Documentos de Académico
Documentos de Profesional
Documentos de Cultura
Ẹkáàrọ́ọ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi, aòjíire bí? Akú ìsinmi òní o, ẹ̀min wa yíò ṣe púpọ rẹ
láyé nínú ọlá ati àlàáfíà ara, ire ni ojú wa yíò máa rí lọ́jọ́ ayé wa o àṣẹ.
Ẹ jẹki a fi odù ifá mímọ Ọ̀bàrà méjì yi ṣe ìwúre ti aarọ yi.
Ifá náà ki báyì wípé:
Eegun gogorogo wọnú igbó ènìyàn gogorogo jáde
Eegun kùrùyẹ́lẹ́ wọnú igbó ènìyàn kùrùyẹ́lẹ́ jáde
Bi mi o tiẹ̀ gbọ́n bi mi o tiẹ̀ mọ̀ràn tani ko mọ wípé eegun tó wọnú igbó lọ tun
padà jáde sita
Àgbò amirọ̀rọ̀ wọ́lẹ̀
Ejò ọmọ oníràngbọn ati
Ẹyẹlé ọmọ ẹlẹ́mìni, àwọn ni ajogun ibi mẹta ti wọn lọ ndeegun ẹlẹ́rìmọ̀símọ̀ pa
ọlọ́fin lójú orun, ọlọfin lọ ji laarọ to gun òkè ìgẹ̀tí ile bara mi àgbonmìrègún,
kini òun máa rú lẹ́bọ ti òun máa tù léṣù ti òun yíò fi ṣẹgun ajogun ibi mẹtẹta lo
dífá sí, wọn ni kí ọlọfin lọ ní ìrọ́ epo ki o lọ fi rúbọ ẹni bi ejo, ki o ni ikoko adin
dúdú ki o fi rúbọ ẹni bi ẹyẹlé, ki o sí ni igbá eérú ki wọn fi rúbọ ẹni bi àgbò,
ọlọfin kábọmọ́ra o rúbọ wọ́n ṣe ṣiṣe ifá fún, nígbàtí o di ọjọ́ keji ti àwọn ajogun
ibi mẹtẹta tun fẹ lọ máa da ọlọfin láàmú, èṣù ti ko ẹbọ tí ọlọfin ru sinu ile, bi ejo
ṣe nbọ o wọnú epo o ku sinu epo, bí ẹyẹlé ṣe nbọ o wọnú ikoko adin o ku sinu
rẹ, bi àgbò ṣe nbọ o wọnú eérú o ku sinu eérú, bi ọlọfin ṣe ṣẹgun àwọn ajogun
ibí mẹtẹta nìyẹn, ọlọfin wa njo o nyọ o nyìn babaláwo àwọn babaláwo nyìn ifá,
ifá nyìn Eledumare óní njẹ rírú ẹbọ a máa gbeni èrù àtùkèsù a máa da ladaju njẹ
ko pẹ ko jìnà ifá wa bámi laruṣẹgun aruṣẹgun ni a nbawo lẹsẹ ọbàrìsà.
Ẹ̀ yin ènìyàn mi, mọse ni ìwúre laarọ yi wípé Eledumare yíò bawa ṣẹgun ajogun
ibi eyikeyi yíò wù kí o máa yọwá lẹnu, gbogbo ẹ̀mínkẹ́mìn ti wọn ba ndi ẹranko
láti máa yọwá lẹnu lójú orun yíò fara gba ọfà lágbára Eledumare, ao ṣẹgun
ajogun ibi gbogbo, ìṣọ́ ati ààbò Eledumare kòní dáwọ́ dúró nínú ayé wa lónì ati
titi láéláé àààṣẹ.
ÀBỌRÚ ÀBỌYÈ OOO.