, una vez
que pone su GORRA o SOMBRERO ROJO en su sacrificio. Si esta persona no hace el sacrificio el asunto
le escapara de las manos.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Investigar el vencimiento de enemigo)

Ifá tun nsọ feleyii wipe kó rubọ nibẹ. Ifa ni wipe awọn kan niwọn ndìlègbè meleyii, wọn ndìtẹ meleyii wipe o ku
ibiti yoo gbe gbà. Ifá ni to bati rubọ, yoo sẹgun gbogbo awọn ti npete, tiwọn ngbìmọràn wipe, ibó ni yoo gbe
gbà, wipe awọn yoo konira beleyii, awọn yoo darán seleyii lọrùn, tikò niroju selé-aiye-rẹ mọ, wipe awọn kòni
jẹki ó depo tofẹ de. Ifá ni gbogbo ete tiwọn ndi lorí eleyii, yoo pada sorí gbogbo awọn ọta-rẹ ni, nigbà teleyii ba
sohun tofẹ se. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa le esta diciendo a esta persona que debe hacer el sacrificio. Ifa dice que hay unas gentes que están
deseándole mal, conspirando, planiando contra esta persona y esperandole por donde puede salir este
consultante. Ifa dice que si hace sacrificio, vencerá a todos los que están deseándole mal, los que están
esperandos por donde puede salir esta persona, los que están deseandos meterle problemas, los que
están planeandos que no le van a dejar vivir en paz, los que le van a hacer sufrir y los que no le van a
dejar llograr o conseguir el puesto que quería. Ifa dice que todas estas conspiraciones volverán a caer
encima de sus enemigos, después de que este consultante cumpla sus deseos. Ifa lo dice asi con este
verso; QUE:

Ilẹ nyọ mi ítẹrẹ-ítẹrẹ. (El suelo me revalo)


Ilẹ nyọ mi ìtẹrẹ-ìtẹrẹ. (El suelo me revalo)

Ilẹ to yọ ara iwaju. (E l suelo que revalo a las gentes que iban delante)

Kero ẹyin o kiyèsi. (Los que vienen detrás deben tener cuidados)

A difá fun Ìwòrì; (Se adivino Ifa para Ìwòrì)

To loun o bogbè mọlẹ. (Que quieria tapar a Ogbè al suelo)

Ìwòrì to bogbè mọlẹ lara n ní. (Es Ìwòrì que tapo a Ogbè al suelo que esta sufriendo)

Ara ò ni Ogbè mọ. (Ogbè ya no sufre nada)

Ìwòrì to bogbè mọlẹ lara nní. (Es Ìwòrì que tapo a Ogbè al suelo que esta sufriendo)

Ó nse: ORIN: (CANCION)

Ìwòrì to bogbè mọlẹ lara nní. (Es Ìwòrì que tapo a Ogbè al suelo que esta sufriendo)

Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)

Ìwòrì to bogbè mọlẹ lara nní. (Es Ìwòrì que tapo a Ogbè al suelo que esta sufriendo)

Ara ò ni Ogbè mọ. (Ogbè ya no sufre nada)

Ìwòrì to bogbè mọlẹ lara nní. (Es Ìwòrì que tapo a Ogbè al suelo que esta sufriendo)

ASẸ IFÄ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá ni teleyii bati rubọ, wipe ìnira yoo ba gbogbo awọn tiwọn fẹ
konira beleyii loju Ìwòrì bogbè.

ASẸ IFÄ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que si esta persona hace sacrificio,
que sufrirán todos los que están deseandos y planiandos hacerle sufrir en el signo de Ìwòrì bogbè.
3·3. ÌWÒRÌ ỌYẸKÚ. (Ìwòrì ò ru Ẹku).

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun iku (Investigar el vencimiento de la muerte)

Ifá lawọn ọmọ-mẹrin kan niyi, kiwọn rubọ funwọn, wipe wọn dẹgbẹ waiye ni, kiwọn máà báà dẹgbẹ lọ sode-
ọrún nijọ kanna. Ifá ni kiwọn setutu fun awọn ọmọ-mẹrẹrin, kiwọn maa dagbere file-aiye silẹ nijọ kanna. Ifá
lẹlẹgbẹ-ọmọ niwọn, wọn dẹgbẹ waiye ni, kiwọn máà báà dẹgbẹ pada lọ sọrún loju Ìwòrì-Ọyẹkú. Kiwọn rubọ
dada funwọn, kawọn babalawo si bawọn jewé Ifá funwọn. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe

Ifa dice que hay cuatro niños que deben hacerles sacrificios, porque vienen al mundo de compañeros
celestiales, para que no vuelven al ceielo el mismo dia como compañeros celestiales. Ifa dice que deben
hacerles sacrificios y ofrecimientos a los cuatro niños para que no mueren y volver al cielo sin avisar a
nadie. Ifa dice que vienen al mundo de compañeros celestiales, para que no vuelven al cielo como
compañeros celestiales, deben hacerles sacrificios muy bien y que los babalawos les preparan las
hierbas de Ifa a los cuatro niños. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Èrúkọ ọdẹ ò latẹdá. (Èrúkọ ọdẹ ò latẹdá)

Èrúkọ bàbà ò latẹyá. (Èrúkọ Bàbà ò latẹyá)

Ka gborí agba jà, ka sebi Ọba. (Peliarse siendo mayor o jefe, uno se queda como Rey)

Eyiti nse olorí Elesùkú (Que era el mayor o jefe de Elesùku)

Áyún-áwá ni sọmọ Álárá. (“Áyún-áwá” es el hijo de Álárá)

Kì fẹẹ kù, ni sọmọ Ajerò. (“Kì fẹẹ kù” era el hijo de Ajerò)
Pèté oju ẹ, ni sọmọ Ọràngún Ilé Ìla. (“Pèté oju ẹ” era el hijo de Ọràngún en la ciudad de Ìla)

Sògò-sẹgẹ ni sọmọ Ọrúnmìlà. (“Sògò-sẹgẹ era el hijo de Ọrúnmìlà

Ọjá ni orukọ ìya awọn mẹrẹrin yi. Wọn ni kọjá rubọ nitorí awọn ọmọ-rẹ mẹrẹrin, kiwọn máà báà file
aiye silẹ nijọ kanna, nitoripe ẹlẹgbẹ ọmọ niwọn lode ọrún, kómá báà kabamọ lọjọ alẹ. Ọjá ni, kínní oun
yoo se. Niwọn ba yàn Ọjá lẹbọ. Ó si rubọ. Lawọn ọmọ-rẹ kò ba kú mọ. Wọn ndagbà sii, wọn nse rere.
Ohun ni tọjá na si ndara sii. Bayi ni ó nyin awọn babalawo rẹ, awọn babalawo rẹ si nyin Ifá, poun kòni
gbàgbe awọn babalawo oun. Ó ni, bẹẹ ni awọn babalawo toun wi, bẹẹ ni awọn babalawo toun sọ:

Ọja era el nombre de la madre de estos cuatro hijos. Dijieron a Ọja que debe hacer el sacrificio para sus
cuatro hijos. Para que sus cuatro hijos no dejan el mundo y murirse el mismo dia, por que son
compañeros celestiales desde el cielo y para que Ọja no termina arepentiendose en los últimos días de
su vida. Ọja pregunto por lo que tenia que hacer. La mandaron todos lo que tenia que hacer. Ọja lo
hizo y sus hijos no murieron, se hicieron mayores, tanto Ọja y sus hijos prosperaron. Ọja empezó
alabar a sus Awos y sus Awos alabandos a Ifa. Oja dijo que no iba a olividarse de sus Awos, por que asi
mismo lo han adivinados y cantados sus Awos; QUE:

Èrúkọ ọdẹ ò latẹdá. (Èrúkọ ọdẹ ò latẹdá)

Èrúkọ bàbà ò latẹyá. (Èrúkọ Bàbà ò latẹyá)

Ka gborí agba jà, ka sebi Ọba. (Peliarse siendo mayor o jefe, uno se queda como Rey)

Eyiti nse olorí Elesùkú (Que era el mayor o jefe de Elesùku)

Áyún-áwá ni sọmọ Álárá. (“Áyún-áwá” es el hijo de Álárá)

Kì fẹẹ kù, ni sọmọ Ajerò. (“Kì fẹẹ kù” era el hijo de Ajerò)

Pèté oju ẹ, ni sọmọ Ọràngún Ilé Ìla. (“Pèté oju ẹ” era el hijo de Ọràngún en la ciudad de Ìla)

Sògò-sẹgẹ ni sọmọ Ọrúnmìlà. (“Sògò-sẹgẹ era el hijo de Ọrúnmìlà

Ẹbọ niwọn ni ó se, nitorí wọn. (Dijieron que deben hacer el sacrificios por ellos)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)


Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto, no tan lejano)

Ifá wa bawa larusẹgun. (Ifa ven a ayudarnos en levantamiento y aceptación de nuestro


sacrificio)

Arusẹgun laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En medio de levantamiento y aceptación de sacrificio se
encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

ASẸ IFA:- Ifá lawọn ọmọ mẹrin kan niyi, kiwọn rubọ funwọn. Ifa ni wipe wọn dẹgbẹ waiye ni, kiwọn
máà báà dẹgbẹ lọ sode-ọrún nijọ kanna.

ASẸ IFA:- Ifa dice que hay cuatro niños que deben hacerles sacrificios, porque vienen al mundo de
compañeros celestiales, para que no vuelven al ceielo el mismo dia como compañeros celestiales

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun ọta. (Investigar el vencimiento de enemigos)

Ifá yi tun nkọni lẹkọ nibẹ, ó si nsọ fun onifá yi pe kó rubọ dada o. Ifa nisẹgun wà feleyii. Ifá leleyii nlọ
sibikan. Ifá ni to bati rubọ kóto lọ, wọn yoo jẹki ó debẹ o. Tikò bati rubọ, awọn ajogun-mẹfa nbẹ loju
ọna, tiwọn kòni jẹki ó debẹ loju ìsalaiye, wọn yoo deleyii lọna. Teleyii ba ndu ìpo-kan, Ifá ni kó rubọ, kó
léè báà debi ìpo ti ndù. Tikò ba mura sadura, kawọn babalawo jewé Ifá fun-un, wọn kòni jẹki ó debẹ o.
Wọn yoo ko baa, to jẹpe ègbèsè ni peleyii. Teleyii bafẹ solorí ẹgbẹ-kan ni, kó setutu, kómá báàrí alatakò
nibẹ. Bayi nifá gbà fisọ pawọn ajogun nbẹ loju ọna, tiwọn yoo deleyii lọnà niyi o:
Ifa nos esta educando aqui, Ifa esta diciendo a este consultante que debe hacer el sacrificio muy bien.
Ifa dice que vencerá. Ifa dice que este consultante quiere irse a un sitio. Ifa dice que si este consultante
debe hacer el sacrificio antes de irse, para que le dejan llegar a su destino. Ifa dice que si este
consultante no hace el sacrificio antes de irse, hay seis mal-deseados que le están esperandos para no
dejarle llegar a su destino jamás, cruzaran sus caminos. Ifa dice que si esta persona esta intentando
conseguir un puesto o cargo. Ifa dice que para conseguir ese puesto o cargo debe hacer sacrificio muy
bien, no dejar de seguir rezando muy bien y que los babalawos le preparan las hierbas de Ifa, para que
no se le presenta oponente para el mismo puesto o cargo que quiere el y dejarle lograr sus objetivos.
Ifa lo dice asi en con este verso que hay seis mal-deseados que le están esperandos para no dejarle
llegar a su destino jamás y cruzaran sus caminos; QUE:

Bọgbọn ba tán ninu awo, a dèkè. (Si no le queda la intenligencia en awo, se convierte en
mentiroso)

Bọrọ badùn àgbà ladùnju, a di òsika. (Si un asunto duele mucho a un persona mayor, se
convierte en mal-deseado)

Àgbàlàgbà to dàgbà, to loun ò kọfá mọ. (Una persona mayor que dice que no quiere aprender
mas Ifa)

Toba pẹẹ, tinu-rẹ a sii rú súsúsú. (Despues de un tiempo, lo que hay en su estomago
eruptara)

A díá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Baba nsawo rode Ìsoko. (El padre iba a predicar Ifa en la ciudad de Ìsoko)

Ọrúnmìlà ni nsawo rode Ìsoko. Wọn ni kó rubọ koto lọ. Wọn lawọn ajogun mẹfa lowà loju ọna. Wọn ni
kóni AKUKỌ ADIẸ MẸFA lẹbọ nibẹ, kóni ÒKÉTÉ MẸFA lẹbọ nibẹ, kóni ỌKẸ-ÓWÓ MẸFA lẹbọ nibẹ.
Ọrúnmìlá gbọ ruru, ó ru. O gbọ tutu, ó tu. O gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, ó ha. Ni Ọrúnmìlà ba kọrí
sode Ìsoko. Bóti nlọ. Ikú ló kọkọ pade loju ọna, nikú bada Ọrúnmìlà duro. Ó ni, kínní o daun duro fún.
Iku ni kò sibiti yoo lọ. Ọrúnmìlà ba funkú ni òkété-kan, ọkẹ-ówó kan ati akukọ adiẹ kan. Ikú ni, kínní
oun tun nwa, ó ni kọrúnmìlà malọ.

Bi Ọrúnmìlà ti nlọ. O tun pade Àrùn loju ọna. Ni Àrùn bada Ọrúnmìlà duro. Ó ni, oun Ọrúnmìlà; kínní
o daun duro fún. Àrùn ni kò sibiti yoo lọ. Ọrúnmìlà ba fun Àrùn lòkété-kan, ọkẹ-ówó kan ati akukọ
adiẹ kan. Àrùn ni, kínní oun tun nwa, ó ni kọrúnmìlà malọ.
Bi Ọrúnmìlà ti nlọ. O ba tun pade Ofò loju ọna. Ni Ofò bada Ọrúnmìlà duro. Ó ni, oun Ọrúnmìlà; kínní
o daun duro fún. Òfò ni kò sibiti yoo lọ. Ọrúnmìlà ni, awọn babalawo ma sọ bẹẹ, wipe ẹlẹkẹta ma niyi.
Ọrúnmìlà ba fun Ofò lòkété-kan, ọkẹ ówó kan ati akukọ adiẹ kan. Òfò ni, kínní oun tun nwa, ó niki
Ọrúnmìlà malọ.

Bi Ọrúnmìlà ti nlọ, ó tun pade ẹlẹkẹrin loju ọna Àseìrì. Ni Àseìrì bada Ọrúnmìlà duro. Ó ni, oun
Ọrúnmìlà; kínní o dahun duro fún. Àseìrì ni kò sibiti yoo lọ. Ọrúnmìlà ba fun Àseìrì lòkété-kan, ọkẹ-
ówó kan ati akukọ adiẹ kan. Àseìrì ni: ¡kínní oun tun nwa!, ó niki Ọrúnmìlà malọ.

Bi Ọrúnmìlà ti nlọ, ó tun pade ẹlẹkarún loju ọna “Àfàìto”. Ni Àfàìto bada Ọrúnmìlà duro. Ó ni, oun
Ọrúnmìlà; kínní o daun duro fún. Àfàìto ni kò sibiti yoo lọ. Ọrúnmìlà ba fun Àfàìto lòkété-kan, ọkẹ-
ówó kan ati akukọ adiẹ kan. Àfàìto ni, ¡kínní ohun tun nwa!, ó niki Ọrúnmìlà malọ.

Bi Ọrúnmìlà ti nlọ. O ba tun pade ẹlẹkẹfa loju ọna “Àìrí-tajése”. Ni Àìrí-tajése bada Ọrúnmìlà duro. Ó
ni, oun Ọrúnmìlà; kínní o daun duro fún. Àìrí-tajése ni kò sibiti yoo lọ. Ọrúnmìlà ba fun Àìrí-tajése
lòkété-kan, ọkẹ-ówó kan ati akukọ adiẹ kan. Àìrí-tajése ni, kínní oun tun nwa, ó niki Ọrúnmìlà malọ.

Ni Ọrúnmìla ba morin awo sẹnu. Ó ni; Bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun sọ. Ó
ni:

Ọrúnmìlà iba a predicar Ifa en la ciudad de Ìsoko. Dijieron a Ọrúnmìlà que debe hacer el sacrificio
antes de irse, porque hay seis maldiciones esperándole en su camino. Dijieron que debe tener SEIS
GALLOS en su sacrificio, debe tener SEIS RATAS GRANDES en su sacrificio, debe tener SEIS ỌKẸ DE
DINERO en su sacrificio. Ọrúnmìlá oio el sacrificio y sacrifico. Oio el ofrecimientos y ofreció. Hizo caso
a lo que salió en el tablero de la adivinacion de Ifa. Ọrúnmìlà se fue a predicar Ifa en la ciudad de Ìsoko.

Primero, encontró la muerte en su camino. La muerte paro a Ọrúnmìlà. ¿ Ọrúnmìlà pregunto a la


muerte porque le paro?. La muerte le dijo que no podia irse a ningún sitio. Ọrúnmìlà le dio una rata
grande, un ”ọkẹ” de dinero y un gallo. La muerte dijo: ¡Que mas quería yo!, dejo a Ọrúnmìlà irse.

Ọrúnmìlà seguia en su camino, encontró a la enfermedad. La enfermedad paro a Ọrúnmìlà. ¿


Ọrúnmìlà pregunto a la enfermedad porque le paro?. La enfermedad le dijo que no podia irse a
ningún sitio. Ọrúnmìlà le dio una rata grande, un ”ọkẹ” de dinero y un gallo. La enfermedad dijo: ¡Que
mas quería yo!, dejo a Ọrúnmìlà irse.

Ọrúnmìlà seguia en su camino, encontró la tercera maldición “la perdida”. La perdida paro a
Ọrúnmìlà. ¿ Ọrúnmìlà pregunto a la perdida porque le paro?. La perdida le dijo que no podia irse a
ningún sitio. Ọrúnmìlà le dio una rata grande, un ”ọkẹ” de dinero y un gallo. La perdida dijo: ¡Que mas
quería yo!, dejo a Ọrúnmìlà irse.

Ọrúnmìlà seguía en su camino, encontró el cuarto “Àseìrì”. El cuarto “Àseìrì” paro a Ọrúnmìlà. ¿
Ọrúnmìlà pregunto al cuarto porque le paro?. El cuarto “Àseìrì” le dijo que no podia irse a ningún
sitio. Ọrúnmìlà le dio una rata grande, un ”ọkẹ” de dinero y un gallo. El cuarto Àseìrì dijo: ¡Que mas
quería yo!, dejo a Ọrúnmìlà irse.

Ọrúnmìlà seguía en su camino, encontró el quinto “Àfàìto”. El quinto paro a Ọrúnmìlà. ¿ Ọrúnmìlà
pregunto a la “Àfàìto” porque le paro?. El quinto “Àfàìto” le dijo que no podia irse a ningún sitio.
Ọrúnmìlà le dio una rata grande, un “ọkẹ” de dinero y un gallo. El quinto “Àfàìto” dijo: ¡Que mas
quería yo!, dejo a Ọrúnmìlà irse.

Ọrúnmìlà seguia en su camino, encontró el sesto “Àìrí-tajése” en el camino. Àìrí-tajése paro a


Ọrúnmìlà. ¿ Ọrúnmìlà pregunto al sesto “Àìrí-tajése” porque le paro?. El sesto le dijo que no ppdia
irse a ningún sitio. Ọrúnmìlà le dio una rata grande, un “ọkẹ” de dinero y un gallo. El sesto “Àìrí-
tajése” dijo: ¡Que mas quería yo!, dejo a Ọrúnmìlà irse.

Ọrúnmìlà abrió la boca y le salió la canción de awo, decía que; Asi mismo lo adivinaron y lo cantaron
sus babalawos; QUE:

Bọgbọn ba tán ninu awo, a dèkè. (Si no le queda la intenligencia en awo, se convierte en
mentiroso)

Bọrọ badùn àgbà ladùnju, a di òsika. (Si un asunto duele mucho a un persona mayor, se
convierte en mal-deseado)

Àgbàlàgbà to dàgbà, to loun ò kọfá mọ. (Una persona mayor que dice que no quiere aprender
mas Ifa)

Toba pẹẹ, tinu-rẹ a sii rú súsúsú. (Despues de un tiempo, lo que hay en su estomago
eruptara)

A díá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Baba nsawo rode Ìsoko. (El padre iba a predicar Ifa en la ciudad de Ìsoko)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto, no tan lejano)


Ẹ wa wofá awo ki biti nsẹ. (Usteds ven a ver lo que el awo adivino se hizo realidad)

Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)

Ifá wa bawa larusẹgun. (Ifa ven a ayudarnos en levantamiento y aceptación de


nuestro sacrificio)

Arusẹgun laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En el medio de levantamiento y aceptación de sacrificio
se encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Ó nse: ORIN: (CANCION)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ. (Yo me he consagrado con ellos)

Ikú gbà Òkété, ọwọ mi ò to. (La muerte acepto la rata grande, no me cogio a mi)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Àrùn gbà Òkété, ọwọ mi ò to. (La enfermedad acepto la rata grande, no me cogio a mi)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Òfò gbà Òkété, ọwọ mi ò to. (La perdida acepto la rata grande, no me cogio a mi)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Àseìrì gbà Òkété, ọwọ mi ò to. (La “Àseìrì” acepto la rata grande, no me cogio a mi)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)


Emi wọn nimùlẹ. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Àfàìto gbà Òkété, ọwọ mi ò to. (La “Àfàìto” acepto la rata grande, no me cogio a mi)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ. (Yo me he consagrado con ellos)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

Àìrí-tajése gbà Òkété, ọwọ mi ò to. (La “Àìrí-tajése” acepto la rata grande, no me cogio a mi)

Emi wọn nimùlẹ o. (Yo me he consagrado con ellos)

ASẸ IFA:- Ifá leleyii nlọ sibikan. Ifá ni to bati rubọ kóto lọ, wọn yoo jẹki ó debẹ o. Tikò bati rubọ, awọn
ajogun-mẹfa nbẹ loju ọna, tiwọn kòni jẹki ó debẹ loju ìsalaiye.

ASẸ IFA:- Ifa dice que este consultante quiere irse a un sitio. Ifa dice que si hace el sacrificio antes de
irse, le dejaran llegar a su destino. Ifa dice que si este consultante no hace el sacrificio antes de irse, Ifa
que hay seis maldiciones/mal deseados que le están esperandos para no dejarle llegar a su destino
jamás, cruzaran sus caminos.

3·4. ÌWÒRÌ ÒDÍ. (Ìwòrì-di). (Ìwòrì wo-di).

ẸSẸ KINNI.
Ire. (Bendicion)

Ifá ni nkan àtunse kan leleyii dafá si. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kósi BỌ EGÚNGÚN nibẹ, kóle ba saseyọrí nibẹ.
Boya eleyii nwa ọmọ ni o, boya eleyii nwa ìyawo ni o, boya eleyii nwa nkan ilọsiwaju kan ni o, tabi ibisẹ ni o. Ifá
ni keleyii rubọ nibẹ. Teleyii basi bimọ tan, ọmọbinrin ni yoo fibi, ÁTÓ lorukọ rẹ yoo sima jẹ. To basi jọkùnrin
leleyii bi, Ifá ni yoo maa jẹ ÀMUSÀN. Ọmọ egúngún ni. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re pe nkan àtúnse kan leleyii
nwa. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona esta intentando areglar algo. Ifa dice que debe hacer el sacrificio, debe DAR
DE COMER A EGÚNGÚN, para que puede prosperar en lo que esta areglando. Puede ser que esta
persona esta buscando tener hijo, o tener esposa, o tener prosperidad, o tener trabajo. Ifa dice que
esta persona debe hacer el sacrificio. Después de tener hijo, si es una hembra se llamara ÁTÓ, si es un
macho se llamara ÀMUSÀN. Ifa dice que es hijo de egúngún. Ifa lo dice asi en este verso que esta
persona esta intentando areglar algo; QUE:

Ìwòrì wò mi. (Ìwòrì me miro)

Ìdin wò mi. (Ìdin me miro)

A difá fun Bárá-ákáiyé-jẹ (Se adivino Ifa para Bárá-ákáiyé-jẹ)

Ìwòrì wò mi. (Ìwòrì me miro)

Ìdin wò mi. (Ìdin me miro)

A difá fun Bárá-ákọrọ-jẹ. (Se adivino Ifa para Bárá-ákọrọ-jẹ)

Ìwòrì wò mi. (Ìwòrì me miro)

Ìdin wò mi. (Ìdin me miro)

A difá fun Átó forí pa òòkún. (Se adivino Ifa para Átó forí pa òòkún)

Átó kekere abẹnu jege-jege. (Átó chiquitito que tiene la boca firme)
Wọn ni kiwọn ó rubọ nibẹ, pọnà gbọdọ là funwọn. Wipe gbogbo oun tiwọn ba nse, wọn gbọdọ
saseyọrí nibẹ. Niwọn ba rubọ. Wọn lọ BỌ EGÚNGÚN. Bọnà wọn se là niyi, nire gbogbo bade. Niwọn
ba nyin babalawo wọn, ni awọn babalawo wọn nyin Ifá. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo tawọn wi, bẹẹ gẹgẹ
ni babalawo tawọn sọ:

Dijieron a todos ellos que deben hacrel sacrificio, dijieron que sus caminos se abrirán y que
prosperaran en todos lo que hacian, hicieron el sacrificio y dieron DE COMER A EGÚNGÚN. Asi
empezó a abrir sus caminos, les llegaron todas las bendiciones. Empezaron a alabar a sus babalawos y
sus babalawos alabandos a Ifa. Decian que asi mismo lo adivinaron y lo cantaron su babalawo; QUE:

Ìwòrì wò mi. (Ìwòrì me miro)

Ìdin wò mi. (Ìdin me miro)

A difá fun Bárá-ákáiyé-jẹ (Se adivino Ifa para Bárá-ákáiyé-jẹ)

Ìwòrì wò mi. (Ìwòrì me miro)

Ìdin wò mi. (Ìdin me miro)

A difá fun Bárá-ákọrọ-jẹ. (Se adivino Ifa para Bárá-ákọrọ-jẹ)

Ìwòrì wò mi. (Ìwòrì me miro)

Ìdin wò mi. (Ìdin me miro)

A difá fun Átó forí pa òòkún. (Se adivino Ifa para Átó forí pa òòkún)

Átó kekere abẹnu jege-jege. (Átó chiquitito que tiene la boca firme)

Ẹbọ niwọn ni wọn ó se, (Dijieron que deben hacer el sacrificios)

Won si gbẹbọ nibẹ, wọn rubọ. (Lo hicieron)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani nijbutu ire. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de bendiciones)
Ìjẹbutu ire laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En medio de celebración de bendicion se encuentra uno a
los pies del rey de los Orisas).

ASẸ IFÁ:- Ifá ni keleyii rubọ nibẹ. Ifa ni wipe ọnà rẹ yoo là, inu rẹ yoo dun, ti yoo si saseyọrí ninu nkan
to bafẹ se.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hace el sacrificio. Ifa dice que su camino abrirá, será feliz y
prosperara en lo que quiere hacer.

ẸSẸ KEJI.

Ire - Aya (Bendicion de esposa)

Ifá tun nsọ feleyii wipe obinrin kan leleyii fẹ fẹ, tabi ó fẹ yàn lọrẹ ni. Ifá ni tikò bati tọju obinrin yi dada, kòni
gbadùn rẹ. Obinrin yi kòni jẹki ó baun-sùn. Tọkùnrin yi ba toju obinrin yi, wọn yoo gbadùn arawọn. To basi
jobinrin lo dafá, tofẹ fọkùnrin. Ifa ni wipe obinrin yi gbọdọ huwà dada sọkùnrin yi, kólé báà gbadùn rẹ. Tobinrin
yi bati nse nkan tọkùnrin yi nfẹ, ọkùnrin yi yoo maa se tirẹ ni gbogbo ìgbà. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa
na sọ pe:

Ifa le esta diciendo a esta persona que quiere casarse con una mujer o tenerla de novia. Ifa dice que
debe cuidar bien a esta mujer para disfrutarla, esa mujer le dejara acostarse con ella si no la cuida. Si
este hombre cuida bien de esta mujer, los dos disfrutaran entre ellos. Si es una mujer que ha hecho
esta consulta, Ifa dice que quiere casarse con un hombre o tenerle de novio. Ifa dice que si cuida bien a
este hombre, disfrutara del hombre y el hombre será suya en todos los momentos. Ifa lo dice en este
verso; QUE:
Alẹ lẹ. (Se hizo de noche)

Alẹ lẹ. (Se hizo de noche)

A gbọ sínrínkún-sínrínkún awọn ẹfọ lorí ina. (Escuchamos los “sínrínkún-sínrínkún” de los
vegetales gizandose en el fuego)

Alẹ lẹ. (Se hizo de noche)

A gbọ poroki-poroki odo, à ríyan. (Escuchamos los “poroki-poroki” del mortero y no


vimos a la pasta del yame)

Ọgànjọ gàn dùndùndùn. (Se hizo de marugada)

A gbọ wọyọ-wọyọ kọnkọsọ, à ramàlà. (Escuchamos los “wọyọ-wọyọ” del colador y no vimos
a la pasta del yame seca. “Àmàlà”)

Alẹ lẹ. (Se hizo de noche)

À gbọ sínrínkún-sínrínkún awọn ẹfọ lorí ina. (Escuchamos los “sínrínkún-sínrínkún” de los
vegetales gizandose en el fuego)

A difá fun Ìwòrì. (Se adivino Ifa para Ìwòrì)

Tiwọn ni ó wa w’odi lebi. (Que dijieron que iba a refrescar a Odi del hambre)

Ero Opo, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)

Ìwórì séé w”odi lebi. (¡Como el Ìwórì se refresco a Odi del hambre!)

ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni teleyii kòba jẹun kanu, kòni ríhòhò obinrin yi rara, tikò bati
tọju rẹ.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que si esta persona no es capaz de
cuidar a esta mujer, no vera a ella desnuda jamás, si no se cuida bien de ella.
3·5. ÌWÒRÌ ÌROSÙN. (Ìwòrì-Rosùn).

ẸSẸ KINNI.

Ire Ọmọ. (Bendicion de hijo)

Ifá ni obinrin kan niyi, Ifa ni wipe oju ọmọ npọn obinrin yi. Ifa ni wipe kió rubọ nibẹ, Ifa ni yoo bimọ. Kosi lọ
BỌ EGÚNGÚN. Tegúngún ba nbẹ nirán wọn, kó lọ BỌ EGÚNGÚN yi. Ifá ni yoo bimọ, ti yoo bọlọmọ pe. Ifá ni
kó setutu nibẹ, kósí sunmọ awọn babalawo, kiwọn jewé Ifá fun-un. Ifá leleyii yoo rọmọ pe rànsẹ, ti gbogbo ẹdùn
ọkàn rẹ yoo dohun ìgbàgbè, tọràn rẹ yoo sigún. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifadice que hay una mujer que esta apurada por tener hijo. Ifa dice que debe hacer el sacrificio y tendrá
hijo. Ifa dice que debe DAR DE COMER A EGÚNGÚN. Ifa dice que si hay egúngún en su familia, que es
mejor dar de comer a egúngún de su familia. Ifa dice que tendrá hijo. Ifa dice que debe hacer
ofrecimientos y acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa. Ifa dice que ella
tendrá hijo, su deseo se cumplirá y estará bien. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ka gbe súrú jata. (Comemos el picante con pacencia)

Ka sigbe sùrù jobi. (Comemos las nueces de cola con pacencia)

Ègbè nirúnmọlẹ fi nseke ọmọ-awo. (La diedad desmiente al hijo de awo con el coro)
A difá fun Olu. (Se adivino Ifa para Olu)

Ti nsúnkún poun ò bimọ. (Que estaba llorando que no tienia hijo)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani nijẹbutu ọmọ. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de


bendición de hijo)

Ìjẹbutu ọmọ laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En el medio de la celebración de bendición de hijo se
encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Nlẹ o Olu. (Saludo a Olu)

Olurohúnbi. (Olurohúnbi)

Pẹlẹ ò Olu. (Bienvenido Olu)

Olurohúnbi. (Olurohúnbi.)

Ifá leleyii yoo bimọ, ti yoo bọlọmọ pe. Olurohúnbi lọmọ na yoo maa jẹ. Ó rubọ. Kò pẹ, kò jìnnà. Ni
Olurohúnbi ba loyun, lóba bimọ, tosi bọlọmọ pe. Ni ó ba njo, tó nyọ, ó nyin awọn babalawo rẹ, awọn
babalawo rẹ si nyin Ifá. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun sọ:

Ifa dice que esta persona tendrá hijo, estará entre los padres. Ifa dice que ese hijo se llamara
“Olurohúnbi”. La mujer hizo sacrificio. Pronto y no tan lejano. Olurohúnbi se quedo embarazada, dio
la luz al niño y estaba dentro de los padres. Estaba feliz y empezo a bailar, alabando a su babalawo y su
babalawo alabandos Ifa; Que asi mismo lo adivino y canto su babalawo; QUE:

Ka gbe súrú jata. (Comemos el picante con pacencia)

Ka sigbe sùrù jobi. (Comemos las nueces de cola con pacencia)

Ègbè nirúnmọlẹ fi nseke ọmọ-awo. (La diedad desmiente al hijo de awo con el coro)
A difá fun Olu. (Se adivino Ifa para Olu)

Ti nsúnkún poun ò bimọ. (Que estaba llorando que no tienia hijo)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani nijẹbutu ọmọ. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de


bendición de hijo)

Ìjẹbutu ọmọ laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En el medio de la celebración de bendición de hijo se
encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Nlẹ o Olu. (Saludo a Olu)

Olurohúnbi. (Olurohúnbi)

Pẹlẹ ò Olu. (Bienvenido Olu)

Olurohúnbi. (Olurohúnbi.)

ASẸ IFÁ:- Ifá lobinrin kan niyi, Ifa ni wipe oju ọmọ npọn obinrin yi. Ifa ni wipe kó rubọ nibẹ, Ifa ni yoo
bimọ. Kosi lọ BỌ EGÚNGÚN, tegúngún ba nbẹ nirán wọn, kólọ bọ ọ. Ifá lobinrin yi yoo bimọ, ti yoo
bọlọmọ pe.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que hay una mujer que esta apurada por tener hijo; Ifa dice que debe hacer el
sacrificio y tendrá hijo. Ifa dice que debe DAR DE COMER A EGÚNGÚN, si hay egúngún en su familia,
porque es mejor dar de comer a egúngún de su familia. Ifa dice que tendrá hijo y estará entre los
padres.
ẸSẸ KEJI:

Ire Ọmọ. (Bendicion de hijo)

Ifá si tun nsọ fẹniti ó dafá yi, wipe yoo nifọkàn-balẹ. Gbogbo ohun to jẹdùn ọkàn rẹ pata, ni Olodumare
yoo se fun-un, tó bati rubọ. Ifá ladura rẹ yoo gbà. Ifá loju ọmọ npọn eleyii, wipe kó rubọ nibẹ. Ifá
lakoko ti yoo bimọ niyi, KIWỌN MA JẸKI ẸBỌ-RẸ JU ỌTUNLA LỌ. Tó bati rubọ, yoo bimọ. Ẹbọ rẹ kò
gbọdọ kọja ọjọ-mẹta, Ifá lakoko eleyii tito lati bimọ. Ibi tifá gbà sọ bẹẹ niyi, tosi pa lasẹ pẹbọ-rẹ kò
gbọdọ ju ọjọ-mẹta lọ ti yoo fise niyi o. Ó ni:

Ifa le esta diciendo a la persona que ha hecho esta consulta también que lograra su bien-estar y
tranquilidad. Ifa dice que todos lo que le están doliendos y sus apuros se lo solucionara Olodumare. Ifa
dice que si hace sacrificio, sus deseos serán cumplidas y sus rezos serán aceptada. Ifa dice que sus
apuros por tener hijo, que debe hacer el sacrificio y que ya llego su momento de tener hijo. QUE SU
SACRIFICIO DEBE HACERSE ANTES DE PASADO MANANA. Que después de hacer el sacrificio tendrá
hijo, que su sacrificio no debe pasar tres días antes de hacerse. Ifa lo dice con este verso que su
sacrificio no debe pasar los tres días antes de hacerse; QUE:

Ìtìwánrín mẹbọ Ìwo. (“Ìtìwánrín” cogió el sacrificio de Ìwo)

Ọrọ mẹbọ Ìjàyè. (“Ọrọ” cogió el sacrificio de Ìjàyè)

Toba kàn ẹsẹ-kan soso isoro. (Si falta un paso solamente a dificultad)

Ẹ má mà jẹlé Òlòrò ò bajẹ. (Ustedes no dejan que la casa de Òlòrò se rompe/echarse a


peder)

A difá fun Olu. (Se adivino Ifa para Olu)

Ti nsúnkun poun ò bimọ. (Que estaba llorando que no tiene hijo)

Ìgbàti yoo bi; ó bimọ. (Cuando iba a dar la luz, dio la luz a niño)
Wọn ni kolu ó rubọ, wipe akoko-rẹ ti yoo bimọ niyi o. Kó majẹ kẹbọ-rẹ ju ọtunla lọ o. Ifá ni to bati
jọtunla lọ, kòni bimọ o. Sugbọn tikò bati jọtunla lọ, tabi lọtunla, Ifá ni yoo bimọ. Ni ó ba rubọ koto
dọjọ-kẹta. Ni oyun ba duro sii lara, ó si bimọ. Ni ó ba nyin awọn babalawo rẹ, awọn babalawo rẹ si
nyin Ifá. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun sọ:

Le dijieron que debe hacer el sacrificio porque ya llego su momento de tener hijo. Ifa dice que debe
asegurarse que su sacrificio se hace antes de pasado mañana o precisamente pasado mañana y tendrá
hijo. Ifa dice que si el sacrificio pasa los tres días, esta mujer no tendrá hijo. Ella hizo el sacrificio antes
de los tres días. Se quedo embarazada y dio la luz al niño. Empezo a alabar a sus babalawos y sus
babalawos alabandos Ifa, que asi mismo lo adivinaron y cantaron sus babalawos; QUE:

Ìtìwánrín mẹbọ Ìwo. (“Ìtìwánrín” cogió el sacrificio de Ìwo)

Ọrọ mẹbọ Ìjàyè. (“Ọrọ” cogió el sacrificio de Ìjàyè)

Toba kàn ẹsẹ-kan soso isoro. (Si falta un paso solamente a dificultad)

Ẹ má mà jẹlé Òlòrò ò bajẹ. (Ustedes no dejan que la casa de Òlòrò se rompe/echarse a


peder)

A difá fun Olu. (Se adivino Ifa para Olu)

Ti nsúnkun poun ò bimọ. (Que estaba llorando que no tiene hijo)

Ìgbàti yoo bi; ó bimọ. (Cuando iba a dar la luz, dio la luz a niño)

Ìwòrì ka sùnre. (Ìwòrì dejanos dormir bien)

Ka má mà jọjọ olosu ò yẹ. (No dejamos que su dia de la luna falla)

Ìwòrì ka sùnre. (Ìwòrì dejanos dormir/descansar bien)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)


Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto, no tan lejano)

Ifá wa bani nijẹbutu ọmọ. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de bendición de
hijo)

Ìjẹbutu ọmọ laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En medio de celebración de bendición de hijo se encuentra
uno a los pies del rey de los Orisas).

ASẸ-IFÁ:- Ifá ni keleyii fọkàn balẹ. Ifá losu eleyii tile lati bimọ. Ifa ni keleyii ó rubọ nibẹ. KIWỌN MA
JẸKI ẸBỌ-RẸ JU ỌTUNLA LỌ.

ASẸ-IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe confiar y estar tranquilo. Ifa dice que ya esta en su luna para
tener hijo. Ifa dice que debe hacer el sacrificio. QUE SU SACRIFICIO DEBE HACERSE ANTES DE
PASADO MANANA.

3·6. ÌWÒRÌ-ỌWỌNRÍN. (Ìwòrì-Warẹrin, Ìwòrì-Ọwárí, Ìwòrì-Ẹlẹrí).

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun ọmọ. (Investigar vencimiento de hijo)


Ifá yi la npe ni: “Ìwòrì-Warẹrin, ẹrin kò peyin”. Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ nitorí ọmọ. Kómá báà jẹpe ọmọ ti yoo
bi, ọmọ ti yoo máà báà ninu jẹ nigbà gbogbo ni. Kómá báà bi ìbanujẹ-ọmọ, ọmọ ti kòni sànjọ, ti yoo maa da
wahala seleyii lọrùn, tikò ni da rere walé-aiye, ìdamu ni yoo maa ba, keleyii má bi ìdàmu-ọmọ. Ifá sọ bẹ wipe
keleyii ó rubọ, kó setutu. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Este Ifa se llama: “Ìwòrì ven a reírse pero no es para reirse”. Ifa dice que esta persona debe hacer el
sacrificio por hijo, para que el hijo que va a tener, no le quita la felicidad en cada momento. Para que
no sea un niño de infelicidades, un niño que no va a ser útil, un niño que le va a llevar a problemas en
cada momento, un niño que no viene con bendición al mundo, que le dara problema, para que no sea
un niño de infelicidades. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y ofrecimientos para no tener
un hijo problematico. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ìwòrì-Warẹrin. (Ìwòrì ven a reírse)

Ẹrin kò peyin. (No es para reirse)

A difá fun Olorí-Ẹgbẹ. (Se adivino Ifa para Olorí-Ẹgbẹ)

Eyiti yoo bi Seewo lọmọ. (El que iba a dar la luz a “Seewo” como hijo)

Wọn ni kolorí Ẹgbẹ rubọ, kómá báà kàn ìbanujẹ, kómá báà bèmèrè lọmọ o. Olorí Ẹgbẹ si rubọ. Kò pẹ
o, kò jìnnà. Lóba sẹgun. Nigbà tó bimọ to lalubarika, lóba njo, ó nyọ, ó nyin awo rẹ, awọn awo rẹ si
nyin Ifá. Ó lawọn babalawo ma tisọ poun kòni bimọ ìdamu, wipe ewé-Ifá tiwọn ja fun-un lojẹ kisẹgun
de. Ni ó ba njo, ó nyọ. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun sọ:

Dijieron a Olorí-Ẹgbẹ que debe hacer el sacrificio para no encontrar la infelicidad, para que no tenga
un niño que viene al mundo para no quedarse “que va a murir”. Olorí-Ẹgbẹ hizo el sacrificio. Pronto y
no tan lejano, venció y dio a luz a un nino con bendición. Olorí-Ẹgbẹ estaba feliz y empezó a bailar,
alabando a su awo y su awo alabandos a Ifa. Decia que las hierbas de Ifa que le prepararon le ayudo a
vencer. Olorí-Ẹgbẹ estaba feliz, empezó a bailar y cantar, que asi mismo lo adivinaron y cantaron sus
babalawos; QUE:

Ìwòrì-Warẹrin. (Ìwòrì ven a reírse)


Ẹrin kò peyin. (No es para reirse)

A difá fun Olorí-Ẹgbẹ. (Se adivino Ifa para Olorí-Ẹgbẹ)

Eyiti yoo bi Seewo lọmọ. (El que iba a dar la luz a “Seewo” como hijo)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Komá báà bèmère lọmọ. (Para que no tenga un niño que nace para no quedarse a vivir
en este mundo)

Ó gbọ riru, ó ru. (Oio el sacrificio y sacrifico)

Ó gbọ titù, ó tù. (Oio el ofrecimiento y ofreció)

Ó gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, ó ha. (Hizo caso a lo que salió en el tablero de Ifa)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani nijẹbutu ọmọ. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de bendición de
hijo)

Ìjẹbutu ọmọ laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En medio de celebración de bendición de hijo se encuentra
uno a los pies del rey de los Orisas).

ASẸ IFÁ:- Ifá ni keleyii rubọ nibẹ, kómá báà bimọ ìbanujẹ, ọmọ ti yioo maa darán nigbà gbogbo, ọmọ
abikú.

ASẸ IFÁ:- Ifá dice que este persona debe hacer sacrificio para que no tenga un niño que le puede llevar
a la infelicidad, un niño que le va a llevar problemas en cada momento , un hijo que nace para no
quedarse a vivir en este mundo.

ẸSẸ KEJI.
Ayẹwo Ọfọ (Investigar la perdida)

Ifá ni nkankan lo sọnu yi nilé awọn ẹni to dafa yi. Ifá lodidi eniyàn gan lo sọnu. Ifá niwọn ti gbee lọ. Ifá ni
kiwọn rubọ nitorí-rẹ, kiwọn silọ BỌ EGÚNGÚN nibẹ. Kiwọn ni ẸIYẸLE-MẸRIN lẹbọ nibẹ, ÒRUKỌ-MẸRIN lẹbọ
(tikò tikú, ti nrùn, tó nja fọnfọn), ẸGBẸRIN-ÓWÓ ni kóni lẹbọ nibẹ. Ifá nisẹgun yoo de bawọn, wọn yoo ri nkan
to sọnu yi, bẹẹ ni. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o wipe wọn yoo ri nkan to sọnu. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que algo ha desaparecido en la casa de este consultante. Ifa dice que es una persona que ha
desaparecido en la casa de este consultante. Ifa dice que deben hacer el sacrificio para esta persona
desaparecida, deben DAR DE COMER A EGÚNGÚN. Ifa dice que deben tener CUATRO PALOMAS en
su sacrificio, que deben tener CUATRO CHIVOS (chivos vivos y que apestan bastante) en su sacrificio,
deben tener OCHO CIENTOS DE DINERO en su sacrificio. Ifa dice que veceran y encontraran lo que ha
desaparecido en su casa. Ifa lo dice asi con este verso que encontraran lo que ha desaparecido en su
casa; QUE:

Ìwòrì-Warẹrin. (Ìwòrì ven a reírse)

Ẹrin kò peyin. (No es para reirse)

A difá fun wọn Lotu Ifẹ. (Se adivino para ellos en la ciudad de Otu Ifẹ)

Nibiti Ìrúnmọlẹ ti ngbe ọmọ-eniyàn; (Donde la diedad secuestra a seres humanos)

Bi ẹniti ngbe ẹràn. (Como si fuera que estaba secuestrando a los animales)

Ẹbọ niwọn ni wọn ó se. (Les dijieron que deben hacer el sacrificio)

Wọn si gbẹbọ nibẹ, wọn rubọ. (Lo hicieron)

Rúrú ẹbọ ni fín ti gbeni. (Haciendo sacrificio es lo que ayuda a uno)

À tete tu tesu a dàrà danu. (Apasiguando a Esu lo antes posible desvia la mala
suerte)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)


Ifá wa bawa larusẹgun. (Ifa ven a ayudarnos en levantamiento y aceptación de
nuestro sacrificio)

Arusẹgun laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En el medio de levantamiento y aceptación de sacrificio
se encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Wọn nse: ORIN: (CANCION)

Awa ò ma ma rírú eleyii rí o. (¡Nosotros nunca hemos visto algo como este!)

Irúnmọlẹ. (Diedad)

Awa kò rírú eleyii rí o. (¡Nosotros nunca hemos visto algo como este!)

Ẹ gbàwa o. (Ustedes ayudanos)

ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii ó rubọ nibẹ. Ifa ni wipe isẹgun tide fẹniyii. Ifá ni nkan to sọnu, wọn yoo rii loju
Ìwòrì-Warẹrin.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer sacrificio y vencerá. Ifa dice que lo que ha
desaparecido, lo van a encontrar en el signo de Ìwòrì-Warẹrin.

3·7. ÌWÒRÌ-ỌBÀRÀ. (Ìwòrì-Ọpàjùbà, Ìwòrì-Ọbẹrẹ)


.
ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo

Ìwòrì-Ọbàrà ni a npe ni “Ìwòrì ò bẹrẹ tofi nyagbẹ”. Ifá ni kasọ fẹniti ó dafá yi, wipe kó rubọ nitoripe ẹnikan nbẹ
ti yoo maa ja ẹniyii lole, tó nji nkan eleyii. Ifá ni teleyii bati rubọ nibẹ, koni ÌTÌ- OKÙN ÁGBÁ KAN lẹbọ, Ifá ni
lọdun yi lasiri ẹniti nja a lole yoo tu, ti yoo si m’ole yi lọdun-ni. Bayi nifá gbà fisọ bẹẹ loju ‘Ìwòrì ò bẹrẹ tofi
nyagbẹ’. NIbi tifa wa gba to fi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ìwòrì Ọbàrà es lo que llamamos “Ìwòrì no se agacha antes de hacer sus necesidades”. Ifa le esta
diciendo a esta persona que debe hacer el sacrificio, porque hay una persona que va a estar robándole
sus cosas. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe tener UN ROLLO DE SOGA en su
sacrificio. Ifa dice que descubrira y cogera esa persona que le esta robando este ano. Ifa lo dice asi con
este verso en el signo de “Ìwòrì no se agacha antes de hacer sus necesidades”; QUE:

Ìwòrì ò bẹrẹ tofi nyagbẹ’. (Ìwòrì no se agacho antes de hacer sus necesidades “cargar”)

Awo Asúnu. (Awo de Asúnu)

Lo díá fun Asúnu. (Adivino Ifa para Asúnu)

Wọn ni kó rubọ (Dijieron que debe hacer el sacrificio

Ó gbọ riru, ó ru. (Oio el sacrificio y lo hizo)

Ó gbọ titù, ó tù. (Oio el ofrecimiento y ofreció)

Ó gbọ ọhahaha ẹbọ loju ọpọn, ó ha. (Oio lo que salió en el tablero de Ifa y lo hizo)

Wọn niki Asúnu ó rubọ nitorí awọn tiwọn ndaa laamú, tiwọn njaa lole, tiwọn ngbe nkan rẹ. Asúnu si
gbẹbọ nibẹ, ó rubọ.
Dijieron a Asúnu que debe hacer el asacrificio por las gentes que le están estorbando y haciéndole la
vida imposible, las gentes que le están robandos sus pertenencias. Asúnu hizo el sacrificio.

Ìwòrì ò bẹrẹ tofi nyagbẹ’. (Ìwòrì no se agacha antes de hacer sus necesidades)

Awo Olè. (Awo del Ladron)

Lo díá fun Olè. (Adivino Ifa para el Ladron)

Wọn ni kolè ó rubọ (Dijieron al Ladron que debe hacer el sacrificio)

Olè kọ kò rubọ. (El ladron se negó en hacer el sacrificio)

Ó pawo leke. (Llamo a Awo mentiroso)

Ó pesu lolè. (Llamo a Esu ladron)

Ó wo ọrun yànyànyàn, bi ẹnipe ilẹ kòni sú mọ. (Miro al cielo tan brillante como que no iba a hacer
de noche)

Olè ni, kínní pé koun rubọ, awọn alatẹnujẹ yi. Olè kọ kò rubọ. Nigbà to dijọ kan, ni Asúnu ba nyagbẹ,
kò lee lọ sibi kankan, kò lee lọ sibi isẹ, lóba joko silé. Wọn tini kó rubọ, ó siti rubọ pẹlu Ìtì-okùn-ágbá-
kan tiwọn sini kofi sinu ilé rẹ. Gbogbo ilé dakẹ. Ni Asúnu ba sapamọ dada, lóba yọ kẹlẹkẹlẹ jade lọ pe
awọn ara àdúgbo, wipe olè tide o, kiwọn gbà oun o, polè ti wọlé oun o. Niwọn ba sare lọ ki olè mọlẹ,
tiwọn fokùn-ágbá tofi rubọ dolè yi mọlẹ dada.

El ladron dijo que: ¡Porque el tenia que el hacer el sacrificio! Se negó rotundamente en hacer el
sacrificio. Un dia, Asúnu estaba malo, tenia dearia, no fue a ningún sitio, no fue al trabajo, se quedo en
casa. Asúnu ya hizo el sacrificio con un rollo de soga, después del sacrificio, se lo entregaron para
guardarlo en casa. La casa de Asúnu estaba en silencio absoluto. Asúnu salió de la casa con mucho
cuidado para llamar a las gentes del barrio, pidiéndoles ayudas y socorro para captura el ladron que ha
entrado en su casa. Las gentes del barrio le ayudaron a capturar el ladron, le ataron muy bien con la
soga del sacrificio que Asúnu tenia en casa.QUE:
Ìwòrì ò bẹrẹ tofi nyagbẹ’. (Ìwòrì no se agacha antes de hacer sus necesidades)

Awo Olè. (Awo del Ladron)

Lo díá fun Olè. (Adivino Ifa para el Ladron)

Wọn ni kolè ó rubọ (Dijieron al Ladron que debe hacer el sacrificio)

Olè kọ kò rubọ. (El ladron se negó en hacer el sacrificio)

Ó pawo leke. (Llamo a Awo mentiroso)

Ó pesu lolè. (Llamo a Esu ladron)

Ó wo ọrun yànyànyàn, bi ẹnipe ilẹ kòni sú mọ. (Miro al cielo tan brillante como que no iba a hacer
de noche)

ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá leleyii yoo molè, wipe ẹnikan nbẹ ti nji nkan rẹ, wipe asiri eleyii
yoo tu lọdun yi, ọwọ eleyii yoo si tẹ olè yi.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona va a captura
alguien que le esta robando, un ladron que le esta robando sus pertenecías será capturado este ano por
esta persona.

ẸSẸ KEJI

Ayẹwo Aseyọrí. (Investigar la prosperidad)


Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ, ko sini afọkànsin, kóma gbadura dada. To bajẹ babalawo ni eleyii. Ifa ni keleyii máà lọ
sibi isẹ ni gbogbo ọjọ ọsẹ-ifá, kó mase wahala kankan, ko mafi gbàdura. To bajẹ mùsulùmì leleyii, kóma fọjọ-
jïmọ se isinmi, kó mafi gbàdura. To bajẹ onigbàgbọ ni eleyii, kóma fọjọ-àìkú se ìsinmì ati adura, keleyii báse
asenilarí. Ko majẹ wipe eleyii yoo maa sisẹ lasan, làì lówó lọwọ, ko majẹ wipe eleyii kòni sakojọ ninu isẹ rẹ.
Ọlọrun kòni jẹki a sasedànù o. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer sacrificio, debe tener confianza y fe, seguir rezando muy bien. Si
es babalawo, que deja los días de ösëfá para discansar y rezar. Si es musluman, que deja los viernes
para discansar y rezar. Si es cristiano, que deja los domingos para discansar y rezar. Ifa dice que esta
persona debe discansar y rezar una vez a la semana, para que no sea un trabajador de toda la vida, sin
tener dinero, para que no sea un trabajador que no puede reunir nada de dinero de su trabajo.
Olodumare no nos va a dejar trabajar sin frutos. (Ase o). Ifa lo dice con este verso; QUE:

Ìwòrì ò bẹrẹ. (Ìwòrì no se agacho)

Tání jẹ fọjọ ẹdun roko. (¡Quién puede ir al campo el dia de ẹdun!)

A díá fun Amosuláká. (Se adivino Ifa para Amosuláká)

Eyiti nlọ oko àìlere lọdún. (El que iba al campo a trabajar sin frutos)

Amosuláká nlọ soko àìlere lọdún. Wọn ni kó rubọ o, kósi malọ soko nijọ ọsẹ-ifá o. Ọmọ babalawo ni,
ọmọ Ọrúnmìlà ni Amosuláká. Amosuláká kò gbọ ohun tiwọn sọ fun-un. Ojojumọ lóma nsisẹ, ó sisẹ-
sisẹ, kò rere nibẹ. Nigbà to dijọ kan, loba ranti wipe awọn babalawo siti sọ fun-un, wipe koun rubọ,
koun si malọ soko lọjọ ọsẹ-ifá o. Ó batun lọ sọdọ awọn babalawo to dafá, lóba rubọ. Bayi lóse bẹrẹ sini
nisinmi, tosi nilaarí. Nisẹ bẹrẹ sini kojọ, ó laseyọrí, adura rẹ ngbà. Ó loun kòni gbàgbe awọn babalawo
to dafá fun-un o. Ni ó ba nyin awọn babalawo rẹ, awọn babalawo rẹ si nyin Ifá. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni
babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ babalawo toun sọ:

Amosuláká iba al campo a trabajar en lo cual no iba a sacar frutos de sus trabajos. Le dijieron que debe
hacer el sacrificio y que no vaya al campo a trabajar los dias de ọsẹ-ifá. Amosuláká era hijo de
babalawo. Amosuláká era hijo de Ọrúnmìlà. Amosuláká no hizo caso a todos lo que le dijieron los
babalawos. Iba a trabajar en el campo todos los días y no sacaba ningún fruto de sus trabajos. Un dia,
le vino en la memoria lo que ya le habían dichos los babalawos que tenia que hacer el sacrificio y no
irse al campo a trabajar los días de ọsẹ-ifá. Enseguida se fue a consultarse con los babalawos otra vez y
hizo el sacrificio. Empezo a tener descansos, se volvió a ser una persona digna, empezó a tener frutos
en sus trabajo, prospero y sus deseos se cumplieron. Decia que no iba a olividar a los babalawos que le
consultaron Ifa. Estaba feliz, empezó a bailar y cantar, alabando a su awo y su awo alabandos a Ifa,
que asi mismo lo adivino y canto su babalawo; QUE:

Ìwòrì ò bẹrẹ. (Ìwòrì no se agacho)

Tání jẹ fọjọ ẹdun roko. (¡Quién puede ir al campo el dia de ẹdun!)

A díá fun Amosuláká. (Se adivino Ifa para Amosuláká)

Eyiti nlọ oko àìlere. (El que iba al campo a trabajar sin sacar frutos de sus
trabajos)

Ti nlọ bawọn mulẹ ìbudo. (Que iba a coger terreno para establecerse)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que hagan sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani nijẹbutu ire. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de bendición)

Ìjẹbutu ire laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En medio de celebración de bendición se encuentra uno a
los pies del rey de los Orisas).

Amosuláká. (Amosuláká)

Má mà sisẹ, ki ó gbàgbe ọjọ ẹdun. (No trabaja y te olivida los días de ẹdun)

Amosuláká o. (Amosuláká o)

Má mà sisẹ, ki ó má mà gbàgbe ọjọ ẹdun. (No trabaja y te olivida los días de ẹdun)

ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa leleyii gbọdọ maa sinmin, kosi maa gbadura. Toba jẹ babalawo
ni, keleyii màlọ sibi isẹ ni gbogbo ọjọ ọsẹ-ifá, kóma se wahala kankan, koma fi gbàdura. To bajẹ
mùsulùmì leleyii, kóma fọjọ-jïmọ se isinmi, kóma fi gbàdura. To bajẹ onigbàgbọ leleyii, kóma fọjọ-àìkú
se ìsinmì ati adura, keleyii báà sasenilarí lori isẹ rẹ.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que debe descansar y rezar. Si es
babalawo, debe dejar los días de ọsẹ-ifá para descansar y rezar. Si es musluman, debe dejar los viernes
para descansar y rezar. Si es cristiano, debe dejar los domingos para descansar y rezar, para que
prospera en su trabajo.

3·8. ÌWÒRÌ-ỌKÁNRÁN. (Ìwòrì ò rìn kàn,Ìwòrì Nìkànràn).

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgun ọta (Investigar el vencimiento de enemigo)

Ifá ni keleyii rubọ, kómá báà rogún ọràn alakoba, kiwọn ma darán seleyii lọrùn. Tiwọn basi darán sii lọrùn,
sungbọn tọràn yi ba sẹlẹ, kó rubọ bi yoo tise jade ninu ọràn yi, koma jẹpe ninu ọràn yi ni yoo rá si. Ifá ni kó rubọ
nibẹ, kó léè báà sẹgún. Ifá ni koun gbangban si sọrarẹ, kóma ma sọpe boun tito niyi, wipe awa lawa nibẹ, kiwọn
máà báà koba eleyii. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que no encuentrarse con gente que puede
llevarle a tener problemas, meterle en problema sin saber nada. Debe hacer el sacrificio para lograr
salir de esta trampa mortal cuando ocure, para que este problema no acabara con el totalmente. Ifa
dice que debe hacer el sacrificio para vencer. Ifa dice que el mismo debe tener cuidado con su actitud
de “soy yo y nadie mas” o actitud de “somos nosotros que estamos en poder y nadie mas”, para que no
le meten en problema. Ifa lo dice asi en este verso; QUE:

Ìwòrì ò rìn kàn. (Ìwòrì no llego a encuentrarlo en su camino)

Awo ilé Òlòrè-Agbọn kú ọ. (Awo de la casa de Òlòrè-Agbọn kú ọ)

Baba Òlòrè lo lálẹ. (El padre del Òlòrè es el dueño de la noche)

Iya Òlòrè lo làrọ. (La madre de Òlòrè es la dueña de la manana)

Òlòrè lo sọrọ kan kungbà-kungbá. (Òlòrè dijo una palabra/algo tan grande)

Ó wa se mọrànhìn-mọrànhìn. (Se extendió bastante)

A difá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Nijọ ti baba nbẹ larin ìpọnjú. (El dia que el padre estaba en el medio de apuros)

Ti baba nbẹ larin ẹjọ. (Que el padre estaba en medio de litigaciones/causas)

Kò sohun toju awo kìì rí o. (No hay nada que los ojos de awo no puede ver)

Kòsi ohun toju awo kìì kàn. (No hay nada que el awo no puede pasar)

Awo kìì saròka. (Awo no puede ser chismoso)

Ẹni tóba jawo kìì masọ bálá-bálá kakiri. Tó rí nkan, ti nwa lọsọ fẹlomiràn wipe lagbaja ma wa sọdọ mi,
ohun towa se niyi. Kẹnu-rẹ ma mọnu, kẹnu-rẹ ma dakẹ, ko sima pe ararẹ lawo. Ifa ni keleyii sọra, kọrọ
ẹnu-rẹ má kobá á. Wọn niki Ọrúnmìlà ó rubọ. O gbọ rúrú, ó rú. O gbọ tutu, ó tu. O gbọ ọhahaha ẹbọ
loju ọpọn, ó ha. Kò pẹ o, kò jìnnà. Ẹ wa wofá awo ki biti nsẹ.

Awọn awo siti sọ fun baba wipe kó rubọ, kó sọra fun ogún àkobá, tiwọn basi kobá á, kó lee bọ nibẹ. Ni
Ọrúnmìlà ba rubọ. Kò pawo leke. Kò pesu lole. O se gbogbo ohun tiwọn ni kóse. Ni ẹnikan bawa kẹjọ
ba Ọrúnmìlà, lóba sọ fẹniyii pe, bi yoo tise, bi yoo tise niyi. Nigbà tiwọn mu ẹniyi, lóba sọpe babalawo
kan lo kọun ni gbogbo nkan toun se.

Bayi niwọn sewa mu Ọrúnmìlà, loba dọràn si Ọrúnmìlà lọrùn. Sugbọn ọla pe ó ti rubọ, lojẹ kó bọ ninu
ọràn yi. Ifá ni keleyii sọra fun ọrọ akoba, tiwọn bawa fọrọ lọ ọ, kó mọ nkan toun yoo sọ sọrọ na. Kòsi
ohun toju awo kìì rí. Kòsi ohun toju awo kìì kàn. Awo kìì sọ isọkusọ. Ifá ni keleyii sọra fọrọ ẹnu-rẹ,
kómá báà fa ararẹ sinu wahala loju Ìwòrì-Ọrìkàn. Ó ni:

Una persona que es awo no puede esta hablandos por allí sin sentido, no puede ser un chismoso. Si un
awo ve una cosa y empieza a contarlo a las otras personas, que tal persona vino a verle, para hacer tal
cosa, no puede mantener secreto, no puede callarse la boca, ¡y dice que es un awo!. Un awo no puede
ser un chismoso. Ifa dice que esta persona debe tener muchos cuidados, para que su propia palabra no
le lleva a tener o meterse en problema. Dijieron a Ọrúnmìlà que debe hacer el sacrificio. Oio el sacrifcio
y lo hizo. Oio el ofrecimiento y ofreció. Hizo caso a lo que salió en el tablero de la adivinación de Ifa.
Pronto y no tan lejano. Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad

Los awos ya le habían dichos al padre “Ọrúnmìlà” que debe hacer el sacrificio. Dijieron que debe tener
muchos cuidados a lo que le puede llevar a tener problemas sin saber nada. Dijieron que debe hacer el
sacrificio para vencer cuando le meten en problemas sin saber nada. Ọrúnmìlà hizo sacrificio. No
llamo a awo mentiroso. Ni llamo a esu ladron. Hizo todos lo que le mandaron a hacer. Pues, vino una
persona a contar algo a Ọrúnmìlà. Despues de escucharle, Ọrúnmìlà le aconsejo que tenia que hacer
esta cosa asi y hacer aquel cosa asi. Cuando arestaron a esa persona, confeso que un babalawo le
aconsejo y le enseno como el tenia que hacer esta y aquellas cosas.

Enseguida fueron a arestar a Ọrúnmìlà también y se convertio en problema para Ọrúnmìlà. Gracias al
sacrificio que Ọrúnmìlà hizo, por eso logro salir del problema. Ifa dice que esta persona debe tener
cuidado por lo que le puede llevar a tener problema. Cuando le vienen a hablar o pedir consejo, debe
saber lo puede y lo no puede hablar. No hay nada que los ojos del awo no puede ver. No hay nada que
el awo no puede pasar. Un awo no puede hablar por hablar por allí sin sentido o ser un chismoso. Ifa
dice que esta persona debe tener muchos cuidados con lo que habla, para que no entra en problema
por su propio palabra en el signo de Ìwòrì-Ọrìkàn; QUE:

Ìwòrì ò rìn kàn. (Ìwòrì no llego a encuentrarlo en su camino)

Awo ilé Òlòrè-Agbọn kú ọ. (Awo de la casa de Òlòrè-Agbọn kú ọ)

Baba Òlòrè lo lálẹ. (El padre del Òlòrè es el dueño de la noche)

Iya Òlòrè lo làrọ. (La madre de Òlòrè es la dueña de la manana)

Òlòrè lo sọrọ kan kungbà-kungbá. (Òlòrè dijo una palabra/algo tan grande)
Ó wa se mọrànhìn-mọrànhìn. (Se extendió bastante)

A difá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Nijọ ti baba nbẹ larin ìpọnjú. (El dia que el padre estaba en el medio de apuros)

Ti baba nbẹ larin ẹjọ. (Que el padre estaba en medio de litigaciones/causas)

Kò sohun toju awo kìì rí o. (No hay nada que los ojos de awo no puede ver)

Kòsi ohun toju awo kìì kàn. (No hay nada que el awo no puede pasar)

Awo kìì saròka. (Awo no puede ser chismoso)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Ero Opo o, ero Ọffa. (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)

Ẹ wa wofá awo ki biti nsẹ. (Ustedes han vistos lo que el awo adivino se hizo realidad)

Kò sohun toju awo kìì rí o. (No hay nada que los ojos de awo no puede ver)

Kò sohun toju awo kìì kàn. (No hay nada que el awo no puede pasar)

Awo kìì saròka. (Awo no puede ser un chismoso)

ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá ni keleyii sọra fọrọ ẹnu-rẹ, kómá báà fa ararẹ sinu wahala loju
Ìwòrì-Ọrìkàn.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona debe tener
muchos cuidados con lo que habla, para que no entra en problema por su propio palabra en el signo de
Ìwòrì-Ọrìkàn.
ẸSẸ KEJI.

Ire (Bendicion)

Ifá yi tun nkọni lẹkọ wipe keleyii ó rubọ nibẹ. Kóma jà sọla. Kó rubọ nibẹ, koju-rẹ ma ríríkurì, kómá báà rakobá,
kómá báà rí wahala. Boya wọn fẹ gbe nkankan wa sinu ilú, tó wa nja wipe oun lo yẹ kiwọn gbee fun. Tikò ba
sọra nibẹ, yoo tibẹ bọ sinu wahala, wọn le sekú pẹniyii nibẹ. Ifá ni keleyii mà jà sipò kankan rara o. Kómà jà
sọla rara o. Kóni ÀGBEBỌ ADIẸ ati IGBÁ-ÓWÓ lẹbọ nibẹ, kóle báà sẹgún. Kómá jà sọla, kẹtọ tirẹ lee bọsii lọwọ.
Nibi tifa wa gba to fisọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa nos esta educando aquí. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona
no debe peliarse con nadie por por las herencias y las riquezas, para que no encuentra con algo no
deseado, para que no le meten en problemas. Puede ser que quieren trager algo a la ciudad y el
luchando o peliando que le toca coger lo que iban a trager a la ciudad, para que se lo entregan a el. Ifa
dice que si no mantenga calma o tener muchos cuidados, entrara en problema que le puede causar la
muerte. Ifa dice que esta persona no debe luchar o peliarse por ningún cargo en absoluto. Ifa dice que
esta persona no debe luchar o peliarse por las herencias y las riquezas. Ifa dice que debe tener
GALLINA en su sacrificio, debe tener DOS CIENTOS DE DINERO en su sacrificio para vencer. Esta
persona no debe luchar por las herencias para que sus derechos le llegan a sus manos con
tranquilidad. Ifa lo dice asi en este verso; QUE:

Ìwòrì ò rìn kàn. (Ìwòrì no llego a encuentrarlo en su camino)

A díá fun Majàsọlá. (Se adivino Ifa para Majàsọlá)

Eyiti nsọmọ Olorí Ìgbàwasẹ. (Que era el hijo del jefe del principio del mundo)

Ẹ májà sọla o. (Ustedes no pelian por la riqueza)

Ẹ májà sọrọ. (Ustedes no pelian por la riqueza)

Ta bajà sọla. (Si peliamos por la herencia o riqueza)


Ẹnu nii yọni. (Se lleva uno a tener problemas)

Wọn niki Majàsọlá ó rubọ. Wọn ni to bati setutu, wipe jẹjẹ nire rẹ yoo too lọwọ o. Kò pawo leke. Kò
pesu lole. O tun setutu nibẹ. Niwọn ba npinpò ninu ẹgbẹ wọn. Nigbà tó siti gbọ gbogbo ohun tawọn
babalawo wi tẹlẹtẹlẹ. Nse ló nwo wọn, kò sọrọ, kò gín. Funra gbogbo awọn ẹgbẹ-rẹ niwọn panupọ pe
kiwọn fun Majàsọlá nipò yi. Niwọn ba fun-un nipò yi. Ninu rẹ ba ndùn, ó nyin awọn awo rẹ, awọn awo
rẹ si nyin Ifá. Ifá si nyín Olodùmarè. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni awọn babalawo oun wi, bẹẹ gẹgẹ ni awọn
babalawo toun sọ:

Dijieron a Majàsọlá que debe hacer el sacrificio. Le dijieron que después de hacer el ofrecimiento, le
llegara sus bendiciones a sus manos con tranquilidad. Majàsọlá no llamo a awo mentiroso. No llamo a
esu ladron. Hizo todos lo que le mandaron a hacer. Estaban elegiendo un cargo/puesto en una
sociedad de su comunidad. Ya que sus babalawos le han avisado con antelación que no lucha por
ningún cargo/puesto. Majàsọlá se dedico a mirarles a los demás, no dijo nada en absoluto. Todas las
gentes de la sociedad decideron con unanimidad darle el cargo a Majàsọlá. Estaba feliz y empezó a
alabar a sus babalawos y sus babalawos alabandos a Ifa. Ifa alabando Olodùmarè; que asi mismo lo
adivinaron y cantaron sus babalawos; QUE:

Ìwòrì ò rìn kàn. (Ìwòrì no llego a encuentrarlo en su camino)

A díá fun Majàsọlá. (Se adivino Ifa para Majàsọlá)

Eyiti nsọmọ Olorí ohun gbogbo Ìgbàwasẹ. (Que era el hijo del jefe de todas las cosas del principio de
mundo)

Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani nijẹbutu ire. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de bendición)

Ìjẹbutu ire laa bani lẹsẹ Ọbarisa. (En el medio de las celebraciónes de bendición se encuentra
uno a los pies del rey de los Orisas).
Ẹ májà sọla o. (Ustedes no pelian por la riqueza)

Ẹ májà sọrọ. (Ustedes no pelian por la riqueza)

Ta bajà sọla. (Si peliamos por la herencia o riqueza)

Ẹnu nii yọni. (Se lleva uno a tener problemas)

ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii ó rubọ nibẹ, kó màjà sọla, kó rubọ nibẹ koju-rẹ marí ìríkurì, kómá báà rakobá,
kómá báà rí wahala.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer sacrificio, que no debe peliarse con nadie por las
herencias y las riquezas para que no encuentra con algo no deseado, para que no le meten en
problemas.

3·9. ÌWÒRÎ-ÒGÚNDÁ. (Ìwòrì-Ogún Tan), (Ìwòrì-Àwẹdá).

ẸSẸ KINNI:

“Ìwòrì Ogún tan ni feleyii” la npeni “Iwori-Ogunda”. Ifá ni gbogbo awọn tiwọn ngbogún teleyii. Ifa ni keleyii ó
rubọ nibẹ, wipe akoko to ti yoo sẹgún gbogbo wọn, ti gbogbo awọn ogún towa niwaju rẹ yoo tan. Ifá ni keleyii ó
rubọ nibẹ, wipe ayipada yoo de bẹniyi lorí gbogbo ìsoro tóni. Ifá lasìkò to ti gbogbo búbúrú ti nsẹlẹ seleyii yoo
dopín, tàyipada maa de. Ifá ni kó rubọ nibẹ. Gbogbo awọn tiwọn ngbogún teleyii, wọn yoo pada lẹyin rẹ, ti yoo
si sẹgún, toun nà yoo si nilaarí, ti yoo lówó lẹyin ìgbà tawọn ọta bati pada lẹyin rẹ. Ifá ni gbogbo ogun yoo kuro
niwaju rẹ patapata, tisẹ rẹ yoo si malọ dede, tọkàn rẹ yoo si balẹ. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Este signo de “Ìwòrì se termino la guierra para esta persona” es lo que llamamos “Iwori-Ogunda”. Ifa
dice que esta persona debe hacer sacrificio. Ifa dice que todas las gentes que están levatandos
guierras/batallas contra esta persona, Ifa dice que ya llego el momento que vencera a todos ellos
totalmente. Ifa dice que todas las guierras/batallas que esta persona tiene por delante se terminaran
totalmente. Ifa dice que debe hacer el sacrificio y se cambiaran sus situaciones de dificultades para
bien. Ifa dice que ya llego el momento que todas las cosas malas que le están pasandos llegaran a su fin
y sus situaciones cambiaran para bien, vencerá a sus enemigos, prosperara y tendrá dinero después de
vencer a los que están llevantandos guierras/batallas contra el, sus trabajos iran muy bien y lograra su
bienestar. Ifa lo dice con este verso; QUE:

Ogun tán. (La guierra se termino)

Ọtẹ tán. (La conspiración se termino)

Ẹniti nbami jà, ko siwọ. (El que esta peliando conmigo, que parra de peliarse
conmigo)

A díá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Nijọ ti baba nlọ Ifẹ Òdaiye. (El dia que el padre “Ọrúnmìlà” iba a Ifẹ Òdaiye)

Tawọn eniyàn yoo gbogun tii. (Que las gentes iban a levantar guierras/batallas contra
el)

Wọn niki baba ó rubọ, wipe ogun ti gbogbo awọn ọmọ-araiye gbe ti ọ yi, wipe yoo sẹgún. Baba se
gbogbo nkan tiwọn ni kóse. Bayi lo se sẹgun ọta. O dipe gbogbo bi kòse rorún sùn, ó bẹrẹ sini sùn
dada, wọn tun npe e funsẹ nibikan, ó tun nrówó gbà, ó nlówó lọwọ, lọkàn rẹ tun balẹ. Ni ó ba nyin
awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si nyin Ifá. Ni orin awo ba bọsii lẹnu. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni awọn babalawo toun
wi, bẹẹ gẹgẹ ni awọn babalawo toun sọ:
Dijieron al padre “Ọrúnmìlà” que debe hacer el sacrificio. Dijieron que todas las gentes del mundo que
están levantandos guierras/batallas contra el, vencerá a todos ellos. El padre hizo todos lo que tenia
que hacer y venció a sus enemigos. El padre“Örúnmìlà” que no podía dormir, empezó a dormir muy
bien. Le llamaban para trabajos en todos los sitios, ganaba dinero y estaba tranquilo. Estaba feliz y
empezó a alabar a sus babalawos y sus babalawos alabandos a Ifa. Abrio la boca y le salió la canción de
awo; Que asi mismo lo adivinaron y cantaron sus babalawos; QUE:

Ogun tán. (La guierra se termino)

Ọtẹ tán. (La conspiración se termino)

Ẹniti nbami jà, ko siwọ. (El que esta peliando conmigo, que parra de peliarse
conmigo)

A díá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Nijọ ti baba nlọ Ifẹ Òdaiye. (El dia que el padre “Ọrúnmìlà” iba a Ifẹ Òdaiye)

Tawọn eniyàn yoo gbogun tii. (Que las gentes iban a levantar guierras/batallas contra
el)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bawa larusẹgun. (Ifa ven a ayudarnos en levantamiento y aceptación de


nuestro sacrificio)

Arusẹgun laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En medio de levantamiento y aceptación de sacrificio
se encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Njẹ ta ba leeni; (¡Si están preseguiendo a uno!)

Ta ò ba bani. (Y no pueden coger a uno)

Nse laa pada lẹyin ẹni. (Lo que hay que hacer es rendirse de las
presecuciones)

Njẹ ta ba leeni; (¡Si están preseguiendo a uno!)


Ta ò ba bani. (Y no pueden llegar a uno)

Nse laa pada lẹyin ẹni. (Lo que hay que hacer es rendirse de las
presecuciones)

ASẸ-IFÁ: Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ. Ifa ni wipe tiwọn bati nlee.. lee…, tiwọn kòba beleyii, wọn yoo pada
lẹyin rẹ ni, nisẹgun yoo bade.

ASẸ IFÄ:- Ifa dice esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que después de que las gentes le
persiguen tanto y no pueden cogerle, se rendiran, le dejaran en paz y le llegara el vencimiento.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun ọta (Investigar el vencimiento de enimigo)

Ifá ni keleyii rubọ isẹgun, wipe gbogbo ibi yoo sẹ patapata. Ifá logun nbọ. Ifá niwọn ngbogun bọwa beleyii. Kó
rubọ, kólè báà sẹgun, tiwọn bagbogun na de loju “Ìwòrì- Gbogun de” yi. Oun na lo njẹ “Ìwòrì Ogbun tan” ati
“Ìwòrì Ògúndá”. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o loju Ìwòrì- Gbogun de. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio para el vencimiento, Ifa dice que todas las maldiciones
se vencerán totalmente. Ifa dice que le va a venir a esta persona batallas/guierras. Ifa dice que las
gentes van a venir a levantar batallas/guierras contra esta persona. Ifa dice que cuando llegan estas
batallas, que debe hacer sacrificio para vencer estas batallas en el signo de “Ìwòrì llego con la guierra”
también se llama“Ìwòrì, se termino la guierra” y “Ìwòrì se venció la guierra”. Ifa lo dice asi con este
con este verso en el signo de “Ìwòrì, se termino la guierra”; QUE:
Njẹ ta ba leeni; (¡Si están preseguiendo a uno!)

Ta ò ba bani. (Y no pueden coger a uno)

Nse laa pada lẹyin ẹni. (Lo que hay que hacer es rendirse de las presecuciones)

Ìwòwò tiri wò. (Ìwòwò tiri wò)

Ogun tán. (La guierra se termino)

Ọtẹ tán. (La conspiración se termino)

Ẹniti nbami jà, ko siwọ. (El que esta peliando conmigo, que parra de peliarse
conmiigo)

A díá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Nijọ tiwọn ngbogún ree Ilú Ìlárá. (El dia que iban de guierra a la ciudad de Ìlárá)

Ẹ má mà kogun timi o. (Ustedes no levantan guierras contra me)

Ogun ò ribi Iyán. (La guierra no es como pasta de yame)

Ogun ò ribi ọkà. (La guierra no es como pasta de yame seca)

Ẹ má mà kogun jami o. (Ustedes no levanta guierra contra me)

ASẸ IFÁ:- Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ, kiwọn máà báà kogun jeleyii loju Ìwòrì Ogun tan.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que las gentes no levantan
guierras/batallas contra esta persona en el signo de “Ìwòrì se termino la guierra”.
3·10. ÌWÒRÌ-ỌSÁ. (Ìwòrì ò ja’wùsá), (Ìwòrì Wọsá).

ẸSẸ KINNI.

Ifá ni keleyii o setutu, kósi lọ ni suru dada. Ifá lọrọ kàn yoo sẹlẹ, tọrọ na yoo le, ti yoo tobi. Ifa ni wipe awọn kan
yoo ma bara wọn jà, tiwọn yoo ti parí rẹ titi, tikò nise parí. Ifá ni kẹni tó dafá yi o setutu, Ifa ni wipe oun ni yoo
parí ọrọ yi. Ifá lawọn kan yoo tun ma binu seleyii wipe soun lowa mọrọ pari ní, wipe bawó ni tirẹ se jẹ. Wọn
yoo si tun bẹrẹ sini dìtẹ meleyii. Ifá ni keleyii ma binu rara, kó ni suru dada, wipe onisuru ni njogun ohun
gbogbo. Ifá ni teleyii ba binu, ti nkan ba bajẹ, kòni latunse o. Ifá ni keleyii o má mà gbìjà ararẹ rara o, kosi ma
gbìjà ẹnikankan rara o. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y ofrecimiento. Ifa dice que esta persona debe tener
bastantes pacencias. Ifa dice que va a ocurir un asunto bastante fuerte y de grande dimensión. Ifa dice
que unas gentes van a estar discurtiendos o peliandose entre ellos, sin que haya maneras de parrar o
solucionarlo, después de muchos intentos en solucionarlo. Ifa dice que este consultante debe hacer el
sacrificio. Ifa dice que el será la persona que va a solucionar esas discurciones o peliar. Al raíz de esto,
Ifa dice que otras personas se enfardaran con este consultante diciendo que: ¡Si el solamente es el que
sabe solucionar las cosas!, ¡quien es el! Y van a empezar a conspirar contra este consultante. Ifa dice
que no debe enfadarse para nada y que debe tener bastantes paciencias. Ifa dice que: “el que tiene
paciencia es el que disfruta de todas las cosas” Ifa dice que si se enfada este consultante, el asunto no
tendrá solución ninguno jamas. Ifa dice que este consultante no debe peliar por si mismo, ni debe
peliar por nadie para nada en absoluto. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Àbàtà se jẹgbẹ gbọkọ. (La laguna movio sus olas para llevar/hundir el barco)

A difá fun Ọrunmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrunmìlà)

Baba nlọ ree gbà Okùn-Aiye mu. (El padre “Ọrunmìlà” iba a coger la soga del mundo)
Ẹbọ niwọn ni ó se. (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Ẹ rọra fẹsọ se. (Ustedes hacen las cosas con cuidados)

Ẹ rọra f’ẹsọ j’aiye. (Disfrutan de la vida con cuidados)

Bi aiye ba ja. (¡Si el mundo se rompe!)

Oniso kò si o. (No hay quien que lo puede amarar)

Ẹ rọra f’ẹsọ se. (Ustedes hacen las cosas con cuidados)

Ẹ rọra fẹsọ j’aiye. (Disfruta de la vida con cuidados)

Aiye d’ẹsọ-ẹsọ. (El mundo se ha convertido en cuidado)

Aiye dẹhẹhẹ. (El mundo se ha convertido en fragilidad)

Bi o ba lówó lọwọ. (Si tienes dinero)

Ẹ se ówó niwọn-niwọn. (Ustedes usan el dinero con moderaciónes)

Ówó dẹhẹhẹ (El dinero se ha convertido en fragilidad)

Ówó d’ẹsọ-ẹsọ. (El dinero se ha convertido en cuidado)

Bi o ba nilé. (Si tienes casa)

Ẹ selé niwọn-niwọn. (Usa la casa con moderación)

Ilé dẹhẹhẹ. (La casa se ha convertido en fragilidad)

Ilé d’ẹsọ-ẹsọ. (La casa se ha convertido en cuidado)

Bi o ba n’ire gbogbo. (Si teneis todas las bendiciones)

Ẹ sere gbogbo niwọn-niwọn. . (Ustedes usan todas las bendiciones con moderaciónes)

Ire gbogbo dẹhẹhẹ. (Todas las bendiciones se han convertidos fragilidades)

Ire gbogbo d’ẹsọ-ẹsọ. (Todas las bendiciones se han convertidos en cuidados)


ASẸ IFÁ:- Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ. Ifá ni keleyii maa gbe ìgbesi aiye-rẹ, kawọn kan máà báà sẹleyii
lorí nibẹ. Ifa niwọn yoo maa fín eleyii niràn, tiwọn yoo ma se buburu sii, sugbọn kò gbọdọ binu rara o,
nitoripe toun ba binu, ohun ti yoo seleyii, yoo buru ju ohun tiwọn fẹ se fun-un lọ, ti nkan ba siti bajẹ,
kòni latunse. Kóni suru dada o.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona debe dedicarse a
vivir su vida, para que no le matan. Ifa dice que le van a falta respeto, van a comportarse mal con el.
Ifa dice que esta persona no debe enfadarse para nada. Ifa dice que si esta persona se enfada, le pasara
cosas peores que lo que les quieren hacer a el y no tendrá solución o areglo ninguno. Ifa dice que debe
tener pacencia bastante.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo ẹjọ. (Investigar la litigación)

Ifá yi tun nkọwa lẹkọ wipe keleyii nisuru dada o. Kóma sọrọ ti yoo gbee lọ sẹwọn. Kó má mà sì ọrọ sọ. Ki ó sọra
fun gbogbo ọrọ toba njade lẹnu rẹ. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Este Ifa nos esta educando, que esta persona debe tener bastante pacencia/cuidados. Que no debe
hablar algo que le puede llevar a la cárcel. Que no habla lo que no debe hablar, que debe controlarse
con lo que habla. Debe tener muchos cuidados con lo que sale de su boca. Ifa lo dice asi con este verso;
QUE:

Onì sá. (Hoy se escapo)


Ọlá sá. (Manana se escapo)

A díá fun Alabahún Ìjàpa. (Se adivino Ifa para la tortuga)

Eyiti yoo sọrọ tikò sunwọn lẹnu. (El que iba a hablar lo que no debia hablar)

Ti yoo si koba ararẹ. (Y que iba a meterse en problema con sus propios palabras)

Wọn niki Alabahún Ìjàpà sọrarẹ, kósi rubọ ẸYẸLE-MẸRINDINLOGUN nibẹ, kóni ỌPỌLỌPỌ ÓWÓ lẹbọ
nibẹ, kọrọ ẹnu-rẹ máà báà kó baa, debi wipe wọn yoo dì lokùn. Alabahún pawo leke. O pesu lole. Kò
rubọ. Idi niyi tiwọn fi nfokùn di Alabahún lati oko walé titi dọjọ oni. Tiwọn bati fokùn di Alabahún,
kòni lee sá mọ, kòni agbara kankan mọ. Alabahún sọrọ tikò sunwọn lẹnu, ti yoo si sá roko. Nigbàti ó
doko, lówa nráti gbogbo Ifá tawọn babalawo da fun-un. Awọn babalawo ni, sébi awọn sọ fun ọ, iwọ
Alabahún pe kó rubọ, seni ó nsa kakiri. Onì sá. Ọlá sá. Ó ni lotitọ loun nsá.

Dijieron a la tortuga que debe tener muchos cuidados. Dijieron que debe tener DIECISEIS PALOMAS
en su sacrificio, debe tener MUCHO DINERO en su sacrificio, para que su propio palabra no le lleva
hasta amararle con la cuerda. La tortuga llamo a awo mentiroso, llamo a Esu ladron y no hizo el
sacrificio. Esta es la razón de que se amara la tortuga desde el campo para llevarlo a la casa, hasta el
dia de hoy. Cuando se amara la tortuga, ya no puede hacer nada en absoluto, ya no puede escapar, no
le quedara ningúna fuerza. La tortuga hablo lo que no debia hablar y se escapo al campo. Cuando llego
al campo, empezó a recordarse de lo que le han adivinados los babalawos. Los babalawos le
contestaron que: ¡Si ya te lo hemos dichos con antelación! Que debes hacer el sacrificio y empezaste a
escapar por allí. Hoy se escapo. Manana se escapo. La tortuga contesto, que era la verdad que el estaba
escapando por allí.

Onì sá. (Hoy se escapo)

Ọlá sá. (Manana se escapo)

A díá fun Alabahún Ìjàpa. (Se adivino Ifa para la tortuga)

Eyiti yoo sọrọ tikò sunwọn lẹnu. (El que iba a hablar lo que no debia hablar)

Ti yoo si koba ararẹ. (Y que iba a meterse en problema con sus propios palabras)
Ti yoo si sá roko. (Y que iba a escparse al campo)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó kọ, kò rubọ. (Se negó en hacer el sacrificio)

Esu aisẹbọ (La tentación de no hacer el sacrificio)

Ẹgba aiteru (La paralisis de no apasiguar a esu pronto)

Ohun lomu kiwọn ma fokun de Alabahún Ìjàpa (Por eso se amaran la tortuga con la soga)

ASẸ IFÁ:- Ifá ni keleyii rubọ nibẹ, kó sọ ọrọ ẹnu ararẹ, kiwọn máà báà deleyii lokùn lọsi ọgba ẹwọn.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, que debe tener muchos cuidados con lo que
habla, para que no le llevan a la cárcel esposado.

3·11. ÌWÒRÌ-ÌKÁ. (Ìwòrì-Àyọká).

ẸSẸ KINNI.

Ire ọmọ. (Bendicion de hijo)


Ifá lobinrin kan niyi, kò lọmọ. Toba sọkunrin ni, oun na kò lọmọ, sugbọn ó lówó lọwọ loju Ìwòrì Àyóká. Ifá ni
keleyii dọrọ ówó nini duro na, tóba fẹ bimọ. Ifá niyànju beleyii yoo tise rówó lo nse nigbogbo ìgbà. Ifá ni eleyii ti
fẹràn ówó jọmọ lọ. Ifá ni kó fọlà silẹ na, kó wọmọ, wipe mejeji kò léè sese. Keniyàn ma wówó, kotún loun yoo
bimọ. Ifá ni kòse se bẹẹ. Ifá ni keleyii rubọ ọmọ loju Ìwòrì Àyọká. Ifá lọmọ ẹni lọlà ẹni toba dọjọ alẹ. Ifá ni
teleyii ba nlọ si gbogbo orílẹ ede loni lọla, kòni ráyè bimọ. Ifá ni keniyàn bimọ ti yoo jogún rẹ lo dara, ọmọ ẹni
lẹsọ ẹni. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o loju Ìwòrì-Àyọká. Ifa na sọ pe:

En el signo de Ìwòrì Àyóká. Ifa dice que hay una mujer que no tiene hijo. Si el consultante es un
hombre, el hombre no tiene hijo. Pero esta persona tiene dinero. Ifa dice que esta persona debe dejar
de buscar dinero y concentrarse en como puede tener hijo. Ifa dice que esta persona esta luchando
para conseguir dinero cada momento. Ifa dice que le gusta mas tener el dinero que tener hijo. Ifa dice
que las dos cosas no pueden ser al mismo tiempo, tener dinero y tener hijo al mismo tiempo. Ifa dice
que esta persona debe dejar de buscar el dinero y concentrarse en como puede tener hijo. Ifa dice que
esta persona debe hacer el sacrificio para tener hijo en el signo de Ìwòrì Àyọká. Ifa dice que el hijo de
uno es la riqueza/tesoro de uno el dia de mañana. Ifa dice que esta persona va de un país a otro cada
momento, no tiene tiempo para tener hijo que puede heredarle el dia de mañana. Ifa dice que el hijo de
uno es el tesoro de uno. Ifa lo dice asi con este verso en el signo de Ìwòrì Àyọká; QUE:

Ta bada Ìwòrì Àyọká. (Si nos sale el signo de Ìwòrì Àyöká en la consulta de Ifa)

Ẹrin laa rín kaiye. (Debemos reírnos por todo el mundo)

A difá fun Onijẹsha-Modù-Àrè. (Se adivino Ifa para Onijẹsha-Modù-Àrè)

Tiwọn ni kiwọn fẹbọ ọlà silẹ. (Le dijieron que deja de hacer el sacrificio para las riquezas)

Ẹbọ ọmọ ni kiwọn se. (Que debe concentrarse en hacer el sacrificio para tener hijo)

Awọn árá Ijẹsa-Modù-Àrè, onisowo niwọn, sugbọn wọn kò bimọ. Niwọn balọ sókó awo wipe sáwọn na
léé bimọ. Ifá niwọn yoo bimọ, sugbọn kiwọn fọnà ólówó silẹ na, kiwọn dọnà ówó duro na. Kiwọn
setutu, kiwọn sìmà lọ sọtùn lọ sosi mọ. Ifa ni wipe wọn yoo dọlọmọ. Niwọn ba rubọ. Lọmọ bade.
Niwọn njo, niwọn nyọ, wọn nyin awọn awo, awọn awo si nyin Ifa. Wọn ni; bẹẹ gẹgẹ ni awọn babalawo
tawọn wi, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo tawọn sọ:
Las gentes de Ijẹsa-Modù-Àrè son comerciantes, pero no tienen hijos. Se fueron a consultarse con Ifa
de ¡como pueden tener hijos!. Ifa dice que tendrán hijos, pero deben dejar de preocuparse en las
riquezas para tener hijos. Ifa dice que deben hacer el sacrificio y ofrecimientos; y no irse de un sitio a
otro cada momento. Ifa dice que se convertirán en padres de hijos. Hicieron el sacrificio y tuvieron
hijos, estaban felices, empezaron a bailar y cantar, alabandos a sus babalawos y sus babalawos
alabandos a Ifa; Que asi mismo lo adivinaron y cantaron sus babalawos; QUE:

Ta bada Ìwòrì Àyọká. (Si nos sale el signo de Ìwòrì Àyöká en la consulta de Ifa)

Ẹrin laa rín kaiye. (Debemos reírnos por todo el mundo)

A difá fun Onijẹsha-Modù-Àrè. (Se adivino Ifa para Onijẹsha-Modù-Àrè)

Tiwọn ni kiwọn fẹbọ ọlà silẹ. (Le dijieron que deja de hacer el sacrificio para las riquezas)

Ẹbọ ọmọ ni kiwọn se. (Que debe concentrarse en hacer el sacrificio para tener hijo)

Wọn si gbẹbọ nibẹ, wọn rubọ. (Lo hicieron)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani larusẹgún ọmọ. (Ifa ven a ayudarnos en el levantamiento y aceptación de nuestros
sacrificios de vencimiento de hijo)

Àrusẹgún ọmọ laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En el medio del levantamiento y aceptación de nuestros
sacrificios del vencimiento de hijo se encuentra uno a los pies del rey de los Orisas)

ASẸ IFÁ:- Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ. Ifá ni teleyii bati fọrọ ọlà silẹ, yoo bimọ, Kó sẹbọ ati etutu.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que si esta persona deja de
preocuparse por las riquezas, Ifa dice que tendra hijo. Ifa dice que debe hacer el sacrificio y
ofrecimientos.
ẸSẸ KEJI.

Ire ire-gbogbo (Todas las bendiciones)

Ifá niyawo eleyii yoo fii silẹ. Ifa nikó setutu nibẹ. Kó sima kanju wipe oun fẹ lówó. Ifa ni wipe gbogbo ire leleyii
yoo ni patapata, yoo lówó, yoo lọmọ, yoo lọla, yoo ni àlùbaríkà. Ifá ni kó rubọ nibẹ. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re
o loju Ìwòrì Àyọká. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que la mujer de esta persona le va a dejar. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y
ofrecimiento. Ifa dice que esta persona no debe tener prisa para tener dinero. Ifa dice que esta persona
tendrá todas las bendiciones, tendrá dinero, tendrá hijo, tendrá riquezas y prosperidades. Ifa dice que
debe hacer el sacrificio. Ifa lo dice asi con este verso en el signo de Ìwòrì Àyọká; QUE:

A o sa o ró o (A o sa o ró o)

Àsà ni sawo kòro. (Àsà es el awo de kòro)

A difá fun Ìwòrì Àyọká. (Se adivino Ifa para Ìwòrì Àyọká)

Eyiti nse Oluwó Ìsà-lọrún. (Que era el Oluwó en el cielo)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Emi ò sawo osì mọ. (Yo ya no hago el awo de las pobrezas)

Ki nma bosì kú laiye temi. (Para que no muero con las pobrezas en mi vida)

Ìwòrì Àyọká. (Ìwòrì Àyọká)

Abi ìsawo jìngìnnì. (Que sabe como hacer el awo completo)


Wọn niki Ìwòrì Àyọká ó rubọ. Ifá yi leleyii yoo se là. Toba jọmọ babalawo, kólọ kofá. Ti kìì basi sọmọ
babalawo, kó sunmọ awọn babalawo, kiwọn SẸFÁ FUN-UN. Ifá nire gbogbo ni yoo ni, yoo là, ẹmi-rẹ
yoo si gùn dada. Ìwòrì Àyọká rubọ tan, nire gbogbo bade. Lóba nyin awọn awo rẹ, awọn awo rẹ si
nyin Ifá, ẹsẹ tó gbe, orin awo lo bọsii lẹnu. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo
toun sọ:

Dijieron a Ìwòrì Àyọká que debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona va a ser rico con este
signo que le ha salido. Si esta persona es hijo de babalawo, debe aprender Ifa y dedicarse al oficio de
babalawo. Si no es hijo de babalawo, debe acercarse a los babalawos y RECIBIR UNA MANO DE IFA.
Ifa dice que tendrá todas las bendiciones y tendrá larga vida. Ìwòrì Àyọká hizo sacrificio y le llego
todas las bendiciones. Ìwòrì Àyọká empezó a alabar a sus babalawos y sus babalawos alabandos a Ifa.
Ìwòrì Àyọká abrio la boca y le salió la canción de awo, que asi mismo lo adivinaron y cantaron sus
babalawos; QUE:

A o sa o ró o (A o sa o ró o)

Àsà ni sawo kòro. (Àsà es el awo de kòro)

A difá fun Ìwòrì Àyọká. (Se adivino Ifa para Ìwòrì Àyọká)

Eyiti nse Oluwó Ìsà-lọrún. (Que era el Oluwó en el cielo)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Emi ò sawo osì mọ. (Yo ya no hago el awo de las pobrezas)

Ki nma bosì kú laiye temi. (Para que no muero con las pobrezas en mi vida)

Ìwòrì Àyọká. (Ìwòrì Àyọká)

Abi ìsawo jìngìnnì. (Que sabe como hacer el awo completo)

Ó nse: ORIN: (CANCION)


Ìwòrì Àyọká. (Ìwòrì Àyọká)

Abi ìsawo jìngìnnì o. (Que sabe como hacer el awo completo)

Ìwòrì Àyọká. (Ìwòrì Àyọká)

Abi ìsawo jìngìnnì o. (Que sabe como hacer el awo completo)

Emi ò sawo osì mọ. (Yo ya no hago Awo de pobreza)

Ki nma ba Òsì kú laiye temi. (Para que no muero con pobreza en mi vida)

Ìwòrì Àyọká. (Ìwòrì Àyọká)

Abi ìsawo jìngìnnì o. (Que sabe como hacer el awo completo)

ASẸ IFA:- Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ. Ifa ni wipe òsì yoo fii silẹ, yoo dólówó, yoo dọlọlà, ẹmi-rẹ yoo si
gùn loju Ìwòrì Àyọká.

ASẸ IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que dejara de ser pobre, tendrá
dinero, tendrá riquezas y tendrá larga vida en el signo de Ìwòrì Àyọká.

3·12. ÌWÒRÌ-ÒTÚRÚPỌN. (Ìwòrì-Tútù).

ẸSẸ KINNI.
Ayẹwo ọfọ (Investigar las pedidas)

Ifä ni keleyii ó sọrarẹ dada. Kó rubọ nibẹ, kósi súnmọ awọn babalawo kiwọn jewé Ifá fun-un, komá
báà jẹpe obinrin ti yoo fẹ laiye rẹ, obinrin tẹmi-rẹ kòni gùn ni. Toba sijẹ pobinrin lo dafa yi, komá báà
jẹpe ọkunrin tẹmi-rẹ kòni gùn ni yoo fẹ. Ifá nkeleyii nilọ lorí ọkọ nini tabi ìyawo fifẹ. Kó rubọ nibẹ, kósi
kún fadura, kọràn rẹ le dayọ, kiwọn le jogbọ jatọ.

Ifá tun nkeleyii nilọ loju Ìwòrì-Tútù, wipe keleyii rubọ nibẹ, kó setutu, kawọn babalawo jewé Ifá fun
un, kómá báà jẹgbese lorí ọja ti yoo rà. Tikò ba rubọ kóto ràjà yi, gbèsè ni yoo mu bọ nibẹ, ti yoo si
peleyii lẹkún. Ọjà ti a o fówó arawa rà, ti yoo pani lẹkún, Ifá kòni jẹki a ríí, Òdùmàrè kòni jẹki a ríí.

Ifá sitún nsọ feleyii wipe ibikan ló nlọ, komá báà jẹpe wahala ti yoo rí nibẹ, wọn kòni jẹki ó pada silé rẹ
mọ. Ifá nkeleyii nilọ, wipe keleyii ó rubọ asise nibi ìrìn-àjò, nibi isẹ-rẹ loju Ìwòrì Tútù. Ifá ni teleyii bati
rubọ, gbogbo ire ti nba nrí, kòni fisin ẹni-ẹlẹni o. Kòni fisin orí-olorí. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o.
Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe tener cuidado bastante. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio
y acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa, para que la mujer que iba a
casarse con ella no sea una persona de corta vida. Si es una mujer que ha hecho esta conslta, para que
el hombre que iba a casarse con el, no sea un hombre de corta vida. Ifa le esta llamando la atención a
esta persona sobre su vida de casamiento con hombre o mujer. Ifa dice que debe hacer el sacrificio,
seguir rezando para tener una vida feliz y para que pueden vivir juntos hasta vejez.

Ifa le esta llamando la atención a esta persona en el signo de Ìwòrì-Tútù que debe hacer el sacrificio y
ofrecimiento, acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa, para no aruinarse en
las mercancías que va a comprar para su negocio o comercio. Ifa dice que si esta persona no hacer el
sacrificio antes de comprar las mercancías, entrara en deudas con esas mercancías que quiere
comprar, se arepentira y llorara. Ifa pide a Òdùmàrè que no nos deja entrar en deudas. (Ase o). Que Ifá
no nos permite entrar en deudas. (Ase o).

Ifa le esta diciendo a esta persona también que quiere ir a un sitio, para que no tenga problema en su
viaje que no le va a permitir volver a su casa. Ifa le esta llamando la atención a esta persona que debe
hacer el sacrificio por equivocaciones, omisiones y erorres antes de enbarcarse en ese viaje de su
negocio o comercio en el signo de Ìwòrì Tútù. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio para
que todas las bendiciones que le llegan será para sus propios beneficios, para que no gastarlo en cuidar
o mantener otras personas, para que no trabaja para los demas. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Èkìtì bàbàbà. (Èkìtì bàbàbà)

A difá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Nijọti baba ntu owo-ẹru jọ. (El dia que el padre “Ọrúnmìlà” estaba reuinendose dinero
para comprar esclavo)

Ti yoo si pàdanù ẹrú. (Que iba a peder la escalva)

Ọrúnmìlà ntu owó ẹru jọ, lati rẹrú, ẹrú-binrin losi fẹ rà. Wọn niki ó rubọ. O kọ, kò rubo. Ló balọ rẹrú,
tosi mẹrú wale. A si bufun Esu-Ọdàrà, ti nse ọrẹ Ọrúnmìlà. Nijọ kẹta, lẹrú ti Ọrúnmìlà rà ba kú. Ibiyi
nifá ti nsọ feleyii wipe obinrin ti yoo fẹ, ẹlẹmi kukuru ni yoo jẹ. Ọjọ kẹta ti Ọrínmìlà fẹ ìyawo wolé,
nìyawo kú.

Ni gbogbo árá ilé Ọrúnmòlà ba nsúnkún, ọfọ sẹwọn nibẹ. Inu Ọrúnmìlà kò dùn, Esu ti sọrẹ Ọrúnmìlà
ba wọlé de; ó ni, kínní o wa sẹlẹ tiwọn nsúnkún. Ọrúnmìlà lẹrú toun rà nijẹta lo kú. Esu niwọ kò dafá
sohun tiwọ lọ rà ni ati wipe iwọ kò rubọ. Ọrúnmìlà loun dafá, wipe oun sẹsẹ nwọna ati rubọ ni. Esu
bani kólọ rubọ, kóse gbogbo ohun tawọn babalawo ni kóse.

Wọn sini kóni EWURẸ lẹbọ nibẹ, wọn ni kóni ỌPỌLỌPỌ ÓWÓ lẹbọ nibẹ, wipe ajé-rẹ yoo yọ. Nigbàti
Ọrúnmìlà rubọ tan. Ni Esu ba tọju okú yi dada, ó filẹkẹ ati goolù sokú lọrùn, ó wee lasọ, ó wee ni gèlè,
ó se lọsọ, ó bọ ni bàtà, ó se gbogbo rẹ. Nigbà tó se lọsọ tan. Lóba gbe lọ sorita-kan lẹgbẹ ọjà ti gbogbo
aiye nna. O si gbee joko dada, tawọn eeyàn kò mọpe o tikú. Ni Esu balọ sapamọ sibikan, tó nwo
gbogbo nkan ti nsẹlẹ, bawọn eniyàn ti nkọja niwọn nki okú yi, tikò dahun, niwọn ba bẹrẹ sini sa fokú.

Ọrúnmìlà estaba reuinendo dinero para comprar esclavo, iba a comprar una hembra esclava. Dijieron
a Ọrúnmìlà que debe hacer el sacrificio. Ọrúnmìlà se negó en hacer el sacrificio. Ọrúnmìlà se fue a
comprar la esclava y la trajo a casa. Tambien se adivino para Esu-Ọdàrà que era el amigo de Ọrúnmìlà.
El tercer dia, la esclava de Ọrúnmìlà se murió. Aquí es donde Ifa esta diciendo a esta persona que la
mujer que iba a casarse con ella, es una mujer de corta vida. El tercer dia que Ọrúnmìlà se caso con su
esposa y la llevo casa, ella se murió.
Todas las familiares de Ọrúnmìlà estaban llorandos por la pedida que han sufrido. Ọrúnmìlà estaba
triste. Esu que es el amigo de Ọrúnmìlà entro en la casa y pregunto ¿Por qué estaban llorandos?
Ọrúnmìlà le contesto que la esclavo que el compro antes de ayer se murió. Esu pregunto a Ọrúnmìlà
¿Por qué no ha consultar a Ifa y hacer el sacrificio antes de comprar la esclava? Ọrúnmìlà contesto a
Esu que consulto a Ifa y estaba buscando medio para hacer el sacrificio. Esu le dijo que vaya a hacer el
sacrificio y todos los que los Babalawos le mandaron a hacer.

Le dijieron a Ọrúnmìlà que debe tener UNA CHIVA en su sacrificio, que debe tener MUCHO DINERO
en su sacrificio. Que Ọrúnmìlà iba a recuperar el dinero invertido en la esclava muerta. Ọrúnmìlà hizo
el sacrificio y todos lo que le mandaron a hacer. Esu cogió la esclava muerta, la lavo bien, puso cuentas
y oro en su cuello, la vestio con ropa y zapatos. Esu llevo la esclava muerta a un tres cruces cerca del
mercado que iban todas las gentes de la ciudad y la sento bien. Esu se escondió en un sitio mirando
todos que pasaban. Todas las gentes que pasaban no sabían que era una persona muerta, la saludaban
y ella no contestaba. Empezaron a correr que es una persona muerta.

Bi Ajé se nbọ pelu awọn igba-ẹrú-rẹ. Nigba tó debi toku wa, kò mọpe o tikú, lóba nbere lọwọ okú pe;
‘Éló ni kínní yi, éló ni kínní yi’. Nigbà tokú kò dahun. Ninu babi Ajé, loba lagi mokú lorí, lokú ba subu
lulẹ gbomù. Bayi lesu se jade, ó ni: ‘iwọ Ajé, ẹrú Ọrúnmìlà niwọ mapa yi’. Ajé ro poun loun pokú ni.
Lóba bẹrẹ sini bẹ Esu pe kómá binu. Esu ni rara o, wipe awọn yoo jọ dọdọ Ọrúnmìlà ni. Ajé loun yoo
fikan ninu awọn ẹrú oun dipo. Esu ni rara. Ajé loun yoo fun-un lẹrú meji. Esu ni rara. Ajé loun yoo fi
gbogbo igba-ẹrú oun dipo. Esu ni rara. Ajé ni kómu-un pẹlu gbogbo ẹrú oun dipo. Esu ni rara. Bayi ni
Ajé pẹlu gbogbo awọn ẹrú-rẹ se tẹle Esu lọ sọdọ Ọrúnmìlà. Nigbà tesu siti delé Ọrúnmìlà tẹlẹ, tóti ba
Ọrúnmìlà daro pajé rẹ yoo yọ. Bayi ni Ajé ati gbogbo awọn ẹrú-rẹ si dẹrú Ọrúnmìlà titi doni oloni.

Ibi tifá ti nsọ feleyii wipe ko sọra, nibi ìrìn-àjò to fẹ lọ niyi. Ko rubọ nibẹ, komá báà jẹ ìrìn-àjò àìni pada
walé. Kómá báà dẹrú ẹgbẹ-rẹ, kómà báà sasedanu. Ajé kọ kò rubọ nibẹ. O si rìnrìn àìpada walé, ó
sowo asedanu, tosi dẹrú Ọrúnmìlà titi doni oloni. Bayi lajé se dele Ọrúnmìlà.

Ifá ni keleyii o rubọ nitorí owo asedanu. Ifá ni keleyii rubọ nibi nkan ti nlọ rà, kóbà léè rí nkan yi tà,
kówó-rẹ si pada walé. Bayi ni Ọrúnmìlà se njo, tó nyọ. Ó ni, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni
babalawo toun sọ:
Ajé “dinero” llego al tres cruces con sus dos-cientos esclavos y no sabia que era una persona muerta.
Ajé empezó a preguntarla: ¿Cuántos vale estas cosas? ¿Cuántos vale aquellas cosas? La muerta no
contesto nada. Ajé se enfado y pego la muerta en la cabeza con un palo y la muerta se fue al suelo. Esu
salió fuera de su escondite, se enfrento a Ajé que: ¡Tu Ajé, acabas de matar a la esclava de Ọrúnmìlà!
Ajé pensaba que fue el que mato a la esclava muerta. Ajé empezó a pedir perdon y clemencia a Esu. Ajé
dijo que iba sustituirla con uno de sus esclavos. Esu dijo que no. Luego Ajé subió la ofreta a dos
esclavos. Esu dijo que no. Después Ajé subió la ofreta a los dos-cientos esclavos. Esu se negó
rotundamente y dijo que iban a ir juntos a hablar con Ọrúnmìlà. Ajé ofreció el mismo y sus dos-cientos
esclavos a Esu. Esu dijo que no. Al final, Esu llevo a Ajé y sus dos-cientos esclavos a Ọrúnmìlà. Esu ya
había hablado con Ọrúnmìlà y consolarle en su casa que su dinero volverá, que iba a recuperar su
dinero invertido en la esclava muerta. Esu se llevo a Ajé y sus dos-cientos esclavos a Ọrúnmìlà. Asi fue
como Ajé y sus dos cientos esclavos se convertieron en esclavos de Ọrúnmìlà hasta el dia de hoy.

Aqui es donde Ifa esta diciendo a esta persona que debe tener cuidado, Ifa dice que quiere ir de viaje,
Ifa dice que debe hacer el sacrificio, para que ese viaje no le lleva a meterse en problema, hasta para no
volver a su casa, para que no se convierte en esclavo de su compañero, para que no se enbarca en un
comercio o negocio que puede aruinarle. Ajé no hizo sacrificio y embarco en un viaje sin retorno, sin
vuelta, se aruino y se convertio enesclavo de Ọrúnmìlà hasta el dia de hoy. Asi llego el Aje a la casa de
Ọrúnmìlà.

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio para no tener pedidas en su negocio o comercio, para
que puede vende lo que iba a comprar y sacar ganacias que puede llevar a su casa. Ọrúnmìlà estaba
feliz, empezó a bailar y canta, que asi mismo lo adivinaron y cantaron sus babalawos; QUE:

Èkìtì bàbàbà. (Èkìtì bàbàbà)

A difá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Nijọti baba ntu owo-ẹru jọ. (El dia que el padre “Ọrúnmìlà” estaba reuinendose dinero
para comprar esclavo)

Ti yoo silọ ree rẹrú (Que iba a comprar una esclava)

Ti yoo si pàdanù ẹrú. (Que iba a peder la escalva)

A si bufun Esu-Ọdàrà. (Tambien se adivino Ifa para Esu-Ọdàrà)

Nijọ toun ati Ọrúnmìlà nse ọrẹ. (El dia que el y Ọrúnmìlà eran amigos)

Ti yoo si gbere gbogbo bọwa fun Ọrúnmìlà. (Que iba a llevar todas las bendiciones a Ọrúnmìlà)
Ẹbọ niwọn ni ó se. (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Ẹyin ò rí bi. (¡Ustedes lo han visto!)

Bi a bani ọrẹ-rere. (Si tenemos amigo con suerte)

Nseni a sorí-rere. (La suerte tocara a uno también)

Ibi a bani ìpo, nlaa gbe o. (Uno debe vivir donde tiene cargo o rango)

Bi a bani ọrẹ-rere. (Si tenemos amigo con suerte)

Nseni a sorí-rere. (La suerte tocara a uno también)

ASẸ IFÄ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá ni ọrẹ eleyii kan nbẹ, kó dii mu dada, wipe asepapọ wọn dara,
yoo rire nibẹ, yoo sini ifọkàn balẹ.

ASẸ IFÄ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona tiene un amigo,
Ifa dice que debe unirse o sujetarse muy bien a su amigo. Ifa dice que hay bendiciones en sus
amistades y que conseguirá su tranquilidad/bien estar.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgun ọta (Investigar el vencimiento de enemigos)

Ifá lawọn aiye ndeleyii laamu, wọn nkóná sọràn rẹ. Ifa nikó LỌ BỌ ỌSUN nibẹ, kilé aiye rẹ le dara, ko léè báà
dùn, ko larínrín, kó léè báà sẹgún ọta. Ifá lọta ndeleyii laamú, wọn kòjẹ kó saseyọrí rara, eleyii nsisẹ-sisẹ, kò
lojutu. NIbi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:
Ifa dice que los brujos/as están estorbaandos y molestandos a esta persona, están cruzándole en sus
caminos. Ifa dice que debe DAR DE COMER A ỌSUN, para que tenga buena vida, para que sea feliz y
para vencer a sus enemigos. Ifa dice que los enemigos estan estorbaandos y molestandos a esta
persona, no le dejan prosperar. Ifa dice que esta persona esta trabajando sin frutos. Ifa lo dice asi con
este verso, QUE:

Ìwòrì Tútù níníní (Ìwòrì esta fresquísimo).

Bi ẹni tiwọn nsà da. (Como alguien que le están amarandos o hechandole
maldiciones)

A díá fun Ẹgbẹwa-Oosa. (Se adivino Ifa para los dos mil Orisas)

Eyi tiwọn nkona masọ-rẹ ninu igba. (El que le estaban quemando sus caminos dentro de una
calabaza para quitarle sus ropas)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Le dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto, y no tan lejano)

Ifá wa bani larusẹgún. (Ifa ven a ayudarnos en el levantamiento y aceptación de


nuestros sacrificios)

Àrusẹgún laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En el medio del levantamiento y aceptación de nuestros
sacrificios se encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

ASẸ IFÄ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá lawọn aiye ndeleyii laamu, wọn nkóná sọràn rẹ, kólọ BỌ ỌSUN
nibẹ, kilé aiye rẹ le dara, ko léè báà dùn, ko larínrín, kó léè báà según ọta.

ASẸ IFÄ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que los brujos/as están
estorbaandos y molestandos a esta persona, están cruzándole en sus caminos. Ifa dice que debe DAR
DE COMER A ỌSUN, para que tenga buena vida, para que sea feliz y para vencer a sus enemigos.
.

3·13. ÌWÒRÌ-ÒTÚRÁ. (Ìwòrì-Wòtu).

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo iku (Investigar la muerte)

Ifá ni keleyii sọrarẹ, kómá gbọkàn lagbara kan, kagbara yi máà báà doju tẹniyii nijọ kan, ti yoo sii sekú
pẹniyii. Ifá ni keleyii si sọrarẹ, kóma gbàmọràn tọrẹ-rẹ ba nbaa da, nitorí ìmọràn to léè jẹki araiye sekú
peleyii ni. Ifá ni keleyii sọrarẹ, kó masi jọrarẹ loju wipe oun jẹ nkan loju Olodumare, kó sọra ìgberaga.
Ifá ni teleyii basọ wipe kòsi nkankan tẹnikan lee foun se, Ifá lawọn ọmọ-araiye yoo pa eleyii sere ni. Ibi
tifá tisọ wipe keleyii ma gbera lògùn tabi agbara kankan niyi o, nitoripe ọrẹ-rẹ yoo sọfun pògùn tabi
agbara kan wà nibikan, wipe yoo doju tii. Ó ni:

Ifa dice que esta persona debe tener cuidado. Ifa dice que esta persona no debe depender de los
poderes medicinales, ni poderes físicos, para que sus poderes no le lleva a la veriguenza y la muerte un
dia. Ifa dice que esta persona no debe aceptar a los consejos de su amigo, porque son consejos que
puede llevarle a la muerte desde las manos de las gentes. Ifa dice que esta persona no debe ser atrevido
o arogante, que no diga que es alguien en la presencia de Olodumare. Que no diga que nadie puede
hacerle nada, Ifa dice que las gentes le mataran como una mosca. Aquí es donde Ifa lo dice con este
verso que no debe depender de ningún poder, sea medicinales o físico, porque su amigo le va decir que
hay poderes en algún sitio, lo cual le llevara a la veriguenza y la muerte; QUE:

Ìwòrì tíntí. (Ìwòrì tíntí.)

Babalawo Òrì. (Babalawo del pájaro de Òrì)

Lo difá fun Òrì. (Adivino Ifa para el pájaro de Òrì)

Ìwòrì tíntí. (Ìwòrì tíntí.)

Babalawo Ọkùn. (Babalawo de Ọkùn “centipies”)

Lo difá fun Ọkùn (Adivino Ifa para Ọkùn “centipies”).

Nijọ tawọn mejeji jọ nsọrẹ. (El dia que los dos eran amigos)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Le dijieron que debe el hacer el sacrificio)

Ọkùn si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Ọkùn “centipies” hizo el sacrificio)

Rirú ẹbọ ni nfín, ti ngbeni. (Haciendo sacrificio que se levanta y se acepta es lo que
ayuda a uno)

A tete rú tesu a dàrà danu. (Apasiguando a Esu pronto, desvia la mala suerte)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani larusẹgún . (Ifa ven a ayudarnos en el levantamiento y aceptación de


nuestros sacrificios)

Àrusẹgún laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En medio del levantamiento y aceptación de nuestros
sacrificios se encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Ìwòrì tíntí. (Ìwòrì tíntí)

Babalawo Òrì. (Babalawo del pájaro de Òrì)

Lo difá fun Òrì. (Adivino Ifa para el pájaro de Òrì)

Wọn niki Òrì ó gbẹbọ nibẹ, ki ó rubọ. (Dijieron al pájaro de Òrì que debe hacer el sacrificio)
Òrì kọ, kò rubọ. (El pájaro de Òrì se negó en hacer el sacrificio)

Ó pawo leke, (Llamo a awo mentiroso)

Ó pesu lole. (llamo a Esu ladron)

Ó wo ọrún yànyàn bi ẹnipe ilẹ kòni su mọ. (Miro el cielo tan brillante como que no iba a hacer de
noche)

Esu àìsẹbọ. (La tentación de no hacer sacrificio)

Ẹgbà àìtu. (La paralisis de no apasiguar a esu pronto)

Ni npa alaìrubọ lọ. (Es lo que esta matando al que no hace el sacrificio)

Ọkùn ati Òrì, ọrẹ gidi niwọn. Ti Ọkùn ba lode kan tofẹ lọ, yoo ransẹ si Òrì, tiwọn yoo jọ lọ. Ti Òrì na ba
lode kan tofẹ lọ, yoo ransẹ si Ọkùn tiwọn yoo jọ lọ. Nigbâ to dijọ kan, tiwọn nlọ sode. Ni Ọkùn wa bi
Òrì wipe, iwọ ọrẹ mi, kínní ó de, to jẹpe tawọn ba nlọ sode, tiwọ bati rawọn àdaiye-gun, iwọ yoo maa
sá funwọn. Òrì ni, iwọ ọrẹ-mi, awọn àdaiye-gun ma npa eniyàn jẹ ni o. Ọkùn niki Òrì ma sa funwọn
mọ lati oni lọ. O ni ògùn toun nlo, oun yoo see fun-un, to jẹpe tawọn ọmọ àdaiye-gun bati rí oun, wọn
yoo moju kuro lara-rẹ ni. Òrì ni kó se fun-un. Ni Ọkùn ba sògùn fun Òrì.

Ọkùn “centipies” y el pájaro de Òrì eran amigos intimos. Si Ọkùn“centipies” quiere salir, siempre
invita a su amigo Òrì a salir juntos. Si el pájaro de Òrì quiere salir, siempre invita a su amigo
Ọkùn“centipies” para salir juntos. Un dia que iban juntos fuera, Ọkùn pregunto a su amigo Òrì que:
¿Por qué te hechas a correr cada vez que ve a las gentes? Òrì contesto que las gentes matan. Ọkùn dijo
a su amigo que no tenga miedo a las gentes mas apartir de ahora y que no se hecha a correr por ellos.
Ọkùn dijo que el tiene una medicina que el usa para que las gentes quitan sus vistas a el. El pájaro de
Òrì pidió a su amigo que le prepara la misma medicina. Ọkùn“centipies” hizo la medicina para el
pájaro de Òrì.

Nijọ kan, niwọn ba nlọ sode, niwọn ba pade awọn ọmọ àdaiye-gun lọna. Ni awọn ọmọ àdaiye-gun ba
nwa okuta. Ọkùn kò sini ọbẹ lara tẹlẹ tiwọn lee jẹ. Sugbọn Òrì lẹran lara tiwọn lee jẹ. Bawọn ọmọ
àdaiye-gun ti fagi yọ, ni Òrì ba fo lọ. Òrì nse, ògùn tọrẹ oun se fun-un jẹjẹ-jẹjẹ, nse ni nkàn nti-ti-ti. Ti
Òrì ba gbọkàn le ògùn Ọkùn ni, nse ni kiba kú. Òrì na siti pada lọ silé awọn babalawo, tiwọn ni kó rubọ
ìfura. Òrì siti rubọ ìfurá. Ifá nimọràn tọrẹ eleyii yoo maa baa gbà, ìmọràn ikú ni o. Ifá ni keleyii máà
gbàmọràn yi, kósi máà gbọkàn lògùn tabi agbara o.

Un dia, se iban juntos y se encontraron con las gentes por el camino. Las gentes empezaban a buscar
piedras. Ọkùn no tiene cuerpo, no tiene carne que las gentes pueden comer. Pero el pájaro de Òrì
tiene cuerpo y carne que las gentes pueden comer. Cuando Òrì vio que las gentes sacaban palos. El
pájaro de Òrì se escapo volando, diciendo que: “la medicina que me hizo mi amigo fallo”. Gracias a
que el pájaro de Òrì no dependió de la medicina que le hizo su amigo Ọkùn, las gentes lo hubieran
matado. Òrì también fue a consultarse con los babalawos y le dijieron que debe hacer el sacrificio para
la alerta. El pájaro de Òrì hizo el sacrificio para la alerta. Ifa dice que los consejos que le esta dando el
amigo de este consultante, son consejos que le puede llevar a la muerte y que no debe aceptarlo. Ifa
dice que no debe depender de los poderes medicinales, ni poderes físicos.

Ìwòrì tíntí. (Ìwòrì tíntí.)

Babalawo Òrì. (Babalawo del pájaro de Òrì)

Lo difá fun Òrì. (Adivino Ifa para el pájaro de Òrì)

Ìwòrì tíntí. (Ìwòrì tíntí.)

Babalawo Ọkùn. (Babalawo de Ọkùn “centipies”)

Lo difá fun Ọkùn (Adivino Ifa para Ọkùn “centipies”).

Nijọ tawọn mejeji jọ nsọrẹ. (El dia que los dos eran amigos)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Le dijieron que debe el hacer el sacrificio)

Ọkùn si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Ọkùn hizo el sacrificio)

Rirú ẹbọ ni nfín, ti ngbeni. (Haciendo sacrificio que se levanta y se acepta es lo que
ayuda a uno)

A tete rú tesu a dàrà danu. (Apasiguando a Esu pronto, desvia la mala suerte)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)


Ifá wa bani larusẹgún . (Ifa ven a ayudarnos en el levantamiento y aceptación de
nuestros sacrificios)

Àrusẹgún laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En medio del levantamiento y aceptación de nuestros
sacrificios se encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Ìwòrì tíntí. (Ìwòrì tíntí)

Babalawo Òrì. (Babalawo del pájaro de Òrì)

Lo difá fun Òrì. (Adivino Ifa para el pájaro de Òrì)

Wọn niki Òrì ó gbëbọ nibẹ, kó rubọ. (Dijieron al pájaro de Òrì que debe hacer el sacrificio)

Òrì kọ, kò rubọ. (El pájaro de Òrì se negó en hacer el sacrificio)

Ó pawo leke, (Llamo a awo mentiroso)

Ó pesu lole. (Llamo a Esu ladron)

Ó wo ọrún yànyàn bi ẹnipe ilẹ kòni su mọ. (Miro el cielo tan brillante como que no iba a hacer de
noche)

Esu àìsẹbọ. (La tentación de no hacer sacrificio)

Ẹgbà àìtu. (La paralisis de no apasiguar a esu pronto)

Ni npa alaìrubọ lọ. (Es lo que esta matando al que no hace el sacrificio)

ASẸ IFA:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá nimọràn tọrẹ eleyii yoo maa baa gbà, ìmọràn ikú ni o. Ifá ni
keleyii máà gbàmọràn yi, kósi má gbọkàn lògùn tabi agbara o.

ASẸ IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que los consejos que le esta dando
el amigo de este consultante, son consejos que le puede llevar a la muerte y que no debe aceptarlo. Ifa
dice que esta persona no debe depender de los poderes medicinales, ni poderes físicos.
ẸSẸ KEJI

Ayẹwo isẹgun ọta (Investigar el vencimiento de enemigo)

Ifá ni keleyii o rubọ nibẹ, kósi sọra nibẹ, kómá báà fọwọ ararẹ basẹ ararẹ jẹ, kómá báà fọwọ ararẹ tusẹ ararẹ ka.
To basi jọkùnrin to niyawo meji leleyii, tilé rẹ ndùn yínyín, kómá báà fọwọ ararẹ tulé ararẹ ru. Ifa ni Keleyii
rubọ ìgbẹyin, kó rubọ isẹgun, kó rubọ ọta, kiwọn ma tusẹ-rẹ ka. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y debe tener cuidado, para no destruir o echar a
peder sus trabajos con sus propios manos. Si es un hombre que tiene dos mujeres y hay felicidades en
su casa, Ifa dice que debe tener mucho cuidados para que no se echa peder su casa por su culpa. Ifa
dice que esta persona debe hacer el sacrificio para la finalidad, debe hacer sacrificio para el
vencimiento, debe hacer sacrificio para el vencimiento de los enemigos, para que no le causan
liquidaciónes y echar a peder sus trabajos. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Igi wọrọkọ ni tuna ka. (Arbol curvado es lo que destruye el camino)

Asiwere eniyàn ni tulé ararẹ ka. (Persona loco es el que destruye su casa)

A difá fun Balé-Ilé. (Se adivino Ifa para el jefe de la casa)

Ti yoo fọwọ ararẹ tulé ararẹ ka. (Que iba a destruir su propio casa)

Ti yoo rojọ ìyawo fun ìyalé. (Que iba a hablar sobre su segunda esposa con la primera
esposa)
Ti yoo rojọ ìyalé fun ìyawo. (Que iba a hablar sobre su primera esposa con la segunda
esposa)

Ẹbọ niwọn ni ó se. (Le dijieron que debe hacer el sacrificio)

Ẹgbà àìrubọ. (La paralisis de no hacer el sacrificio)

Esu àìtesu. (La tentación de no apasigua a Esu pronto)

Àìtete gbẹbọ rubọ fesu. (Al no llevar el sacrificio pronto a Esu)

Ni nfi basẹ ararẹ jẹ o. (Por eso se destruye su propio trabajo)

Iwọ se nkọ sẹ tẹlẹda rán ọ. (¿Porqué estas negando el trabajo que te mando tu criador)

Ẹgbà àìrubọ. (La paralisis de no hacer el sacrificio)

Esu àìtesu. (La tentación de no apasigua a Esu pronto)

Àìtete gbẹbọ rubọ fesu. (Al no llevar el sacrificio pronto a Esu)

Niwọ fi npasẹ tẹlẹda rán ọ (Por eso destruye el trabajo que te mando tu criador)

ASẸ IFA:- Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ, kósi sọra nibẹ, kómá báà fọwọ ararẹ basẹ ararẹ jẹ, kómá báà fọwọ
ararẹ tusẹ ararẹ ka.

ASẸ IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y debe tener cuidado, para no destruir o
echar a peder su pripio trabajo.
3·14. ÌWÒRÌ-ÌRẸTẸ. (Ìwòrì-Wẹrẹ), (Ìwòrì-Átẹ), (Ìwòrì-Àìwolẹ).

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo.

Ifá ni keleyii o rubọ nibẹ. Wọn ni kiwọn ni ÌGBIN lẹbọ nibẹ ati ẸJA-ÀRỌ ati ỌPỌLỌPỌ-ÓWÓ. Kómá báà tẹ
nigbẹyin, kóma si agbara lo, kó sọrarẹ dada, kómá báà si agbara lo, kómá báà sẹsín nigbẹyin. Toba loun lagbara
lati mafi yànyàn jẹ, kó sọrarẹ, kómá báà sẹsín nigbẹyin. Ifá ni keleyii ma huwà buruku o, toba rope asegbe nbẹ,
kò sasegbe kankan o. Èrè iwà teleyii bahu, ni yoo gbà. Tó base dada, yoo gbà dada. Tó base buruku, yoo gbà
buruku. Ifá ni kóma sì agbara lo rara o, nitorí atubọtan rẹ, kolè dara. Keleyii máà báà tẹ loju Ìwòrì Átẹ. Iwòrì ti
ntẹ eniyàn. NIbi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe tener CARACOL en su sacrificio, debe tener PEZ
GATO en su sacrificio, debe tener MUCHO DINERO en su sacrificio, para no quedarse en ridículo al
final. Ifa dice que debe tener cuidado muy bien, para no mal adminisrtrar o usar mal sus poderes, para
no quedarse en ridículo al final. Si esta persona dice que sabe engañar o chuliar las gentes, debe tener
muchos cuidados para no quedarse en ridículo al final. Ifa dice que esta persona no debe comportarse
mal, por que pagara las consecuencias de sus hechos. Ifa dice que esta persona cosechara lo ha
sembrado. Si hace bien, le pagaran con bien. Si hace mal, le pagaran con mal. Ifa dice que no debe usar
mal sus poderes para nada, que no debe abusar de las gentes con sus podres, para que su vejez sea de
buena vida, para que esta persona no se queda en ridículo al final en el signo de Ìwòrì-Átẹ, “Ìwòrì que
deja la gente en ridículo” Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ìwòrì Átẹ. (Ìwòrì que deja la gente en ridiculo)

Ìrẹtẹ Àtẹ. (Ìrẹtẹ que deja la gente en ridiculo)

Ẹ rọra tẹwọn. (Ustedes tengan cuidados en dejarles en ridículos)

Kọmọ araiye máà báà siwà hu. (Para que las gentes del mundo no se comportan mal)
Ẹni ba serere. (El que se comporta/hacer bien)

A gbà rere. (Recibira o cobrara con el bien)

Ẹni ba sìka. (El que se comporta/hacer mal)

A si gbà ìka. (Recibira o cobrara con mal)

A díá fun awọn Aiye. (Se adivino Ifa para las gentes del mundo)

Nigbà ìgbawasë. (Al principio del mundo)

Ẹyin òlè, ki ẹ ma jalè mọ o. (Ustedes que son ladrones, dejan de robar)

Ẹni ba jalè a sẹsín. (El que roba se quedara en ridículo)

Ẹni baji wọn lẹgbẹrún ówó. (El que roba a ellos mil de dinero)

A sì sòfò ẹgbẹwa. (Pedera dos mil)

Ẹbọ niwọn ni kiwọn ó se. (Dijieron que deben hacer el sacrificio)

Wọn kọ, wọn kò rubọ. (Se negaron en hacer el sacrificio)

Awọn tiwọn nfarawọn sẹsín. (Los que estan dejandose en ridículos)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto, no tan lejano)

Ẹ wa wofá awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver el Ifa que el awo adivino se hizo realidad)

Ó nse: ORIN: (CANCION)

Ẹ wa wofá awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver el Ifa que el awo adivino se hizo realidad)

Ẹ wa wofá awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver el Ifa que el awo adivino se hizo realidad)

Kò pẹ o, kò jìnnà. (Pronto y no tan lejano)

Ẹ wa wofá awo ki biti nsẹ. (Ustedes ven a ver el Ifa que el awo adivino se hizo realidad)

Wọn ni kiwọn o rubọ. Wọn kọ, wọn kò rubọ. Awọn tiwọn gbajumọ, tiwọn wa nlọ jale, niwọn ba fara-
wọn sẹsín. Niwọn ba muwọn, tiwọn jawọn si hòhò, wọn fiwọn sẹsín aiye. Niwọn ba nsọ pe awọn
babalawo tisọ bẹẹ wipe awọn yoo tẹ o, wipe agbara tawọn ni, kawọn máà síì lo, nigba tawọn sì agbara
yi lo, lawọn sẹsín aiye bayi.

Les dijieron que deben hacer el sacrificio y se negaron en hacer el sacrificio.Ellos que son famosos y
estaban robandos por allí, al final se quedaron en ridículos. Les cogieron, les desnudaron delante de
todo mundo y se quedaron en ridículo delante el todo mundo. Empezaron a decir que los babalawos
les habían dichos que iban a quedarse en ridículo, que no debían mal administrar o usar mal sus
poderes, ni abusar de las gentes. Usaron mal sus poderes y se quedaron en ridículos.

ASẸ IFA:- Ifá ni keleyii o rubọ nibẹ. Wọn ni kiwọn ni ÌGBIN lẹbọ nibẹ ati ẸJA-ÀRỌ ati ỌPỌLỌPỌ-ÓWÓ.
Kómá báà tẹ nigbẹyin, kóma si agbara lo, kó sọrarẹ dada, kómá báà si agbara lo, kómá báà sẹsín
nigbẹyin.

ASẸ IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, debe tener CARACOL en su sacrificio, debe
tener PEZ GATO en su sacrificio, debe tener MUCHO DINERO en su sacrificio, para no quedarse en
ridículo al final. Ifa dice que esta personadebe tener cuidado para no mal adminisrtrar o usar mal sus
poderes y no quedarse en ridículo al final.

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo isẹgún ọta (Investigar el vencimientos de los enimigos)

Ifá logún nbẹ feleyii o. Ifá ni kó rubọ isẹgún, kólè báà sẹgún nibẹ. Ifá larin ọta leleyii wà, ninu ogún ìdìlé. Ifa ni
keleyii ó rubọ, kólè báà bọ ninu rẹ. Kó rubọ, kawọn babalawo si jewé Ifá fun-un, kólè báà sẹgún. Toba jẹlu kan
lo dafá yi, Ifá logún nbọ o. Kiwọn tete rubọ kogún ma wọlé tiwọn ninu ilu yi. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa
na sọ pe:

Ifa dice que hay batallas o guierras para esta persona. Ifa dice que esta person debe hacer el sacrificio
de vencimiento, para que puede vencer. Ifa dice que esta persona esta en el medio de los enemigos, Ifa
dice que esta persona tiene batallas o guierras familiares y debe hacer el sacrificio para salvarse. Ifa
dice que debe hacer el sacrificio y acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa
para poder vencer. Si es una ciudad que ha hecho esta consulta, Ifa dice que esa ciudad va entrar en
guierra y que deben hacer el sacrificio antemano para que la guierra no entra en esa ciudad. Ifa lo dice
asi con este verso; QUE:

Ìri aiye rí. (Lo que el mundo ha experimentado)

Kò gbọ àìmọwà hu. (No entiende de no saber comportarse)

A díá fun Ọrúnmìlà. (Se adivino Ifa para Ọrúnmìlà)

Baba yoo gbedè bọrun. (El padre “Ọrúnmìlà” iba a colgar el collar de ”ìdè” en su cuello)

Yoo maa gún iyán. (Iba a machacar el yame para preparar la pasta de yame)

Wọn ni baba eetírí bayi. (Dijieron que: ¡Padre, porque ha pasado esto!)

Ó ni, Ìwòrì àìwolẹ. (Dijo que es “Ìwòrì de no mirar el suelo”)

Ẹyin ò rogún loju opopo. (Ustedes no han vistos que hay guierra en la calle)

ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá logún nbẹ loju opopo feleyii. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kogún yi
máà báà wọle tẹni tó dafá yi loju Ìwòrì-Ìrẹtẹ.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que hay guierra en la calle para esta
persona ( hay guierra para esta persona). Ifa dice que debe hacer el sacrificio para que la guierra no
entra en su casa en el signo de Ìwòrì Ìrẹtẹ.
3·15. ÌWÒRÌ-ỌSẸ. (Ìwòrì wosẹ)****************************

ẸSẸ KINNI.

Ifá ni keleyii sọrarẹ dada loju “Ìwòrì wo-ìsẹ”, kómá ma hún-àhúndá, kóma sọpe afi koju oun to gbogbo
nkan, tóba ntọ pípí, toni afi koju oun to gbogbo nkan,

Este Ifa se llama“Ìwòrì mira la pobreza”. Ifa dice que esta persona debe tener cuidado bastante, que no
haga las cosas que le puede causa problemas, que no diga que debe ver todas las cosas con sus propio
ojos, si esta persona esta siendo tan desconfiado para ver todas las cosas con sus propio ojos,
3·16. ÌWÒRÌ-OFÚN. (Ìwòrì Wofún).

ẸSẸ KINNI.

Ayẹwo isẹgún ọta (Investigar el vencimiento de enimigo)

Ifá ni keleyii ó rubọ nibẹ, kaiye má báà pa kadara-rẹ dà loju Ìwòrì Wòfún. Kósi súnmọ awọn babalawo,
kiwọn baa jewé Ifá, nitoripe wọn yoo gbiyànju lati pa kadara-rẹ dà. Tó bati rubọ, tawọn babalawo jewé
Ifá fun-un, agbara wọn kòni léè keleyii, Ifá lo sọ bẹẹ loju Ìwòrì Wòfún. Ifá ni beleyii se nsagbara to, lati
là, lati lówó, lati nire gbogbo, Ifá lawọn ọta nfà silẹ ni, ti nkan rẹ bati dara, wọn a tun yi pada seyiti kò
dara.

Ifá ni keleyii kiyesi orún tó nsun. Ifá ni lati oju orún niwọn ti ndeleyii laamu. Wọn kòni jẹ kọwọ eleyii to nkan tó
nwa loju ìsalaiye. Nitoripe Eledumarè ti deleyii lati sorí-rere, lati nire gbogbo teniyàn nni. Sugbọn nigba tó
daiye tan, wọn ngbìyànju lati yi kadara eleyii pada loju Ìwòrì Wọfún. Nibi tifa wa gba tofi sọ bẹẹ re o. Ifa na sọ
pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que no le cambian su destino en el signo de
Ìwòrì Wòfún. Ifa dice que debe acercarse a los babalawos para que le preparan las hierbas de Ifa,
porque están intentandos cambiar su destino. Ifa dice que si esta persona hace el sacrificio y le
preparan hierbas de Ifa, no conseguirán cambiarle su destino en el signo de Ìwòrì Wòfún. Ifa dice que
todos los esfuerzos que esta haciendo esta persona para conseguir dinero, riquezas y todas las
bendiciones, Ifa dice que los enemigos le están llevandos para atrás, cuando la cosa le quiere salir bien,
darán vuelta a su destino para mal, para que no le sale bien las cosas.

Ifa dice que esta person debe prestar atención a sus sueños. Ifa dice que le están estorbandos y
cambiándole su destino desde sus sueños. No le dejan cumplir sus sueños en la vida real, poque
Eledumarè ha criado esta persona para ser una persona prosperoso, para tener todas las bendiciones,
al llegar a mundo esta persona, las gentes están intentandos cambiarle su destino. Ifa lo dice asi con
este verso en el signo de Ìwòrì Wọfún; QUE:
Mo wowaju, Ìwòrì Wòfún N ò ríbí. (Miro adelante Ìwòrì Wòfún, no vi maldición)

Mo wẹyin, Ìwòrì Wòfún N ò ríbí. (Miro detras Ìwòrì Wòfún, no vi maldición)

Mo wo agbede-gbede-meji Ìwòrì Wòfún. (Miro el centro Ìwòrì Wòfún)

Mo rohun bi Ọkùn. (Vi algo como mil pies)

Mo rohun bi idẹ. (Vi algo como mil bronce)

A difá fun Érélú. (Se adivino Ifa para Érélú)

Eyiti nseya Ọràn. (Que era la madre de problema “Ọràn”)

Ẹni tise àbẹnukú Érélú. (Que era el “àbẹnukú” de Érélú)

To gbọkùn ju sọbẹ. (Metio mil pies en la salsa)

Ọkùn siwa yipada ó dẹja. (Mil pies se convertio en pezcado)

Wọn tisọ fun Érélú wipe Ode Ìsalaiye tó nlọ yi, wipe yoo rise nibẹ, ọna rẹ yoo là, sugbọn awọn ọmọ
araiye yoo pa kadara-rẹ dà. Érélú kòni ìgbagbọ, kò rubọ. Nigbà to dijọ kan, ni Érélú ba nsùn, ó nlala
kala. Érélú ni, kínní gbogbo irú eleyii, wọn nfara hàn loju orun, sugbọn kò tun kà si.

Nijọ kan, ni Érélú ba sebẹ osíkí to dara, ó wa sẹja-aborí-dudu sii. Ni ó ba gúnyan wipe koun jẹun. Nigba tó
gúnyan tan, ó fẹ bubẹ, wọn tiyi ọbẹ pada. Ọkùnrùn lóba nibẹ, ẹrù ba Érélú gidigidi. Érélú ni, kínní gbogbo irú
eleyii. Ni Érélú balọ soko awo lọ dafá. Ni Ìwòrì-ọfún ba jade. Awọn babalawo ni nkan apẹrẹ kan leleyii nrí yi.
Kó rubọ, ki nkan apẹrẹ buruku yi léè yipada si rere, atipe orún teleyii nsùn kò dara. Keleyii ó setutu nibẹ. Wọn
ni kerélú rubọ nibẹ. O nigbagbọ, kò dẹja bi tẹlẹ. Ni Érélú ba rubọ. Nigbà terélú pada delé, ọbẹ-rẹ ti yi pada sọbẹ
òsiki ati ẹja àrọ dudu pada. Inu rẹ dùn. Ó ni awọn babalawo lo kifá to bayi, tiwọn ni nkan oun yoo yi pada si
rere, o si yi pada si rere.

Ifá ni kasọ feleyiii wipe yoo ri wahala nibi isẹ-rẹ. Sugbọn ayipada-rẹ yoo dara fun-un. Keleyii o setutu
nibẹ. Bayi ni Érélú se njo, ó nyọ, ó nyin awọn babalawo rẹ, awọn babalawo rẹ si nyin Ifá. Ó ni, bẹẹ
gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun sọ:
Ya se lo han dicho a Érélú que el mundo que iba, tendrá vida buena, hara cosas buenas, su camino
abrirá, pero las gentes del mundo cambiaran su destino. Érélú no tenia fe y no hizo el sacrificio. Un
dia, Érélú estaba dormiendo y estaba sonando mal, estaba recibiendos señales malas en sus suenos,
pero no lo daba importancias.

Un dia, Érélú preparo una salsa muy buena con las semillas de calabaza y con pez-gato de cabeza
negra. Érélú preparo la pasta de yame para comer. Cuando termino preparando la pasta de yame, iba
coger la salsa para comer, cuando dio la vuelta a la salsa. Érélú vio mil-pies dentro de su salsa de
calabaza. Érélú cogió mierdo bastante fuerte, estaba soprendido de lo que le estaba pasando. Érélú se
fue a consultarse con Ifa y le salio Ìworì-ọfún. Los babalawos le dijieron que estaba recibiendos malas
señales en sus sueños. Dijieron que debe hacer el sacrificio y que las señales malas que esta recibiendos
en sus suenos cambiaran a buenas señales. Dijieron que Érélú no estaba dormiendo bien tampoco y
que debe hacer ofrecimiento. Érélú ya no dudaba a los mensages de Ifa como antes. Érélú hizo el
sacrificio. Cuando Érélú volvió a casa, su salsa ya había cambiado otra vez a la salsa de semillas de
calabaza con pez-gato de cabeza negra. Érélú estaba feliz, estaba soprendido con lo que le han
adivinados los babalawos y que las malas señales han vuelto a cambiarse a buenas señales, su destino
ha cambiado para bien otra vez.

Ifa le esta diciendo a esta persona que va a tener problema en su trabajo, pero las cosas cambiaran
para bien. Ifa dice que esta persona debe hacer sacrificio y ofrecimientos. Érélú estaba feliz, empezó a
bailar y cantar, alabando a sus babalawos y sus babalawos alabandos a Ifa; Que asi mismo lo
advinaron y cantaron sus babalawos; QUE:

Mo wowaju, Ìwòrì Wòfún N ò ríbí. (Miro adelante Ìwòrì Wòfún, no vi maldición)

Mo wẹyin, Ìwòrì Wòfún N ò ríbí. (Miro detras Ìwòrì Wòfún, no vi maldición)

Mo wo agbede-gbede-meji Ìwòrì Wòfún. (Miro el centro Ìwòrì Wòfún)

Mo rohun bi Ọkùn. (Vi algo como mil pies)

Mo rohun bi idẹ. (Vi algo como mil bronce)

A difá fun Érélú. (Se adivino Ifa para Érélú)

Eyiti nseya Ọràn. (Que era la madre de problema “Ọràn”)

Ẹni tise àbẹnukú Érélú. (Que era el “àbẹnukú” de Érélú)

To gbọkùn ju sọbẹ. (Metio mil pies en la salsa)

Ọkùn siwa yipada ó dẹja. (Mil pies se convertio en pezcado)


Ẹbọ niwọn ni ó se, (Dijieron que debe hacer el sacrificios)

Ó si gbẹbọ nibẹ, ó rubọ. (Lo hizo)

Kò pẹ o, kò jìnnà (Pronto y no tan lejano)

Ifá wa bani nijẹbutu ire. (Ifa ven a encontrarnos en las celebraciones de


bendición)

Ìjẹbutu ire laa bani lẹsẹ ọbarisa. (En medio de las celebraciónes de bendición se
encuentra uno a los pies del rey de los Orisas).

Ó nse: ORIN: (CANCION)

Ẹni tó serélú. (El que echo maldición a Érélú)

To gbọkùn ju sọbẹ. (Metio mil pies en la salsa)

Ọkùn siwa yipada ó dẹja. (Mil pies se cambio y se convertio en pezcado otra
vez)

Ọkùn siwa yipada ó dẹja. (Mil pies se cambio y se convertio en pezcado otra
vez)

Ọkùn siwa yipada ó dẹja. (Mil pies se cambio y se convertio en pezcado otra
vez)

Èrìgì àlọ. (Èrìgì àlọ)

Èrìgì àlọ. (Èrìgì àlọ)

Èrìgì àlọ. (Èrìgì àlọ)

Ọkùn siwa yipada ó dẹja. (Mil pies se convertio en pezcado)

Ẹni tó serélú. (El que echo maldición a Érélú)

To gbọkùn ju sọbẹ. (Metio mil pies en la salsa)

Èrìgì àlọ. (Èrìgì àlọ)

Ọkùn siwa yipada ó dẹja. (Mil pies se cambio y se convertio en pezcado otra
vez)
ASẸ IFÁ:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifá ni gbogbo ohun buburu eleyii yoo yipada si rere. Ifa ni kó rubọ
loju Ìwòrì-Wofún.

ASẸ IFÁ:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que todas las cosas malas de esta
persona cambiaran para bien. Ifa dice que debe hacer el sacrificio en el signo de Ìwòrì-Wofún.

También podría gustarte