Documentos de Académico
Documentos de Profesional
Documentos de Cultura
Oshe Sa
Oshe Sa
Cuando es Ifá Osobbó: IKU, ARUN, OFO, etc., hay que andar rápido
porque la persona corre peligro.
Aquí la persona tiene un defecto en sus piernas o un hijo que nació con
las piernas torcidas.
Por este Oddun, la persona es incapaz de hacer su casa o vive en
alguna que le han dejado por herencia u otro.
Òsé sá o
Òsé ò sá
Kèlèmbè balè
Ó fara yíiku kítí kìtì kítí
A díá fún Ògún
Tí n gbóguún lo Ìlóbìnrin
A díá fún Òòsà
Òòsà n gbóguún lo Ìlóbìnrin
A díá fún Sàngó
Sàngó n gbóguún lo Ìlóbìnrin
A díá fún Òrúnmìlà
Òrúnmìlà n gbóguún lo Ìlóbìnrin
Ebo n wón ní kí gbogboo wón ó se kí wón ó tóó móo lo
Gbogbo àwon Òòsà ni ón n gbógun lo Ìlóbìnrin
Won ò rí Ìlóbìnrin mú
Òrúnmìlà ló se tán tí ó loogun Ìlóbìnrin
Wón ní kó rúbo
Wón ní kó rú Ìrùkè méjì
Wón ní tó bá dè òhún
Wón ní kó mó se múra kan kaan kan
Wón ní àwon Obìnrin ó tèlé e
Yóó sì kó won lérú
Òrúnmìlà dé òhún
Ó ní Òsé sá o
Òsé ò sá
Kèlèmbè balè fara yíiku kítí kìtì kítí
A díá fún òkànlénú Irúnmolè
Tí n gbóguún lo Ìlóbìnrin
Wón dé Ìlóbìnrin
Won ò rí won kó lérú
Òsé sá o
Òsé ò sá
Kèlèmbè balè fara yíiku kítí kìtì kítí
Awo ilé Òrúnmìlà
A díá fún Òrúnmìlà
Ifá wá n gbóguún lo Ìlóbìnrin
Wón ní ó rúbo kó tóó lo
Òrúnmìlà o wáá gbébo nbè
O rúbo
Ó dé Ìlóbìnrin
Ní bá n jó
Ní bá n dárin
Ní n se pa kéké mó won
Ogun Obìnrin lò n lo
Òsé mó sàá
Ogun Obìnrin lò n lo
Pòkòkò mó won
Ogun Obìnrin lò n lo
Òsé mó sàá
Ogun Obìnrin lò n lo
E yónú sí mi
Ogun Obìnrin lò n lo
Òsé mó sàá
Ogun Obìnrin lò n lo
Pa kókó mó won
Ogun Obìnrin lò n lo
Òsé mó sàá
Ogun Obìnrin lò n lo
Oní gángan n lù
Òrúnmìlà n jó
Ìrùkè n jù lówó è
Àwon Obìnrin bá bèèrè pé
‘Kín leléyìun n seé bò un’?
‘Wón ló ní kóun ó mó sàá’
‘Kóun ó móo bò ni’
Èsù bá da adìe méjì Òrúnmìlà rú sílè
Òrúnmìlà tún dárin
E bá n mádìeè mi
Ogun Obìnrin lò n lo
Òsé mó sàá
Ogun obìnrin lò n lo
Nígbà tí won ó móo lé adìe
Adìe bá kojú sí ònà ilé Òrúnmìlà
Gbogbo àwon Obìnrin bá n lè adìe títíítí
Wón lè adìe wo inú ilé Òrúnmìlà
À fi kóró ti ón kóónú è
Wón ò bá le lo mó
Ifá pé òun pé ire Obìnrin fún eléyìun.