Está en la página 1de 2

AMI ERANKO NAA (666) (Ota le legbeta o le mefa)

O si mu gbogbo won ati kekere ati nla oloro ati talaka, ominira ati eru, ki a fi ami kan fun won ni owo
otun tabi ni iwaju won. Ati ki enikeni ma le ra tabi ta, bikose eniti o ba ni ami oruko eranko naa tabi iye
oruko re. Nihin ni ogbon gbe wa, eni ti o ba ni oye ki o siro iye ti n be lara eranko naa, nitori iye eniyan
ni iye naa si je ota le legbeta o le mefa.666 (Ifihan 13:16-18)
666 JE ETO AKOSO GBOGBO AGBAYE LABE IJOBA KAN SOSO
Ni bayi,. Awon ohun elo kan to n sise pelu ero ayara bi asa (konputa) to le se ise odiwon ni a ti sise lori re ti
awujo wa si ti gba wole. Ohun elo kekere ti a n lo pelu konputa ti n lo imo ero ni a ti fi sinu awon ohun elo ti n lo
ina, awon oja tita, awon nnkan osin ati eniyan. Eyi kii se imo sayensi ti ojo ola ti ko le sele, o n sele lonii.
Ni opolopo ibi ninu aye, imo ti n lo ohun elo kekere kan lati se awari aisan, arun opolo, ito suga, aisan ninu
okan, ti o si tun n dena eniyan jiji gbe. Ni aipe, iru awon ohun to nii se pelu emi yii yoo di ohun ti gbogbo aye fe
won yoo si fee maa gbe e sara fun idanimo, aabo ati itopinpin. eto oro aje ati awon iwulo ti a ko tii le ronu re.
O se ni laanu pe iru awon ohun elo yii maa n toju ohun idanimo enikan, awon ohun ti a si ri mu jade ninu lilo re
ni a le fi pamo ki a si je ki o wa ninu ero ayara bi asa. Ara eniyan a wa di eyi ti a se ami si ti a si n topinpin re, ti
a o si maa dari iwa iru eni bee.
Gbingbin ohun elo (microchip) si ara eniyan yoo yi iri eniyan, irorun re ati igbe aye eni bee pada. Wahala to n
waye nipa lilo ohun elo to ni se pelu emi lara eniyan koja oro ewa, ilera, eto iselu tabi oro ofin.
Satani n sise ninu aye, o si n yi awon eniyan pada lati mu ipinnu re se. Boya a mo tabi a ko mo, asodi si Kristi
yoo fi ipa mu awon eniyan lati tele e ati lati gboran si agbekale to dabii pe o wa fun anfani awon eniyan oun
sugbon ni titele igbekale itan aye eniyan ati iselodi eniyan si Olorun yoo mu irora ati ijiya wa titi ti Kristi yoo fi
pada wa.
O si n tan awon ti n gbe ori ile aye je nipa awon ohun iyanu ti a fi fun wa lati se niwaju eranko naa, o n
wi fun awon ti n gbe ori ile aye lati ya aworan fun eranko naa ti o ti gba ogbe ida ti o si ye. A si fi fun un
lati fie mi fun awon eranko naa ki o ma a soro ki o si mu ki a pa gbogbo awon ti ko foribale fun aworan
eranko naa (Ifihan 13:14-15)
Asiko kan n bo nigba ti awujo ati awon eniyan yoo wa ni abe akoso ara eni ti a o ti maa topinpin eniyan ti a o si
maa se alaye re, a o maa se odiwon re, ti ero ayara bi asa (konputa) yoo si maa se ayewo re. Ni gba yii,
enikeni ti o ba ko lati gba ilana yii ni a o fi iya je, ti a o si pa.
IDASILE AWUJO TI O WOPO
A ti n lo si ipele awujo ti o bara mu, ti awon eniyan ni ipokipo yoo ti ni anfani si ohunkohun nibikibi ati
nigbakugba lai ni fi se asiko tabi ibi ti won wa. Lilo imo ero ti n fi ise redio han ni awon ile itaja kekere je apeere
kan . A se isiro pe opolopo awon oja ti a n ta ni yoo maa lo imo ero ti n fi ise redio han laarin odun kan tabi
meji (lati odun 2005), won yoo si dipo awon ila ti a maa n fa si ara ohun ti a ra ti ero ayara bi asa (konputa) le
ka eleyi ti a ti n lo fun ogbon odun seyin.
Ohun ti o n ti idagbasoke yii leyinn ni pe a o maa gbe igbe aye ti ko lewu, igbe aye to rorun, to ni oro ti o si se e
gbadun nipa lilo imo ero to n sakoso igbe aye eni lojoojumo. Ni awujo to n pongbe fun eto isuna ti ero n sakoso
re, ibara eni soro to ya kankan ati aabo, kii wa se ohun to le pe ti a o fi gba ki a fi ero to n sise pelu pelu radio si
ni lara ti yoo si da owo ti a ti ji pada, tabi ti o sonu tabi eyi ti a pamo. Ni aipe ojo.
1. A o maa reti ki gbogbo eniyan ni ohun elo to n sise pelu emi. Gbogbo eto oro aje ni yoo maa lo ohun
elo yii ti yoo si maa dipo bi a se n sewo.
2. Ko ni si ohun kankan ti o pamo mo, ominira ko si ni si mo.
3. Aladari kan ti o je asodi si Kristi yoo maa dari gbogbo aye nipa eto ti o je alatagba ti o si n kan ara won.

AMI ERANKO NAA NI ARA ENIYAN, A KO GBODO GBA A (Ifihan 14:9, 14:11, 16:2)
1. Gbigba ami yii je tita okan ara eni fun satani lai ni le ra a pada. Ese yii je eyi ti ko ni idariji, ti ko si se e
yipada nipa ami naa (Ifihan 14:9-11) Olorun lo ni okan re. Nitori naa ti o ba gba ami yii, o ti di ti satani
niyen.
2. Ti o ba gba ami yii, o n fi tifetife fi igbagbo re fun eniyan lai se Olorun. O ti yan lati gbe lai si Olorun ife to ni
ipinnu lati lo ayeraye pelu re ni orun. Olorun ko fe ki o yan ona orun apadi. Olorun mo awon nnkan yii tele
nitori pe o fe o, ti o si fe ki o mo eyi, a fi han wa ninu akosile Aposteli Johanu ninu iwe Ifihan ni ogorun
odun leyin iku Kristi. Ti a ko ba mu o lo si orun ti a fi o sile fun ijiya, o ko gbodo gba ami eranko naa sibe a
o je o niya, a o si pa o fun aigba ijoba ti satani n ddari re. O gbodo maa ranti eyi ni gbogbo igba nitori pe
ireti orun si wa titi ti opin yoo fi de.
NJE O TI GBA JESU GEGE BI OLUGBALA RE?
Gbogbo eniyan lo sa a ti se ti won si kuna ogo Olorun (Romu 3:23)
Owo ko ni ohun gbogbo, eniyan ko le wa sodo Olorun nipa gbigbagbo ninu awon Olorun miran tabi igbekele
eniyan, imo tabi rere sise. Ajosep[o pelu Jesu Kristi nikan lo le mu ki o se e se lati duro ninu ododo niwaju
Olorun Mimo ni opin aye eniyan. Nitori idi eyi ni Jesu Kristi se jiya lori igi agbelebu, ti o ta eje re sile, ti o ku ti o
si ji pada. Eleyi ni Olorun se lati fi ife re, agbara re ati ogo re nipa gbigba wa lowo ese ati iku.
Emi ni ona otito ati iye ko si eni ti o le wa si odo baba bi ko se ni pase mi (Johannu 14:6). Pe bi iwo ba fi enu
re jewo Jesu ni Oluwa, ti iwo si gbagbo ninu okan re pe Oluwa jii dide kuro ninu oku, a o gba o la. Nitori okan li
a fi a fi igbagbo si ododo, enu li a si fi ijewo si igbala. (Romu 10:9-10)
O gbodo gba Jesu gbo pe o ku fun ese re Jesu fe o niori ti Olorun fe araye to bee ge ti o fi omo bibi re kan
soso fun ni ki enikeni ti o ba gba gbo ma baa segbe sugbon ki o le ni iye ainipekun. (Johannu 3:16). Ri ara re
bi elese ki o si gbadura ninu igbagbo . O nilo lati gba Jesu ni olugbala re. Dajudaju orun wa, orun apaadi si
wa. Jesu nikan ni ona si orun.

JESU N PADA BO MURA SILE FUN IGBASOKE


Jesu, eni ti o ra wa pada nipa agbelebu yoo pese ibi kan , yoo si pada wa lati wa pelu wa. O ti se ileri fun wa
(Johannu 14:3) igbasoke yoo waye saaju wakati idanwo (Ifihan 3:10) Jesu wipe eyin le moye oju orun ati ti
aye, sugbon eyin ko mo awon ami akoko wonyi (Mat. 16:3, Luku 12:56)

EYIN ARA MIMO NINU JESU KRISTI


Igbasoke je ohun ti a fi sile fun awon mimo ti a o gbe soke ni awosanmo nigba ti Olorun ba pe ipe, awon mimo
ti a o gba soke ni a o gbe soke lati pade Jesu ni oju orun (1 Tessalonika 4:16-17) Igbasoke ni a fi sile fun awon
onigbagbo ti o wo aso funfun ti emi. Ara won ni a o yi pada si ara ti ologo, yoo si je inu didun Oluwa. (Ifihan
19:7-8). Ti o ba si wa ninu igbagbo ko gbona, ko tutu, Jesu yoo po o jade o ko gbodo dabi iru onigbagbo bi eyi
(Ifihan 3:16) Wiwa Jesu akoko ni lati mu igbala wa, sugbon o n pada bo lati pade awon to se tan ti won si n
duro dee ni awosanmo ni idahun si ipe, eyi ni a n pe ni igbasoke. Jesu Oluwa, yoo ko awon omo re pelu ara re
lo si orun.Leyin wakati idanwo ninu aye, yoo tun pada wa si aye pelu awon ti a gba soke pelu re lo si orun lati
lo si Jerusalemu titun, eyi ni a o pe ni Ipadabo re leekeji. Nitori kini ireti wa tabi ayo wa tabi ade isogo re? (1
Tessalonika 2:19)
Nigba ti Jesu ba pada de, awon eni mimo ti a gba soke nikan ni a o ko de iwaju ite ogo (1korinti 15:49-55). Bi
a ti ko tile mo ojo ati asiko pipada bo re awon omo imole ko si ninu okunkun nitori naa ojo naa ko ni de ba yin
bi ole. (1 Tessalonika 5:1-4). Nitori naa ranti bi iwo ti gba ati bi iwo ti gbo, ki o si pa a mo ki o si ronu piwada.
Nje bi iwo ko ba sora, emi o de si o bi ole, iwo ki yoo si mo wakati ti emi o de si o. (Ifihan 3:3) Awon onigbagbo
ko gbona ko tutu, awon ti a ti so mo aye ati awon ti ko mo Jesu ni a o fi sile fun wakati idanwo. Wakati idanwo
yoo je igba eru julo ninu itan aye eniyan. Awon ti a fi sile ninu wakati idanwo ko gbodo gba ohun elo ti o
ni se pelu emi (ti o ni oruko satani) si ara won (iwaju tabi owo otun Ifihan 13:16, 20:4) a ni de oju iku
paapaa. Awon Kristeni to ba pa ara won yoo wa ninu ina titi ayeraye. Nipa kiko ohun elo yii, a o je o
niya, a o si pa o fun awon alaigbagbo, kii se pe ki o ko ohun elo naa nikan, sugbon o nilati jewo Jesu ni
Oluwa ati Olugbala re pelu enu re, ki o toro fun idariji fun ese re ki o si gbagbo ninu okan re pe omo
Olorun ni ati pe o ku fun wa. Amin.

También podría gustarte